A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn.
Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe.
Ìyàwó Fir‘aon wí pé: "Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ." Wọn kò sì fura.
Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: "Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe."
Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: "Kí l'ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?" Wọ́n sọ pé: "A kò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlágbà arúgbó sì ni bàbá wa."
Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: "Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."
Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?" Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: "Òpìdán méjì tó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n)." Wọ́n sì tún wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn)."
Sọ pé: "Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: "A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀."
Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún.
Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí.
A sọ (fún wọn) pé: "Ẹ pe àwọn òrìṣà yín." Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n.)
Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni gbogbo ẹyìn ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí wá." Nígbà̀náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.
Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn tó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l'ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (ìyẹn pàápàá bíbẹ Allāhu -subhānu wa ta‘ālā -). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.