Gbagede Yoruba
 



Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un
 
Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun Lati Owo Akoroyin Olootu

Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un

Beeyan ba gesin ninu obinrin opo; kan, Abileko Medinat Folasade Adekunle, l'Ojoru, Wesde, ose to koja yii, tohun ko ni i kose rara nibi tinu e dun de pelu bi ile-ejo giga kan l'Ore, nijoba ibile Odigbo, l'Ondo, se pase fawon ebi oko e pe ki won gbese kuro lori dukia toko re fi sile saye lo.

Saaju lobinrin naa ati agbejoro re, Amofin Anthony Oyibo, ti mori le ile-ejo giga naa, to si fesun kan awon ebi oko re meji kan, Hamzat Taofeek ati Sherifat Olabiyo, pe won gbese le gbogbo dukia toko re, Oloogbe Hamzat Adekunle, fi sile foun atawon omo re, ti won ko si je ko letoo sawon ogun naa.

Iyaale ile naa ro ile-ejo lati pase pe kawon ebi oko re ohun sanwo to to egberun lona eedegbeta naira (N500,000) fun un gege bii owo gba-ma-binu fun iya nla ti won fi je e tomotomo.

Ninu alaye tobinrin opo to n fomije soro nile-ejo ohun se lo ti ni kete toko oun ti doloogbe lawon ebi e ti fi kokoro ti soobu nla toun ni niluu Ore pa, ti won tun gbese le gbogbo ogun ti baale oun fi sile saye lai tie wo tawon omo toun bi. Igbese naa lo ni o so oun atawon omo oloogbe di onibaara osan gangan.

Medinat tun se e lalaye pe se loun atawon omo oun maa n pin ara awon sawon mosalasi to wa niluu Ore, nibi tawon ti maa n toro owo lati le rowo jeun.

Arowa awon ebi oko mejeeji ti won fesun kan nipase agbejoro won, Amofin Bode Akinkoye, pe ki adajo fagile esun tobinrin yii pe nitori ko lese nile ladajo kootu yii, Onidaajo Olorundahunsi ko lati gba wole.

Ninu idajo Olorundahunsi lo ti fidi e mule pe igbese tawon ebi yii gbe ku die kaato, nigba to se pe oloogbe naa fomo saye lo, ati pe awon omo naa lo letoo lati jogun ohunkohun ti baba won fi sile gege bii ilana ati asa ile Yoruba.

Bee lo fofin de awon ebi oloogbe pe eegun won ko tun gbodo se mo nibi dukia ti oloogbe naa fi sile saye lo pelu afikun pe ki obinrin naa maa mojuto dukia toko e fi sile.

Bakan naa lo ko lati fase sibeere olupejo pe kile-ejo pase ki olujejo sanwo itanran to to egberun lona eedegbeta naira fun un. O loun ko lati se bee nitori pe ebi oko re ni won i se, ati pe ninu ohunkohun, o ye keeyan maa ro eyin oro, paapaa niwon igba toro omo ti wo ibasepo obinrin olujejo ohun ati oloogbe. O ni eje to wa lara awon olujejo mejeeji yii naa lo wa lara oko re to doloogbe.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:09:14 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun:
Onka Yoruba - Numbers In Yoruba: Figures And Counting, Kika Ni Yoruba Computes


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Imo Ofin-Olohun - Awon Ibeere Ati Idahun



"Adajo Ni Kawon Ebi Oko Medinat Da Ogun Oko Re Pada Fun un" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com