Prev  

20. Surah Tâ­Hâ. سورة طه

  Next  



1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
طه
Ta-ha

Yoruba
 
Tọ̄ hā. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)

Ayah  20:2  الأية
مَا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْقُرْآنَ لِتَشْقَىٰ
Ma anzalna AAalayka alqur-analitashqa

Yoruba
 
A kò sọ al-Ƙur'ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.

Ayah  20:3  الأية
إِلَّا تَذْكِرَةً لِّمَن يَخْشَىٰ
Illa tathkiratan liman yakhsha

Yoruba
 
Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

Ayah  20:4  الأية
تَنزِيلًا مِّمَّنْ خَلَقَ الْأَرْضَ وَالسَّمَاوَاتِ الْعُلَى
Tanzeelan mimman khalaqa al-arda wassamawatialAAula

Yoruba
 
(Ó jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.

Ayah  20:5  الأية
الرَّحْمَٰنُ عَلَى الْعَرْشِ اسْتَوَىٰ
Arrahmanu AAalaalAAarshi istawa

Yoruba
 
Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.

Ayah  20:6  الأية
لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَمَا تَحْتَ الثَّرَىٰ
Lahu ma fee assamawatiwama fee al-ardi wama baynahuma wamatahta aththara

Yoruba
 
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀, ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun tó wà lábẹ́ ilẹ̀.

Ayah  20:7  الأية
وَإِن تَجْهَرْ بِالْقَوْلِ فَإِنَّهُ يَعْلَمُ السِّرَّ وَأَخْفَى
Wa-in tajhar bilqawli fa-innahuyaAAlamu assirra waakhfa

Yoruba
 
Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.

Ayah  20:8  الأية
اللهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ لَهُ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ
Allahu la ilaha illahuwa lahu al-asmao alhusna

Yoruba
 
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ.

Ayah  20:9  الأية
وَهَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ مُوسَىٰ
Wahal ataka hadeethu moosa

Yoruba
 
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Ayah  20:10  الأية
إِذْ رَأَىٰ نَارًا فَقَالَ لِأَهْلِهِ امْكُثُوا إِنِّي آنَسْتُ نَارًا لَّعَلِّي آتِيكُم مِّنْهَا بِقَبَسٍ أَوْ أَجِدُ عَلَى النَّارِ هُدًى
Ith raa naran faqalali-ahlihi omkuthoo innee anastu naran laAAallee ateekumminha biqabasin aw ajidu AAala annarihuda

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: "Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí́n̄g rí ògúnná mú wá fún yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà."

Ayah  20:11  الأية
فَلَمَّا أَتَاهَا نُودِيَ يَا مُوسَىٰ
Falamma ataha noodiya yamoosa

Yoruba
 
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é "Mūsā,

Ayah  20:12  الأية
إِنِّي أَنَا رَبُّكَ فَاخْلَعْ نَعْلَيْكَ ۖ إِنَّكَ بِالْوَادِ الْمُقَدَّسِ طُوًى
Innee ana rabbuka fakhlaAAnaAAlayka innaka bilwadi almuqaddasi tuwa

Yoruba
 
Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.

Ayah  20:13  الأية
وَأَنَا اخْتَرْتُكَ فَاسْتَمِعْ لِمَا يُوحَىٰ
Waana ikhtartuka fastamiAAlima yooha

Yoruba
 
Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí.

Ayah  20:14  الأية
إِنَّنِي أَنَا اللهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنَا فَاعْبُدْنِي وَأَقِمِ الصَّلَاةَ لِذِكْرِي
Innanee ana Allahu lailaha illa ana faAAbudnee waaqimi assalatalithikree

Yoruba
 
Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.

Ayah  20:15  الأية
إِنَّ السَّاعَةَ آتِيَةٌ أَكَادُ أُخْفِيهَا لِتُجْزَىٰ كُلُّ نَفْسٍ بِمَا تَسْعَىٰ
Inna assaAAata atiyatunakadu okhfeeha litujza kullu nafsin bimatasAAa

Yoruba
 
Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hàn rẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì kan. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́.

Ayah  20:16  الأية
فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنْهَا مَن لَّا يُؤْمِنُ بِهَا وَاتَّبَعَ هَوَاهُ فَتَرْدَىٰ
Fala yasuddannaka AAanhaman la yu/minu biha wattabaAAa hawahufatarda

Yoruba
 
Nítorí náà, ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun.

Ayah  20:17  الأية
وَمَا تِلْكَ بِيَمِينِكَ يَا مُوسَىٰ
Wama tilka biyameenika ya moosa

Yoruba
 
Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā?"

Ayah  20:18  الأية
قَالَ هِيَ عَصَايَ أَتَوَكَّأُ عَلَيْهَا وَأَهُشُّ بِهَا عَلَىٰ غَنَمِي وَلِيَ فِيهَا مَآرِبُ أُخْرَىٰ
Qala hiya AAasaya atawakkaoAAalayha waahushshu biha AAala ghanameewaliya feeha maaribu okhra

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn."

Ayah  20:19  الأية
قَالَ أَلْقِهَا يَا مُوسَىٰ
Qala alqiha ya moosa

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Jù ú sílẹ̀, Mūsā."

Ayah  20:20  الأية
فَأَلْقَاهَا فَإِذَا هِيَ حَيَّةٌ تَسْعَىٰ
Faalqaha fa-itha hiya hayyatuntasAAa

Yoruba
 
Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò tó ń sáré.

Ayah  20:21  الأية
قَالَ خُذْهَا وَلَا تَخَفْ ۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا الْأُولَىٰ
Qala khuthha walatakhaf sanuAAeeduha seerataha al-oola

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́.

Ayah  20:22  الأية
وَاضْمُمْ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ آيَةً أُخْرَىٰ
Wadmum yadaka ila janahikatakhruj baydaa min ghayri soo-in ayatan okhra

Yoruba
 
Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn.

Ayah  20:23  الأية
لِنُرِيَكَ مِنْ آيَاتِنَا الْكُبْرَى
Linuriyaka min ayatinaalkubra

Yoruba
 
Kí Á lè fi èyí tó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́.

Ayah  20:24  الأية
اذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ
Ithhab ila firAAawna innahu tagha

Yoruba
 
Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà."

Ayah  20:25  الأية
قَالَ رَبِّ اشْرَحْ لِي صَدْرِي
Qala rabbi ishrah lee sadree

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi.

Ayah  20:26  الأية
وَيَسِّرْ لِي أَمْرِي
Wayassir lee amree

Yoruba
 
Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi.

Ayah  20:27  الأية
وَاحْلُلْ عُقْدَةً مِّن لِّسَانِي
Wahlul AAuqdatan min lisanee

Yoruba
 
Tú kókó orí ahọ́n mi

Ayah  20:28  الأية
يَفْقَهُوا قَوْلِي
Yafqahoo qawlee

Yoruba
 
Kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé.

Ayah  20:29  الأية
وَاجْعَل لِّي وَزِيرًا مِّنْ أَهْلِي
WajAAal lee wazeeran min ahlee

Yoruba
 
Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi,

Ayah  20:30  الأية
هَارُونَ أَخِي
Haroona akhee

Yoruba
 
Hārūn, arákùnrin mi ni.

Ayah  20:31  الأية
اشْدُدْ بِهِ أَزْرِي
Oshdud bihi azree

Yoruba
 
Fi kún mi lọ́wọ́.

Ayah  20:32  الأية
وَأَشْرِكْهُ فِي أَمْرِي
Waashrik-hu fee amree

Yoruba
 
Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi

Ayah  20:33  الأية
كَيْ نُسَبِّحَكَ كَثِيرًا
Kay nusabbihaka katheera

Yoruba
 
Torí kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀,

Ayah  20:34  الأية
وَنَذْكُرَكَ كَثِيرًا
Wanathkuraka katheera

Yoruba
 
Kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

Ayah  20:35  الأية
إِنَّكَ كُنتَ بِنَا بَصِيرًا
Innaka kunta bina baseera

Yoruba
 
Dájúdájú Ìwọ ń rí wa."

Ayah  20:36  الأية
قَالَ قَدْ أُوتِيتَ سُؤْلَكَ يَا مُوسَىٰ
Qala qad ooteeta su/laka yamoosa

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā.

Ayah  20:37  الأية
وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَيْكَ مَرَّةً أُخْرَىٰ
Walaqad mananna AAalayka marratanokhra

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí.

Ayah  20:38  الأية
إِذْ أَوْحَيْنَا إِلَىٰ أُمِّكَ مَا يُوحَىٰ
Ith awhayna ilaommika ma yooha

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ

Ayah  20:39  الأية
أَنِ اقْذِفِيهِ فِي التَّابُوتِ فَاقْذِفِيهِ فِي الْيَمِّ فَلْيُلْقِهِ الْيَمُّ بِالسَّاحِلِ يَأْخُذْهُ عَدُوٌّ لِّي وَعَدُوٌّ لَّهُ ۚ وَأَلْقَيْتُ عَلَيْكَ مَحَبَّةً مِّنِّي وَلِتُصْنَعَ عَلَىٰ عَيْنِي
Ani iqthifeehi fee attabootifaqthifeehi fee alyammi falyulqihi alyammu bissahiliya/khuthhu AAaduwwun lee waAAaduwwun lahu waalqaytuAAalayka mahabbatan minnee walitusnaAAa AAalaAAaynee

Yoruba
 
Pé: "Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e." Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi."

Ayah  20:40  الأية
إِذْ تَمْشِي أُخْتُكَ فَتَقُولُ هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ مَن يَكْفُلُهُ ۖ فَرَجَعْنَاكَ إِلَىٰ أُمِّكَ كَيْ تَقَرَّ عَيْنُهَا وَلَا تَحْزَنَ ۚ وَقَتَلْتَ نَفْسًا فَنَجَّيْنَاكَ مِنَ الْغَمِّ وَفَتَنَّاكَ فُتُونًا ۚ فَلَبِثْتَ سِنِينَ فِي أَهْلِ مَدْيَنَ ثُمَّ جِئْتَ عَلَىٰ قَدَرٍ يَا مُوسَىٰ
Ith tamshee okhtuka fataqoolu haladullukum AAala man yakfuluhu farajaAAnaka ilaommika kay taqarra AAaynuha wala tahzanawaqatalta nafsan fanajjaynaka mina alghammi wafatannakafutoonan falabithta sineena fee ahli madyana thumma ji/ta AAalaqadarin ya moosa

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì ń sọ pé: "Ṣé kí n̄g júwe yín sí ẹni tí ó máa gbà á tọ́?" A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, àti pé kí ò má baà banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.

Ayah  20:41  الأية
وَاصْطَنَعْتُكَ لِنَفْسِي
WastanaAAtuka linafsee

Yoruba
 
Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi.

Ayah  20:42  الأية
اذْهَبْ أَنتَ وَأَخُوكَ بِآيَاتِي وَلَا تَنِيَا فِي ذِكْرِي
Ithhab anta waakhooka bi-ayateewala taniya fee thikree

Yoruba
 
Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ níbi ìrántí Mi.

Ayah  20:43  الأية
اذْهَبَا إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ
Ithhaba ila firAAawnainnahu tagha

Yoruba
 
Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

Ayah  20:44  الأية
فَقُولَا لَهُ قَوْلًا لَّيِّنًا لَّعَلَّهُ يَتَذَكَّرُ أَوْ يَخْشَىٰ
Faqoola lahu qawlan layyinanlaAAallahu yatathakkaru aw yakhsha

Yoruba
 
Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi)."

Ayah  20:45  الأية
قَالَا رَبَّنَا إِنَّنَا نَخَافُ أَن يَفْرُطَ عَلَيْنَا أَوْ أَن يَطْغَىٰ
Qala rabbana innananakhafu an yafruta AAalayna aw an yatgha

Yoruba
 
Àwọn méjèèjì sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-ààlà."

Ayah  20:46  الأية
قَالَ لَا تَخَافَا ۖ إِنَّنِي مَعَكُمَا أَسْمَعُ وَأَرَىٰ
Qala la takhafainnanee maAAakuma asmaAAu waara

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín)."

Ayah  20:47  الأية
فَأْتِيَاهُ فَقُولَا إِنَّا رَسُولَا رَبِّكَ فَأَرْسِلْ مَعَنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ وَلَا تُعَذِّبْهُمْ ۖ قَدْ جِئْنَاكَ بِآيَةٍ مِّن رَّبِّكَ ۖ وَالسَّلَامُ عَلَىٰ مَنِ اتَّبَعَ الْهُدَىٰ
Fa/tiyahu faqoola innarasoola rabbika faarsil maAAana banee isra-eelawala tuAAaththibhum qad ji/naka bi-ayatinmin rabbika wassalamu AAala mani ittabaAAaalhuda

Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: "Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà náà.

Ayah  20:48  الأية
إِنَّا قَدْ أُوحِيَ إِلَيْنَا أَنَّ الْعَذَابَ عَلَىٰ مَن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
Inna qad oohiya ilaynaanna alAAathaba AAala man kaththaba watawalla

Yoruba
 
Dájúdájú wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé, dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i."

Ayah  20:49  الأية
قَالَ فَمَن رَّبُّكُمَا يَا مُوسَىٰ
Qala faman rabbukuma yamoosa

Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?"

Ayah  20:50  الأية
قَالَ رَبُّنَا الَّذِي أَعْطَىٰ كُلَّ شَيْءٍ خَلْقَهُ ثُمَّ هَدَىٰ
Qala rabbuna allatheeaAAta kulla shay-in khalqahu thumma hada

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà."

Ayah  20:51  الأية
قَالَ فَمَا بَالُ الْقُرُونِ الْأُولَىٰ
Qala fama balualqurooni al-oola

Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Kí ló mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?"

Ayah  20:52  الأية
قَالَ عِلْمُهَا عِندَ رَبِّي فِي كِتَابٍ ۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّي وَلَا يَنسَى
Qala AAilmuha AAinda rabbeefee kitabin la yadillu rabbee walayansa

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé.

Ayah  20:53  الأية
الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ مَهْدًا وَسَلَكَ لَكُمْ فِيهَا سُبُلًا وَأَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِّن نَّبَاتٍ شَتَّىٰ
Allathee jaAAala lakumu al-ardamahdan wasalaka lakum feeha subulan waanzala mina assama-imaan faakhrajna bihi azwajan min nabatinshatta

Yoruba
 
(Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fún yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ayah  20:54  الأية
كُلُوا وَارْعَوْا أَنْعَامَكُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّأُولِي النُّهَىٰ
Kuloo warAAaw anAAamakum innafee thalika laayatin li-olee annuha

Yoruba
 
Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

Ayah  20:55  الأية
مِنْهَا خَلَقْنَاكُمْ وَفِيهَا نُعِيدُكُمْ وَمِنْهَا نُخْرِجُكُمْ تَارَةً أُخْرَىٰ
Minha khalaqnakum wafeehanuAAeedukum waminha nukhrijukum taratan okhra

Yoruba
 
Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn."

Ayah  20:56  الأية
وَلَقَدْ أَرَيْنَاهُ آيَاتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ
Walaqad araynahu ayatinakullaha fakaththaba waaba

Yoruba
 
Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é ní irọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀.

Ayah  20:57  الأية
قَالَ أَجِئْتَنَا لِتُخْرِجَنَا مِنْ أَرْضِنَا بِسِحْرِكَ يَا مُوسَىٰ
Qala aji/tana litukhrijanamin ardina bisihrika ya moosa

Yoruba
 
Ó wí pé: "Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā?

Ayah  20:58  الأية
فَلَنَأْتِيَنَّكَ بِسِحْرٍ مِّثْلِهِ فَاجْعَلْ بَيْنَنَا وَبَيْنَكَ مَوْعِدًا لَّا نُخْلِفُهُ نَحْنُ وَلَا أَنتَ مَكَانًا سُوًى
Falana/tiyannaka bisihrin mithlihi fajAAalbaynana wabaynaka mawAAidan la nukhlifuhu nahnuwala anta makanan suwa

Yoruba
 
Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àyè àdéhùn ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó jẹ́) àyè kan tí kò níí fì sọ́dọ̀ igun méjèèjì."

Ayah  20:59  الأية
قَالَ مَوْعِدُكُمْ يَوْمُ الزِّينَةِ وَأَن يُحْشَرَ النَّاسُ ضُحًى
Qala mawAAidukum yawmu azzeenatiwaan yuhshara annasu duha

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta."

Ayah  20:60  الأية
فَتَوَلَّىٰ فِرْعَوْنُ فَجَمَعَ كَيْدَهُ ثُمَّ أَتَىٰ
Fatawalla firAAawnu fajamaAAa kaydahuthumma ata

Yoruba
 
Fir‘aon pẹ̀yìndà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀).

Ayah  20:61  الأية
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ وَيْلَكُمْ لَا تَفْتَرُوا عَلَى اللهِ كَذِبًا فَيُسْحِتَكُم بِعَذَابٍ ۖ وَقَدْ خَابَ مَنِ افْتَرَىٰ
Qala lahum moosa waylakum lataftaroo AAala Allahi kathiban fayushitakumbiAAathabin waqad khaba mani iftara

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti pòfo."

Ayah  20:62  الأية
فَتَنَازَعُوا أَمْرَهُم بَيْنَهُمْ وَأَسَرُّوا النَّجْوَىٰ
FatanazaAAoo amrahum baynahumwaasarroo annajwa

Yoruba
 
Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀.

Ayah  20:63  الأية
قَالُوا إِنْ هَٰذَانِ لَسَاحِرَانِ يُرِيدَانِ أَن يُخْرِجَاكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِمَا وَيَذْهَبَا بِطَرِيقَتِكُمُ الْمُثْلَىٰ
Qaloo in hathani lasahiraniyureedani an yukhrijakum min ardikum bisihrihimawayathhaba bitareeqatikumu almuthla

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín tó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́.

Ayah  20:64  الأية
فَأَجْمِعُوا كَيْدَكُمْ ثُمَّ ائْتُوا صَفًّا ۚ وَقَدْ أَفْلَحَ الْيَوْمَ مَنِ اسْتَعْلَىٰ
FaajmiAAoo kaydakum thumma i/too saffanwaqad aflaha alyawma mani istaAAla

Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè."

Ayah  20:65  الأية
قَالُوا يَا مُوسَىٰ إِمَّا أَن تُلْقِيَ وَإِمَّا أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنْ أَلْقَىٰ
Qaloo ya moosa immaan tulqiya wa-imma an nakoona awwala man alqa

Yoruba
 
(Àwọn òpìdán) wí pé: "Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀."

Ayah  20:66  الأية
قَالَ بَلْ أَلْقُوا ۖ فَإِذَا حِبَالُهُمْ وَعِصِيُّهُمْ يُخَيَّلُ إِلَيْهِ مِن سِحْرِهِمْ أَنَّهَا تَسْعَىٰ
Qala bal alqoo fa-itha hibaluhumwaAAisiyyuhum yukhayyalu ilayhi min sihrihim annahatasAAa

Yoruba
 
(Mūsā) sọ pé: "Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná)." Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré.

Ayah  20:67  الأية
فَأَوْجَسَ فِي نَفْسِهِ خِيفَةً مُّوسَىٰ
Faawjasa fee nafsihi kheefatan moosa

Yoruba
 
Ìbẹ̀rù wọn sì mú (Ànábì) Mūsā.

Ayah  20:68  الأية
قُلْنَا لَا تَخَفْ إِنَّكَ أَنتَ الْأَعْلَىٰ
Qulna la takhaf innaka antaal-aAAla

Yoruba
 
A sọ pé: "Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè.

Ayah  20:69  الأية
وَأَلْقِ مَا فِي يَمِينِكَ تَلْقَفْ مَا صَنَعُوا ۖ إِنَّمَا صَنَعُوا كَيْدُ سَاحِرٍ ۖ وَلَا يُفْلِحُ السَّاحِرُ حَيْثُ أَتَىٰ
Waalqi ma fee yameenika talqaf masanaAAoo innama sanaAAoo kaydu sahirinwala yuflihu assahiru haythuata

Yoruba
 
Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé."

Ayah  20:70  الأية
فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سُجَّدًا قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ هَارُونَ وَمُوسَىٰ
Faolqiya assaharatu sujjadanqaloo amanna birabbi haroona wamoosa

Yoruba
 
Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā."

Ayah  20:71  الأية
قَالَ آمَنتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ ۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ فِي جُذُوعِ النَّخْلِ وَلَتَعْلَمُنَّ أَيُّنَا أَشَدُّ عَذَابًا وَأَبْقَىٰ
Qala amantum lahu qabla an athanalakum innahu lakabeerukumu allathee AAallamakumu assihrafalaoqattiAAanna aydiyakum waarjulakum min khilafinwalaosallibannakum fee juthooAAi annakhliwalataAAlamunna ayyuna ashaddu AAathaban waabqa

Yoruba
 
(Fir‘aon) wí pé: "Ṣé ẹ ti gbàfà fún un ṣíwájú kí èmi tó yọ̀ǹda fún yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ."

Ayah  20:72  الأية
قَالُوا لَن نُّؤْثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَاءَنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالَّذِي فَطَرَنَا ۖ فَاقْضِ مَا أَنتَ قَاضٍ ۖ إِنَّمَا تَقْضِي هَٰذِهِ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا
Qaloo lan nu/thiraka AAala majaana mina albayyinati wallatheefatarana faqdi ma anta qadininnama taqdee hathihi alhayataaddunya

Yoruba
 
(Àwọn òpìdán) sọ pé: "Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí tó dájú, (a kò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá ní ẹjọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́.

Ayah  20:73  الأية
إِنَّا آمَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغْفِرَ لَنَا خَطَايَانَا وَمَا أَكْرَهْتَنَا عَلَيْهِ مِنَ السِّحْرِ ۗ وَاللهُ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ
Inna amanna birabbinaliyaghfira lana khatayana wamaakrahtana AAalayhi mina assihri wallahukhayrun waabqa

Yoruba
 
Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú Olúwa wa nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé.

Ayah  20:74  الأية
إِنَّهُ مَن يَأْتِ رَبَّهُ مُجْرِمًا فَإِنَّ لَهُ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ
Innahu man ya/ti rabbahu mujriman fa-innalahu jahannama la yamootu feeha wala yahya

Yoruba
 
Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè.

Ayah  20:75  الأية
وَمَن يَأْتِهِ مُؤْمِنًا قَدْ عَمِلَ الصَّالِحَاتِ فَأُولَٰئِكَ لَهُمُ الدَّرَجَاتُ الْعُلَىٰ
Waman ya/tihi mu/minan qad AAamila assalihatifaola-ika lahumu addarajatu alAAula

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (ní ipò) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún.

Ayah  20:76  الأية
جَنَّاتُ عَدْنٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ مَن تَزَكَّىٰ
Jannatu AAadnin tajree min tahtihaal-anharu khalideena feeha wathalikajazao man tazakka

Yoruba
 
(Ohun ni) àwọn Ọgbà ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀)."

Ayah  20:77  الأية
وَلَقَدْ أَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي فَاضْرِبْ لَهُمْ طَرِيقًا فِي الْبَحْرِ يَبَسًا لَّا تَخَافُ دَرَكًا وَلَا تَخْشَىٰ
Walaqad awhayna ilamoosa an asri biAAibadee fadriblahum tareeqan fee albahri yabasan la takhafudarakan wala takhsha

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: "Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ kan nínú omi òkun. O ò níí bẹ̀rù àlébá, o ò sì níí páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun)."

Ayah  20:78  الأية
فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ بِجُنُودِهِ فَغَشِيَهُم مِّنَ الْيَمِّ مَا غَشِيَهُمْ
FaatbaAAahum firAAawnu bijunoodihifaghashiyahum mina alyammi ma ghashiyahum

Yoruba
 
Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.

Ayah  20:79  الأية
وَأَضَلَّ فِرْعَوْنُ قَوْمَهُ وَمَا هَدَىٰ
Waadalla firAAawnu qawmahu wamahada

Yoruba
 
Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà.

Ayah  20:80  الأية
يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ قَدْ أَنجَيْنَاكُم مِّنْ عَدُوِّكُمْ وَوَاعَدْنَاكُمْ جَانِبَ الطُّورِ الْأَيْمَنَ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكُمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ
Ya banee isra-eela qad anjaynakummin AAaduwwikum wawaAAadnakum janiba attoorial-aymana wanazzalna AAalaykumu almanna wassalwa

Yoruba
 
Ẹ̀yin ọmọ 'Isrọ̄'īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún (Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì ní ìwọ̀ òòrùn). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín.

Ayah  20:81  الأية
كُلُوا مِن طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ وَلَا تَطْغَوْا فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبِي ۖ وَمَن يَحْلِلْ عَلَيْهِ غَضَبِي فَقَدْ هَوَىٰ
Kuloo min tayyibati marazaqnakum wala tatghaw feehi fayahillaAAalaykum ghadabee waman yahlil AAalayhi ghadabeefaqad hawa

Yoruba
 
Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fún yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu ààlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).

Ayah  20:82  الأية
وَإِنِّي لَغَفَّارٌ لِّمَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ صَالِحًا ثُمَّ اهْتَدَىٰ
Wa-innee laghaffarun liman tabawaamana waAAamila salihan thumma ihtada

Yoruba
 
Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.

Ayah  20:83  الأية
وَمَا أَعْجَلَكَ عَن قَوْمِكَ يَا مُوسَىٰ
Wama aAAjalaka AAan qawmika yamoosa

Yoruba
 
Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?

Ayah  20:84  الأية
قَالَ هُمْ أُولَاءِ عَلَىٰ أَثَرِي وَعَجِلْتُ إِلَيْكَ رَبِّ لِتَرْضَىٰ
Qala hum ola-i AAalaatharee waAAajiltu ilayka rabbi litarda

Yoruba
 
Ó sọ pé: "Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi."

Ayah  20:85  الأية
قَالَ فَإِنَّا قَدْ فَتَنَّا قَوْمَكَ مِن بَعْدِكَ وَأَضَلَّهُمُ السَّامِرِيُّ
Qala fa-inna qad fatannaqawmaka min baAAdika waadallahumu assamiriy

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà."

Ayah  20:86  الأية
فَرَجَعَ مُوسَىٰ إِلَىٰ قَوْمِهِ غَضْبَانَ أَسِفًا ۚ قَالَ يَا قَوْمِ أَلَمْ يَعِدْكُمْ رَبُّكُمْ وَعْدًا حَسَنًا ۚ أَفَطَالَ عَلَيْكُمُ الْعَهْدُ أَمْ أَرَدتُّمْ أَن يَحِلَّ عَلَيْكُمْ غَضَبٌ مِّن رَّبِّكُمْ فَأَخْلَفْتُم مَّوْعِدِي
FarajaAAa moosa ila qawmihighadbana asifan qala ya qawmi alamyaAAidkum rabbukum waAAdan hasanan afatalaAAalaykumu alAAahdu am aradtum an yahilla AAalaykum ghadabunmin rabbikum faakhlaftum mawAAidee

Yoruba
 
(Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?"

Ayah  20:87  الأية
قَالُوا مَا أَخْلَفْنَا مَوْعِدَكَ بِمَلْكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلْنَا أَوْزَارًا مِّن زِينَةِ الْقَوْمِ فَقَذَفْنَاهَا فَكَذَٰلِكَ أَلْقَى السَّامِرِيُّ
Qaloo ma akhlafnamawAAidaka bimalkina walakinna hummilnaawzaran min zeenati alqawmi faqathafnahafakathalika alqa assamiriy

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀."

Ayah  20:88  الأية
فَأَخْرَجَ لَهُمْ عِجْلًا جَسَدًا لَّهُ خُوَارٌ فَقَالُوا هَٰذَا إِلَٰهُكُمْ وَإِلَٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِيَ
Faakhraja lahum AAijlan jasadan lahu khuwarunfaqaloo hatha ilahukum wa-ilahu moosafanasiy

Yoruba
 
Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, tó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: "Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀)."

Ayah  20:89  الأية
أَفَلَا يَرَوْنَ أَلَّا يَرْجِعُ إِلَيْهِمْ قَوْلًا وَلَا يَمْلِكُ لَهُمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا
Afala yarawna alla yarjiAAuilayhim qawlan wala yamliku lahum darran walanafAAa

Yoruba
 
Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn!

Ayah  20:90  الأية
وَلَقَدْ قَالَ لَهُمْ هَارُونُ مِن قَبْلُ يَا قَوْمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِ ۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ الرَّحْمَٰنُ فَاتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوا أَمْرِي
Walaqad qala lahum haroonu minqablu ya qawmi innama futintum bihi wa-innarabbakumu arrahmanu fattabiAAooneewaateeAAoo amree

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fún yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi."

Ayah  20:91  الأية
قَالُوا لَن نَّبْرَحَ عَلَيْهِ عَاكِفِينَ حَتَّىٰ يَرْجِعَ إِلَيْنَا مُوسَىٰ
Qaloo lan nabraha AAalayhi AAakifeenahatta yarjiAAa ilayna moosa

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ tí a óò máa jọ́sìn fún un títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa."

Ayah  20:92  الأية
قَالَ يَا هَارُونُ مَا مَنَعَكَ إِذْ رَأَيْتَهُمْ ضَلُّوا
Qala ya haroonu mamanaAAaka ith raaytahum dalloo

Yoruba
 
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà

Ayah  20:93  الأية
أَلَّا تَتَّبِعَنِ ۖ أَفَعَصَيْتَ أَمْرِي
Alla tattabiAAani afaAAasaytaamree

Yoruba
 
Láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni?"

Ayah  20:94  الأية
قَالَ يَا ابْنَ أُمَّ لَا تَأْخُذْ بِلِحْيَتِي وَلَا بِرَأْسِي ۖ إِنِّي خَشِيتُ أَن تَقُولَ فَرَّقْتَ بَيْنَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَلَمْ تَرْقُبْ قَوْلِي
Qala yabnaomma la ta/khuthbilihyatee wala bira/see innee khasheetu an taqoolafarraqta bayna banee isra-eela walam tarqub qawlee

Yoruba
 
(Ànábì Hārūn) sọ pé: "Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi mú mi, (má ṣe fi irun) orí mi mú mi. Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi.'"

Ayah  20:95  الأية
قَالَ فَمَا خَطْبُكَ يَا سَامِرِيُّ
Qala fama khatbuka yasamiriy

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?"

Ayah  20:96  الأية
قَالَ بَصُرْتُ بِمَا لَمْ يَبْصُرُوا بِهِ فَقَبَضْتُ قَبْضَةً مِّنْ أَثَرِ الرَّسُولِ فَنَبَذْتُهَا وَكَذَٰلِكَ سَوَّلَتْ لِي نَفْسِي
Qala basurtu bima lamyabsuroo bihi faqabadtu qabdatan min athariarrasooli fanabathtuha wakathalikasawwalat lee nafsee

Yoruba
 
(Sāmiriyy) wí pé: "Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi."

Ayah  20:97  الأية
قَالَ فَاذْهَبْ فَإِنَّ لَكَ فِي الْحَيَاةِ أَن تَقُولَ لَا مِسَاسَ ۖ وَإِنَّ لَكَ مَوْعِدًا لَّن تُخْلَفَهُ ۖ وَانظُرْ إِلَىٰ إِلَٰهِكَ الَّذِي ظَلْتَ عَلَيْهِ عَاكِفًا ۖ لَّنُحَرِّقَنَّهُ ثُمَّ لَنَنسِفَنَّهُ فِي الْيَمِّ نَسْفًا
Qala fathhab fa-innalaka fee alhayati an taqoola la misasawa-inna laka mawAAidan lan tukhlafahu wanthurila ilahika allathee thaltaAAalayhi AAakifan lanuharriqannahu thummalanansifannahu fee alyammi nasfa

Yoruba
 
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, "Má fi ara kàn mí". Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn tí ò ń bọ, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú odò.

Ayah  20:98  الأية
إِنَّمَا إِلَٰهُكُمُ اللهُ الَّذِي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ وَسِعَ كُلَّ شَيْءٍ عِلْمًا
Innama ilahukumu Allahuallathee la ilaha illa huwa wasiAAakulla shay-in AAilma

Yoruba
 
Ọlọ́hun yín ni Allāhu nìkan, ẹni tí kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  20:99  الأية
كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيْكَ مِنْ أَنبَاءِ مَا قَدْ سَبَقَ ۚ وَقَدْ آتَيْنَاكَ مِن لَّدُنَّا ذِكْرًا
Kathalika naqussu AAalayka minanba-i ma qad sabaqa waqad ataynakamin ladunna thikra

Yoruba
 
Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur'ān).

Ayah  20:100  الأية
مَّنْ أَعْرَضَ عَنْهُ فَإِنَّهُ يَحْمِلُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وِزْرًا
Man aAArada AAanhu fa-innahu yahmiluyawma alqiyamati wizra

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde.

Ayah  20:101  الأية
خَالِدِينَ فِيهِ ۖ وَسَاءَ لَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ حِمْلًا
Khalideena feehi wasaa lahumyawma alqiyamati himla

Yoruba
 
Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde.

Ayah  20:102  الأية
يَوْمَ يُنفَخُ فِي الصُّورِ ۚ وَنَحْشُرُ الْمُجْرِمِينَ يَوْمَئِذٍ زُرْقًا
Yawma yunfakhu fee assooriwanahshuru almujrimeena yawma-ithin zurqa

Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, tí ojú wọn yó sì dúdú batakun.

Ayah  20:103  الأية
يَتَخَافَتُونَ بَيْنَهُمْ إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا عَشْرًا
Yatakhafatoona baynahum in labithtumilla AAashra

Yoruba
 
Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: "Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá."

Ayah  20:104  الأية
نَّحْنُ أَعْلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذْ يَقُولُ أَمْثَلُهُمْ طَرِيقَةً إِن لَّبِثْتُمْ إِلَّا يَوْمًا
Nahnu aAAlamu bima yaqooloonaith yaqoolu amthaluhum tareeqatan in labithtum illayawma

Yoruba
 
Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni tí ọpọlọ rẹ̀ pé jùlọ nínú wọn wí pé: "Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan."

Ayah  20:105  الأية
وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْجِبَالِ فَقُلْ يَنسِفُهَا رَبِّي نَسْفًا
Wayas-aloonaka AAani aljibali faqulyansifuha rabbee nasfa

Yoruba
 
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: "Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù pátápátá.

Ayah  20:106  الأية
فَيَذَرُهَا قَاعًا صَفْصَفًا
Fayatharuha qaAAan safsafa

Yoruba
 
Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa.

Ayah  20:107  الأية
لَّا تَرَىٰ فِيهَا عِوَجًا وَلَا أَمْتًا
La tara feeha AAiwajanwala amta

Yoruba
 
O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀.

Ayah  20:108  الأية
يَوْمَئِذٍ يَتَّبِعُونَ الدَّاعِيَ لَا عِوَجَ لَهُ ۖ وَخَشَعَتِ الْأَصْوَاتُ لِلرَّحْمَٰنِ فَلَا تَسْمَعُ إِلَّا هَمْسًا
Yawma-ithin yattabiAAoona addaAAiyala AAiwaja lahu wakhashaAAati al-aswatu lirrahmanifala tasmaAAu illa hamsa

Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀.

Ayah  20:109  الأية
يَوْمَئِذٍ لَّا تَنفَعُ الشَّفَاعَةُ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ الرَّحْمَٰنُ وَرَضِيَ لَهُ قَوْلًا
Yawma-ithin la tanfaAAu ashshafaAAatuilla man athina lahu arrahmanuwaradiya lahu qawla

Yoruba
 
Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un.

Ayah  20:110  الأية
يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِ عِلْمًا
YaAAlamu ma bayna aydeehim wamakhalfahum wala yuheetoona bihi AAilma

Yoruba
 
(Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀.

Ayah  20:111  الأية
وَعَنَتِ الْوُجُوهُ لِلْحَيِّ الْقَيُّومِ ۖ وَقَدْ خَابَ مَنْ حَمَلَ ظُلْمًا
WaAAanati alwujoohu lilhayyialqayyoomi waqad khaba man hamala thulma

Yoruba
 
Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo.

Ayah  20:112  الأية
وَمَن يَعْمَلْ مِنَ الصَّالِحَاتِ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَا يَخَافُ ظُلْمًا وَلَا هَضْمًا
Waman yaAAmal mina assalihatiwahuwa mu/minun fala yakhafu thulmanwala hadma

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu).

Ayah  20:113  الأية
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا وَصَرَّفْنَا فِيهِ مِنَ الْوَعِيدِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ أَوْ يُحْدِثُ لَهُمْ ذِكْرًا
Wakathalika anzalnahu qur-ananAAarabiyyan wasarrafna feehi mina alwaAAeedilaAAallahum yattaqoona aw yuhdithu lahum thikra

Yoruba
 
Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn.

Ayah  20:114  الأية
فَتَعَالَى اللهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۗ وَلَا تَعْجَلْ بِالْقُرْآنِ مِن قَبْلِ أَن يُقْضَىٰ إِلَيْكَ وَحْيُهُ ۖ وَقُل رَّبِّ زِدْنِي عِلْمًا
FataAAala Allahualmaliku alhaqqu wala taAAjal bilqur-animin qabli an yuqda ilayka wahyuhu waqul rabbizidnee AAilma

Yoruba
 
Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur'ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: "Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi."

Ayah  20:115  الأية
وَلَقَدْ عَهِدْنَا إِلَىٰ آدَمَ مِن قَبْلُ فَنَسِيَ وَلَمْ نَجِدْ لَهُ عَزْمًا
Walaqad AAahidna ila adamamin qablu fanasiya walam najid lahu AAazma

Yoruba
 
Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn.

Ayah  20:116  الأية
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ
Wa-ith qulna lilmala-ikatiosjudoo li-adama fasajadoo illa ibleesa aba

Yoruba
 
Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: "Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi 'Iblīs, (tí) ó kọ̀."

Ayah  20:117  الأية
فَقُلْنَا يَا آدَمُ إِنَّ هَٰذَا عَدُوٌّ لَّكَ وَلِزَوْجِكَ فَلَا يُخْرِجَنَّكُمَا مِنَ الْجَنَّةِ فَتَشْقَىٰ
Faqulna ya adamu innahatha AAaduwwun laka walizawjika falayukhrijannakuma mina aljannati fatashqa

Yoruba
 
Nítorí náà, A sọ pé: "Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà máa dààmú (fún ìjẹ-ìmu).

Ayah  20:118  الأية
إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعْرَىٰ
Inna laka alla tajooAAa feehawala taAAra

Yoruba
 
Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀.

Ayah  20:119  الأية
وَأَنَّكَ لَا تَظْمَأُ فِيهَا وَلَا تَضْحَىٰ
Waannaka la tathmaofeeha wala tadha

Yoruba
 
Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́."

Ayah  20:120  الأية
فَوَسْوَسَ إِلَيْهِ الشَّيْطَانُ قَالَ يَا آدَمُ هَلْ أَدُلُّكَ عَلَىٰ شَجَرَةِ الْخُلْدِ وَمُلْكٍ لَّا يَبْلَىٰ
Fawaswasa ilayhi ashshaytanuqala ya adamu hal adulluka AAalashajarati alkhuldi wamulkin la yabla

Yoruba
 
Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: "Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?"

Ayah  20:121  الأية
فَأَكَلَا مِنْهَا فَبَدَتْ لَهُمَا سَوْآتُهُمَا وَطَفِقَا يَخْصِفَانِ عَلَيْهِمَا مِن وَرَقِ الْجَنَّةِ ۚ وَعَصَىٰ آدَمُ رَبَّهُ فَغَوَىٰ
Faakala minha fabadat lahumasaw-atuhuma watafiqa yakhsifaniAAalayhima min waraqi aljannati waAAasa adamurabbahu faghawa

Yoruba
 
Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà.

Ayah  20:122  الأية
ثُمَّ اجْتَبَاهُ رَبُّهُ فَتَابَ عَلَيْهِ وَهَدَىٰ
Thumma ijtabahu rabbuhu fatabaAAalayhi wahada

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà.

Ayah  20:123  الأية
قَالَ اهْبِطَا مِنْهَا جَمِيعًا ۖ بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدًى فَمَنِ اتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشْقَىٰ
Qala ihbita minhajameeAAan baAAdukum libaAAdin AAaduwwun fa-immaya/tiyannakum minnee hudan famani ittabaAAa hudaya falayadillu wala yashqa

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí ṣorí burúkú.

Ayah  20:124  الأية
وَمَنْ أَعْرَضَ عَن ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَىٰ
Waman aAArada AAan thikreefa-inna lahu maAAeeshatan danka wanahshuruhuyawma alqiyamati aAAma

Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde."

Ayah  20:125  الأية
قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرْتَنِي أَعْمَىٰ وَقَدْ كُنتُ بَصِيرًا
Qala rabbi lima hashartaneeaAAma waqad kuntu baseera

Yoruba
 
(Ó) máa wí pé: "Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!"

Ayah  20:126  الأية
قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتْكَ آيَاتُنَا فَنَسِيتَهَا ۖ وَكَذَٰلِكَ الْيَوْمَ تُنسَىٰ
Qala kathalika atatka ayatunafanaseetaha wakathalika alyawma tunsa

Yoruba
 
(Allāhu) sọ pé: "Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná).

Ayah  20:127  الأية
وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي مَنْ أَسْرَفَ وَلَمْ يُؤْمِن بِآيَاتِ رَبِّهِ ۚ وَلَعَذَابُ الْآخِرَةِ أَشَدُّ وَأَبْقَىٰ
Wakathalika najzee man asrafa walamyu/min bi-ayati rabbihi walaAAathabu al-akhiratiashaddu waabqa

Yoruba
 
Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé."

Ayah  20:128  الأية
أَفَلَمْ يَهْدِ لَهُمْ كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّنَ الْقُرُونِ يَمْشُونَ فِي مَسَاكِنِهِمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّأُولِي النُّهَىٰ
Afalam yahdi lahum kam ahlaknaqablahum mina alqurooni yamshoona fee masakinihim inna feethalika laayatin li-olee annuha

Yoruba
 
Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye.

Ayah  20:129  الأية
وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامًا وَأَجَلٌ مُّسَمًّى
Walawla kalimatun sabaqat minrabbika lakana lizaman waajalun musamma

Yoruba
 
Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan.

Ayah  20:130  الأية
فَاصْبِرْ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ قَبْلَ طُلُوعِ الشَّمْسِ وَقَبْلَ غُرُوبِهَا ۖ وَمِنْ آنَاءِ اللَّيْلِ فَسَبِّحْ وَأَطْرَافَ النَّهَارِ لَعَلَّكَ تَرْضَىٰ
Fasbir AAala mayaqooloona wasabbih bihamdi rabbika qabla tulooAAiashshamsi waqabla ghuroobiha wamin ana-iallayli fasabbih waatrafa annaharilaAAallaka tarda

Yoruba
 
Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán nítorí kí (Á lè san ọ́ ní ẹ̀san rere tí) ó máa yọ́nú sí.

Ayah  20:131  الأية
وَلَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِّنْهُمْ زَهْرَةَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا لِنَفْتِنَهُمْ فِيهِ ۚ وَرِزْقُ رَبِّكَ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ
Wala tamuddanna AAaynayka ilama mattaAAna bihi azwajan minhum zahrata alhayatiaddunya linaftinahum feehi warizqu rabbika khayrunwaabqa

Yoruba
 
Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn tó jẹ́ òdòdó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.

Ayah  20:132  الأية
وَأْمُرْ أَهْلَكَ بِالصَّلَاةِ وَاصْطَبِرْ عَلَيْهَا ۖ لَا نَسْأَلُكَ رِزْقًا ۖ نَّحْنُ نَرْزُقُكَ ۗ وَالْعَاقِبَةُ لِلتَّقْوَىٰ
Wa/mur ahlaka bissalatiwastabir AAalayha la nas-alukarizqan nahnu narzuquka walAAaqibatu littaqwa

Yoruba
 
Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l'À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  20:133  الأية
وَقَالُوا لَوْلَا يَأْتِينَا بِآيَةٍ مِّن رَّبِّهِ ۚ أَوَلَمْ تَأْتِهِم بَيِّنَةُ مَا فِي الصُّحُفِ الْأُولَىٰ
Waqaloo lawla ya/teenabi-ayatin min rabbihi awa lam ta/tihim bayyinatu mafee assuhufi al-oola

Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Ṣé ẹ̀rí tó yanjú tó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni?

Ayah  20:134  الأية
وَلَوْ أَنَّا أَهْلَكْنَاهُم بِعَذَابٍ مِّن قَبْلِهِ لَقَالُوا رَبَّنَا لَوْلَا أَرْسَلْتَ إِلَيْنَا رَسُولًا فَنَتَّبِعَ آيَاتِكَ مِن قَبْلِ أَن نَّذِلَّ وَنَخْزَىٰ
Walaw anna ahlaknahum biAAathabinmin qablihi laqaloo rabbana lawla arsaltailayna rasoolan fanattabiAAa ayatika minqabli an nathilla wanakhza

Yoruba
 
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: "Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù."

Ayah  20:135  الأية
قُلْ كُلٌّ مُّتَرَبِّصٌ فَتَرَبَّصُوا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ أَصْحَابُ الصِّرَاطِ السَّوِيِّ وَمَنِ اهْتَدَىٰ
Qul kullun mutarabbisun fatarabbasoofasataAAlamoona man as-habu assiratiassawiyyi wamani ihtada

Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun)." Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni tó mọ̀nà.




© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us