Gbagede Yoruba
 



Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina
 
Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara Lati Owo Akoroyin Olootu

Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina

''Oko mi n soogun, o si daju pe o ti fi pata mi soogun owo nitori pe latigba ti pata mi ti di awati ni mi o ti ni ifokanbale ati alaafia mo, se ni mo maa n gbo tenikan maa n pe oruko mi ti mi o si ri onitohun, mo kan maa n gbo oruko mi saa ni.'' Iyaale ile kan, Abileko Igbolanu Philomina, lo so bee lasiko to to ile-ejo ibile kan lo, to si ro aare ile-ejo ohun lati tu igbeyawo olodun merindinlogun to wa laarin oun pelu oko re, Bonaventure, ka.

Obinrin ohun so pe gbogbo igba nija maa n waye laarin awon, bee lokunrin naa maa n se agbere kiri, omuti paraku ni, ko toju oun pelu awon omo, o si maa n se oogun pupo.


Philomina to je eni odun marunlelogbon to n gbe ni Jimoh Aliyu, lopopona Adebayo, niluu Ado-Ekiti, salaye pe nigba kan lodun 2012 loko oun le oun jade pelu ada, gbogbo wahala ohun lo si mu koun kuro nile.

Obinrin ohun to ti bimo marun-un fun oko re so pe opolopo igba ni okunrin naa maa n lu oun nitori boun se ko lati je ko ba oun lajosepo ati bi oun se taku lati ko owo-osu oun fun un.

O ni ita gbangba loju awon araadugbo lokunrin naa ti maa n lu oun, ti yoo si da ogbe soun lara yannayanna.

O lokunrin naa ki i bikita nipa itoju awon omo, bee ni ki i sanwo ileewe tabi fowo ounje sile.

Sugbon gbogbo igba to ba ti ni owo lowo, se lo maa n gba ile oti lo, ti yoo si muti kanrin pelu siga. O nigbeyawo ohun ti su oun, kile-ejo tu awon ka.

Sugbon ninu oro tie, Bonaventure to je eni odun marundinlaaadota to fi ojule keji, opopona Oke Oniyo, niluu Ado-Ekiti, sebugbe so pe lati odun 2012 niyawo oun ti pa oun ti. O lohun to maa n saaba fa ija ni bi obinrin naa se maa n ji owo oun.

O tako gbogbo esun tobinrin naa fi kan an pe ki i toju ile pelu bo se so pe ojoojumo loun maa n fun obinrin naa lowo ounje. O ni se ni iyawo oun gbe foonu oun pelu awon ebun igbeyawo awon sa lo.

O waa ro ile-ejo lati tu igbeyawo naa ka, won si ko awon omo maraarun foun.

Aare ile-ejo ohun, Joseph Ogunsemi, so pe o han pe igbeyawo olodun merindinlogun ohun ti daru patapata, nitori idi eyi, ile-ejo tu igbeyawo naa ka.

Nipa oro awon omo maraarun-un tigbeyawo naa so, ile-ejo ko Kinsley ati Kenneth fun okunrin naa, sugbon Mercy ati Favor yoo maa gbe odo iya-iya won ti i se Iyaafin Comfort.

Ile-ejo pase ki Love maa gbe pelu egbon oko, bakan naa lokunrin ohun yoo maa san egberun meji naira losoosu nipase ile-ejo fawon omo naa, awon obi won yoo si maa gbaruku ti eto eko won.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:39:39 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara:
Asiri Nla Alaaji Amosa So Itan Igbesi Aye Re, O ni: Anjonnu Ni Mo Fe Niyawo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Aka-re-rin, Irohin Kayeefi Ati Oro-Apara



"Oko Mi Fi Pata Mi Soogun Owo — Philomina" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com