1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الم
Alif-lam-meem
Yoruba
'Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
|
Ayah 3:2 الأية
اللهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ
Allahu la ilaha illahuwa alhayyu alqayyoom
Yoruba
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá.
|
Ayah 3:3 الأية
نَزَّلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ
وَأَنزَلَ التَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ
Nazzala AAalayka alkitaba bilhaqqimusaddiqan lima bayna yadayhi waanzala
attawratawal-injeel
Yoruba
Ó sọ Tírà (al-Ƙur'ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ at-Taorāh àti al-'Injīl kalẹ̀.
|
Ayah 3:4 الأية
مِن قَبْلُ هُدًى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ الْفُرْقَانَ ۗ إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا
بِآيَاتِ اللهِ لَهُمْ عَذَابٌ شَدِيدٌ ۗ وَاللهُ عَزِيزٌ ذُو انتِقَامٍ
Min qablu hudan linnasiwaanzala alfurqana inna allatheena kafaroo bi-ayatiAllahi
lahum AAathabun shadeedun wallahuAAazeezun thoo intiqam
Yoruba
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n jẹ́ ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn. Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀. Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà tó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
|
Ayah 3:5 الأية
إِنَّ اللهَ لَا يَخْفَىٰ عَلَيْهِ شَيْءٌ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ
Inna Allaha la yakhfaAAalayhi shay-on fee al-ardi wala fee assama/-
Yoruba
Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan tó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀.
|
Ayah 3:6 الأية
هُوَ الَّذِي يُصَوِّرُكُمْ فِي الْأَرْحَامِ كَيْفَ يَشَاءُ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا
هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Huwa allathee yusawwirukum feeal-arhami kayfa yashao la ilaha illahuwa
alAAazeezu alhakeem
Yoruba
Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 3:7 الأية
هُوَ الَّذِي أَنزَلَ عَلَيْكَ الْكِتَابَ مِنْهُ آيَاتٌ مُّحْكَمَاتٌ هُنَّ أُمُّ
الْكِتَابِ وَأُخَرُ مُتَشَابِهَاتٌ ۖ فَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ زَيْغٌ
فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَابَهَ مِنْهُ ابْتِغَاءَ الْفِتْنَةِ وَابْتِغَاءَ
تَأْوِيلِهِ ۗ وَمَا يَعْلَمُ تَأْوِيلَهُ إِلَّا اللهُ ۗ وَالرَّاسِخُونَ فِي
الْعِلْمِ يَقُولُونَ آمَنَّا بِهِ كُلٌّ مِّنْ عِندِ رَبِّنَا ۗ وَمَا يَذَّكَّرُ
إِلَّا أُولُو الْأَلْبَابِ
Huwa allathee anzala AAalayka alkitabaminhu ayatun muhkamatun hunna ommualkitabi
waokharu mutashabihatun faammaallatheena fee quloobihim zayghun fayattabiAAoona
matashabaha minhu ibtighaa alfitnati wabtighaata/weelihi wama yaAAlamu ta/weelahu
illa Allahuwarrasikhoona fee alAAilmi yaqooloona amannabihi kullun min AAindi
rabbina wama yaththakkaruilla oloo al-albab
Yoruba
Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí tó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni tó nímọ̀ pàápàá ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: "A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀)." Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè.
|
Ayah 3:8 الأية
رَبَّنَا لَا تُزِغْ قُلُوبَنَا بَعْدَ إِذْ هَدَيْتَنَا وَهَبْ لَنَا مِن لَّدُنكَ
رَحْمَةً ۚ إِنَّكَ أَنتَ الْوَهَّابُ
Rabbana la tuzigh quloobanabaAAda ith hadaytana wahab lana min ladunkarahmatan
innaka anta alwahhab
Yoruba
Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ gan-an ni Ọlọ́rẹ.
|
Ayah 3:9 الأية
رَبَّنَا إِنَّكَ جَامِعُ النَّاسِ لِيَوْمٍ لَّا رَيْبَ فِيهِ ۚ إِنَّ اللهَ لَا
يُخْلِفُ الْمِيعَادَ
Rabbana innaka jamiAAu annasiliyawmin la rayba feehi inna Allaha layukhlifu
almeeAAad
Yoruba
Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l'O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn.
|
Ayah 3:10 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَن تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُم
مِّنَ اللهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمْ وَقُودُ النَّارِ
Inna allatheena kafaroo lan tughniyaAAanhum amwaluhum wala awladuhum mina
Allahishay-an waola-ika hum waqoodu annar
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.
|
Ayah 3:11 الأية
كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا
فَأَخَذَهُمُ اللهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ وَاللهُ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Kada/bi ali firAAawna wallatheenamin qablihim kaththaboo bi-ayatinafaakhathahumu
Allahu bithunoobihim wallahushadeedu alAAiqab
Yoruba
(Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà.
|
Ayah 3:12 الأية
قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُوا سَتُغْلَبُونَ وَتُحْشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ ۚ وَبِئْسَ
الْمِهَادُ
Qul lillatheena kafaroo satughlaboonawatuhsharoona ila jahannama wabi/sa almihad
Yoruba
Sọ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ lọ sí iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú."
|
Ayah 3:13 الأية
قَدْ كَانَ لَكُمْ آيَةٌ فِي فِئَتَيْنِ الْتَقَتَا ۖ فِئَةٌ تُقَاتِلُ فِي سَبِيلِ
اللهِ وَأُخْرَىٰ كَافِرَةٌ يَرَوْنَهُم مِّثْلَيْهِمْ رَأْيَ الْعَيْنِ ۚ
وَاللهُ يُؤَيِّدُ بِنَصْرِهِ مَن يَشَاءُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً
لِّأُولِي الْأَبْصَارِ
Qad kana lakum ayatun feefi-atayni iltaqata fi-atun tuqatilu fee sabeeli
Allahiwaokhra kafiratun yarawnahum mithlayhim ra/yaalAAayni wallahu yu-ayyidu
binasrihi manyashao inna fee thalika laAAibratan li-olee al-absar
Yoruba
Àmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn lójú ogun). Ìjọ kan ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú. Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.
|
Ayah 3:14 الأية
زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ الشَّهَوَاتِ مِنَ النِّسَاءِ وَالْبَنِينَ وَالْقَنَاطِيرِ
الْمُقَنطَرَةِ مِنَ الذَّهَبِ وَالْفِضَّةِ وَالْخَيْلِ الْمُسَوَّمَةِ
وَالْأَنْعَامِ وَالْحَرْثِ ۗ ذَٰلِكَ مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ وَاللهُ
عِندَهُ حُسْنُ الْمَآبِ
Zuyyina linnasi hubbuashshahawati mina annisa-i walbaneenawalqanateeri
almuqantarati mina aththahabiwalfiddati walkhayli almusawwamati
wal-anAAamiwalharthi thalika mataAAu alhayatiaddunya wallahu AAindahu
husnualmaab
Yoruba
Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn ara lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ jaburata àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà.
|
Ayah 3:15 الأية
قُلْ أَؤُنَبِّئُكُم بِخَيْرٍ مِّن ذَٰلِكُمْ ۚ لِلَّذِينَ اتَّقَوْا عِندَ
رَبِّهِمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا
وَأَزْوَاجٌ مُّطَهَّرَةٌ وَرِضْوَانٌ مِّنَ اللهِ ۗ وَاللهُ بَصِيرٌ
بِالْعِبَادِ
Qul aonabbi-okum bikhayrin min thalikumlillatheena ittaqaw AAinda rabbihim
jannatun tajreemin tahtiha al-anharu khalideena feehawaazwajun mutahharatun
waridwanunmina Allahi wallahu baseerun bilAAibad
Yoruba
Sọ pé: "Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan tó dára ju ìyẹn lọ fún yín?" Àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún àwọn tó bá bẹ̀rù (Allāhu) ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn,
|
Ayah 3:16 الأية
الَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا إِنَّنَا آمَنَّا فَاغْفِرْ لَنَا ذُنُوبَنَا
وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
Allatheena yaqooloona rabbanainnana amanna faghfir lana thunoobanawaqina
AAathaba annar
Yoruba
Àwọn tó ń sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná."
|
Ayah 3:17 الأية
الصَّابِرِينَ وَالصَّادِقِينَ وَالْقَانِتِينَ وَالْمُنفِقِينَ
وَالْمُسْتَغْفِرِينَ بِالْأَسْحَارِ
Assabireena wassadiqeenawalqaniteena walmunfiqeena walmustaghfireenabil-ashar
Yoruba
(Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì.
|
Ayah 3:18 الأية
شَهِدَ اللهُ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَالْمَلَائِكَةُ وَأُولُو
الْعِلْمِ قَائِمًا بِالْقِسْطِ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Shahida Allahu annahu la ilahailla huwa walmala-ikatu waoloo alAAilmi
qa-imanbilqisti la ilaha illa huwaalAAazeezu alhakeem
Yoruba
Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 3:19 الأية
إِنَّ الدِّينَ عِندَ اللهِ الْإِسْلَامُ ۗ وَمَا اخْتَلَفَ الَّذِينَ أُوتُوا
الْكِتَابَ إِلَّا مِن بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ الْعِلْمُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۗ وَمَن
يَكْفُرْ بِآيَاتِ اللهِ فَإِنَّ اللهَ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Inna addeena AAinda Allahial-islamu wama ikhtalafa allatheena ootooalkitaba illa
min baAAdi ma jaahumualAAilmu baghyan baynahum waman yakfur bi-ayati
Allahifa-inna Allaha sareeAAu alhisab
Yoruba
Dájúdájú ẹ̀sìn tó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni 'Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) kò yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Ẹni tó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
|
Ayah 3:20 الأية
فَإِنْ حَاجُّوكَ فَقُلْ أَسْلَمْتُ وَجْهِيَ لِلَّهِ وَمَنِ اتَّبَعَنِ ۗ وَقُل
لِّلَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْأُمِّيِّينَ أَأَسْلَمْتُمْ ۚ فَإِنْ
أَسْلَمُوا فَقَدِ اهْتَدَوا ۖ وَّإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا عَلَيْكَ الْبَلَاغُ ۗ
وَاللهُ بَصِيرٌ بِالْعِبَادِ
Fa-in hajjooka faqul aslamtu wajhiyalillahi wamani ittabaAAani waqul lillatheena
ootooalkitaba walommiyyeena aaslamtum fa-inaslamoo faqadi ihtadaw wa-in tawallaw
fa-innama AAalaykaalbalaghu wallahu baseerun bilAAibad
Yoruba
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: "Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (mùsùlùmí ni wá) fún Allāhu." Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: "Ṣé ẹ máa gba 'Islām?" Tí wọ́n bá gba 'Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí'Islām), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.
|
Ayah 3:21 الأية
إِنَّ الَّذِينَ يَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللهِ وَيَقْتُلُونَ النَّبِيِّينَ بِغَيْرِ
حَقٍّ وَيَقْتُلُونَ الَّذِينَ يَأْمُرُونَ بِالْقِسْطِ مِنَ النَّاسِ فَبَشِّرْهُم
بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Inna allatheena yakfuroona bi-ayatiAllahi wayaqtuloona annabiyyeena bighayri
haqqinwayaqtuloona allatheena ya/muroona bilqistimina annasi fabashshirhum
biAAathabin aleem
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe déédé àti ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
|
Ayah 3:22 الأية
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَمَا
لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ
Ola-ika allatheena habitataAAmaluhum fee addunya wal-akhiratiwama lahum min
nasireen
Yoruba
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́.
|
Ayah 3:23 الأية
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ أُوتُوا نَصِيبًا مِّنَ الْكِتَابِ يُدْعَوْنَ إِلَىٰ
كِتَابِ اللهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٌ مِّنْهُمْ وَهُم
مُّعْرِضُونَ
Alam tara ila allatheena ootoonaseeban mina alkitabi yudAAawna ila kitabiAllahi
liyahkuma baynahum thumma yatawallafareequn minhum wahum muAAridoon
Yoruba
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè síbi Tírà Allāhu, nítorí kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà, tí wọ́n sì ń gbúnrí?
|
Ayah 3:24 الأية
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لَن تَمَسَّنَا النَّارُ إِلَّا أَيَّامًا
مَّعْدُودَاتٍ ۖ وَغَرَّهُمْ فِي دِينِهِم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Thalika bi-annahum qaloo lantamassana annaru illa ayyamanmaAAdoodatin
wagharrahum fee deenihim ma kanooyaftaroon
Yoruba
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: "Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ tó lóǹkà." Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn.
|
Ayah 3:25 الأية
فَكَيْفَ إِذَا جَمَعْنَاهُمْ لِيَوْمٍ لَّا رَيْبَ فِيهِ وَوُفِّيَتْ كُلُّ نَفْسٍ
مَّا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Fakayfa itha jamaAAnahumliyawmin la rayba feehi wawuffiyat kullu nafsin
makasabat wahum la yuthlamoon
Yoruba
Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
|
Ayah 3:26 الأية
قُلِ اللهُمَّ مَالِكَ الْمُلْكِ تُؤْتِي الْمُلْكَ مَن تَشَاءُ وَتَنزِعُ
الْمُلْكَ مِمَّن تَشَاءُ وَتُعِزُّ مَن تَشَاءُ وَتُذِلُّ مَن تَشَاءُ ۖ بِيَدِكَ
الْخَيْرُ ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Quli allahumma malika almulkitu/tee almulka man tashao watanziAAu almulka mimman
tashaowatuAAizzu man tashao watuthillu man tashaobiyadika alkhayru innaka AAala
kulli shay-in qadeer
Yoruba
Sọ pé: "Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 3:27 الأية
تُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَتُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ ۖ وَتُخْرِجُ
الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَتُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ ۖ وَتَرْزُقُ مَن
تَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Tooliju allayla fee annahariwatooliju annahara fee allayli watukhriju
alhayyamina almayyiti watukhriju almayyita mina alhayyi watarzuquman tashao
bighayri hisab
Yoruba
Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán. Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru. Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò."
|
Ayah 3:28 الأية
لَّا يَتَّخِذِ الْمُؤْمِنُونَ الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِن دُونِ الْمُؤْمِنِينَ
ۖ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَلَيْسَ مِنَ اللهِ فِي شَيْءٍ إِلَّا أَن تَتَّقُوا
مِنْهُمْ تُقَاةً ۗ وَيُحَذِّرُكُمُ اللهُ نَفْسَهُ ۗ وَإِلَى اللهِ الْمَصِيرُ
La yattakhithi almu/minoonaalkafireena awliyaa min dooni almu/mineena
wamanyafAAal thalika falaysa mina Allahi fee shay-in illaan tattaqoo minhum
tuqatan wayuhaththirukumuAllahu nafsahu wa-ila Allahi almaseer
Yoruba
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín). Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
|
Ayah 3:29 الأية
قُلْ إِن تُخْفُوا مَا فِي صُدُورِكُمْ أَوْ تُبْدُوهُ يَعْلَمْهُ اللهُ ۗ
وَيَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَاللهُ عَلَىٰ كُلِّ
شَيْءٍ قَدِيرٌ
Qul in tukhfoo ma fee sudoorikumaw tubdoohu yaAAlamhu Allahu wayaAAlamu ma fee
assamawatiwama fee al-ardi wallahu AAalakulli shay-in qadeer
Yoruba
Sọ pé: "Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 3:30 الأية
يَوْمَ تَجِدُ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ مِنْ خَيْرٍ مُّحْضَرًا وَمَا عَمِلَتْ
مِن سُوءٍ تَوَدُّ لَوْ أَنَّ بَيْنَهَا وَبَيْنَهُ أَمَدًا بَعِيدًا ۗ
وَيُحَذِّرُكُمُ اللهُ نَفْسَهُ ۗ وَاللهُ رَءُوفٌ بِالْعِبَادِ
Yawma tajidu kullu nafsin ma AAamilatmin khayrin muhdaran wama AAamilat min
soo-intawaddu law anna baynaha wabaynahu amadan baAAeedan
wayuhaththirukumuAllahu nafsahu wallahu raoofun bilAAibad
Yoruba
Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò tó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn olùjọ́sìn.
|
Ayah 3:31 الأية
قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبُّونَ اللهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللهُ
وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ ۗ وَاللهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Qul in kuntum tuhibboona AllahafattabiAAoonee yuhbibkumu Allahu wayaghfirlakum
thunoobakum wallahu ghafoorun raheem
Yoruba
Sọ pé: "Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 3:32 الأية
قُلْ أَطِيعُوا اللهَ وَالرَّسُولَ ۖ فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللهَ لَا يُحِبُّ
الْكَافِرِينَ
Qul ateeAAoo Allaha warrasoolafa-in tawallaw fa-inna Allaha la yuhibbu
alkafireen
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 3:33 الأية
إِنَّ اللهَ اصْطَفَىٰ آدَمَ وَنُوحًا وَآلَ إِبْرَاهِيمَ وَآلَ عِمْرَانَ عَلَى
الْعَالَمِينَ
Inna Allaha istafa adamawanoohan waala ibraheema waala AAimranaAAala alAAalameen
Yoruba
Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé 'Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).
|
Ayah 3:34 الأية
ذُرِّيَّةً بَعْضُهَا مِن بَعْضٍ ۗ وَاللهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Thurriyyatan baAAduhamin baAAdin wallahu sameeAAun AAaleem
Yoruba
Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
|
Ayah 3:35 الأية
إِذْ قَالَتِ امْرَأَتُ عِمْرَانَ رَبِّ إِنِّي نَذَرْتُ لَكَ مَا فِي بَطْنِي
مُحَرَّرًا فَتَقَبَّلْ مِنِّي ۖ إِنَّكَ أَنتَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Ith qalati imraatu AAimranarabbi innee nathartu laka ma fee batnee
muharraranfataqabbal minnee innaka anta assameeAAu alAAaleem
Yoruba
(Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú ikùn mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀."
|
Ayah 3:36 الأية
فَلَمَّا وَضَعَتْهَا قَالَتْ رَبِّ إِنِّي وَضَعْتُهَا أُنثَىٰ وَاللهُ أَعْلَمُ
بِمَا وَضَعَتْ وَلَيْسَ الذَّكَرُ كَالْأُنثَىٰ ۖ وَإِنِّي سَمَّيْتُهَا مَرْيَمَ
وَإِنِّي أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ
Falamma wadaAAat-ha qalatrabbi innee wadaAAtuha ontha wallahuaAAlamu bima
wadaAAat walaysa aththakarukalontha wa-innee sammaytuha maryamawa-innee
oAAeethuha bika wathurriyyatahamina ashshaytani arrajeem
Yoruba
Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ Èṣù ẹni ẹ̀kọ̀."
|
Ayah 3:37 الأية
فَتَقَبَّلَهَا رَبُّهَا بِقَبُولٍ حَسَنٍ وَأَنبَتَهَا نَبَاتًا حَسَنًا
وَكَفَّلَهَا زَكَرِيَّا ۖ كُلَّمَا دَخَلَ عَلَيْهَا زَكَرِيَّا الْمِحْرَابَ
وَجَدَ عِندَهَا رِزْقًا ۖ قَالَ يَا مَرْيَمُ أَنَّىٰ لَكِ هَٰذَا ۖ قَالَتْ هُوَ
مِنْ عِندِ اللهِ ۖ إِنَّ اللهَ يَرْزُقُ مَن يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Fataqabbalaha rabbuhabiqaboolin hasanin waanbataha nabatan hasananwakaffalaha
zakariyya kullama dakhalaAAalayha zakariyya almihraba wajadaAAindaha rizqan qala
ya maryamu annalaki hatha qalat huwa min AAindi Allahi innaAllaha yarzuqu man
yashao bighayri hisab
Yoruba
Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà rẹ̀ ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: "Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?" (Mọryam á) sọ pé: "Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò."
|
Ayah 3:38 الأية
هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُ ۖ قَالَ رَبِّ هَبْ لِي مِن لَّدُنكَ ذُرِّيَّةً
طَيِّبَةً ۖ إِنَّكَ سَمِيعُ الدُّعَاءِ
Hunalika daAAa zakariyyarabbahu qala rabbi hab lee min ladunka
thurriyyatantayyibatan innaka sameeAAu adduAAa/-
Yoruba
Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà."
|
Ayah 3:39 الأية
فَنَادَتْهُ الْمَلَائِكَةُ وَهُوَ قَائِمٌ يُصَلِّي فِي الْمِحْرَابِ أَنَّ اللهَ
يُبَشِّرُكَ بِيَحْيَىٰ مُصَدِّقًا بِكَلِمَةٍ مِّنَ اللهِ وَسَيِّدًا وَحَصُورًا
وَنَبِيًّا مِّنَ الصَّالِحِينَ
Fanadat-hu almala-ikatu wahuwaqa-imun yusallee fee almihrabi annaAllaha
yubashshiruka biyahya musaddiqanbikalimatin mina Allahi wasayyidan
wahasooranwanabiyyan mina assaliheen
Yoruba
Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): "Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu. (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin. (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere."
|
Ayah 3:40 الأية
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَقَدْ بَلَغَنِيَ الْكِبَرُ وَامْرَأَتِي
عَاقِرٌ ۖ قَالَ كَذَٰلِكَ اللهُ يَفْعَلُ مَا يَشَاءُ
Qala rabbi anna yakoonu leeghulamun waqad balaghaniya alkibaru wamraatee
AAaqirunqala kathalika Allahu yafAAalu mayasha/
Yoruba
(Zakariyyā) sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?" (Mọlāika) sọ pé: "Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́."
|
Ayah 3:41 الأية
قَالَ رَبِّ اجْعَل لِّي آيَةً ۖ قَالَ آيَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ النَّاسَ ثَلَاثَةَ
أَيَّامٍ إِلَّا رَمْزًا ۗ وَاذْكُر رَّبَّكَ كَثِيرًا وَسَبِّحْ بِالْعَشِيِّ
وَالْإِبْكَارِ
Qala rabbi ijAAal lee ayatan qalaayatuka alla tukallima annasa thalathataayyamin
illa ramzan wathkur rabbakakatheeran wasabbih bilAAashiyyi wal-ibkar
Yoruba
(Zakariyyā) sọ pé: "Olúwa mi, fún mi ní àmì kan." (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù."
|
Ayah 3:42 الأية
وَإِذْ قَالَتِ الْمَلَائِكَةُ يَا مَرْيَمُ إِنَّ اللهَ اصْطَفَاكِ وَطَهَّرَكِ
وَاصْطَفَاكِ عَلَىٰ نِسَاءِ الْعَالَمِينَ
Wa-ith qalati almala-ikatuya maryamu inna Allaha istafaki watahharakiwastafaki
AAala nisa-i alAAalameen
Yoruba
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ).
|
Ayah 3:43 الأية
يَا مَرْيَمُ اقْنُتِي لِرَبِّكِ وَاسْجُدِي وَارْكَعِي مَعَ الرَّاكِعِينَ
Ya maryamu oqnutee lirabbiki wasjudeewarkaAAee maAAa arrakiAAeen
Yoruba
Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).
|
Ayah 3:44 الأية
ذَٰلِكَ مِنْ أَنبَاءِ الْغَيْبِ نُوحِيهِ إِلَيْكَ ۚ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ
يُلْقُونَ أَقْلَامَهُمْ أَيُّهُمْ يَكْفُلُ مَرْيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيْهِمْ إِذْ
يَخْتَصِمُونَ
Thalika min anba-i alghaybinooheehi ilayka wama kunta ladayhim ithyulqoona
aqlamahum ayyuhum yakfulu maryama wamakunta ladayhim ith yakhtasimoon
Yoruba
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò. Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
|
Ayah 3:45 الأية
إِذْ قَالَتِ الْمَلَائِكَةُ يَا مَرْيَمُ إِنَّ اللهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٍ
مِّنْهُ اسْمُهُ الْمَسِيحُ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ وَجِيهًا فِي الدُّنْيَا
وَالْآخِرَةِ وَمِنَ الْمُقَرَّبِينَ
Ith qalati almala-ikatuya maryamu inna Allaha yubashshiruki bikalimatinminhu
ismuhu almaseehu AAeesa ibnu maryama wajeehanfee addunya wal-akhirati
waminaalmuqarrabeen
Yoruba
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ẹni iyì ni ní ayé àti ní ọ̀run. Ó sì wà lára àwọn alásùn-únmọ́ (Allāhu).
|
Ayah 3:46 الأية
وَيُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا وَمِنَ الصَّالِحِينَ
Wayukallimu annasa feealmahdi wakahlan wamina assaliheen
Yoruba
Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tó bá dàgbà. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere."
|
Ayah 3:47 الأية
قَالَتْ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي وَلَدٌ وَلَمْ يَمْسَسْنِي بَشَرٌ ۖ قَالَ
كَذَٰلِكِ اللهُ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ إِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ
لَهُ كُن فَيَكُونُ
Qalat rabbi anna yakoonu leewaladun walam yamsasnee basharun qala kathaliki
Allahuyakhluqu ma yashao itha qada amranfa-innama yaqoolu lahu kun fayakoon
Yoruba
(Mọryam) sọ pé: "Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí." Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
|
Ayah 3:48 الأية
وَيُعَلِّمُهُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ وَالْإِنجِيلَ
WayuAAallimuhu alkitaba walhikmatawattawrata wal-injeel
Yoruba
(Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-'Injīl.
|
Ayah 3:49 الأية
وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَنِّي قَدْ جِئْتُكُم بِآيَةٍ مِّن
رَّبِّكُمْ ۖ أَنِّي أَخْلُقُ لَكُم مِّنَ الطِّينِ كَهَيْئَةِ الطَّيْرِ فَأَنفُخُ
فِيهِ فَيَكُونُ طَيْرًا بِإِذْنِ اللهِ ۖ وَأُبْرِئُ الْأَكْمَهَ وَالْأَبْرَصَ
وَأُحْيِي الْمَوْتَىٰ بِإِذْنِ اللهِ ۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأْكُلُونَ وَمَا
تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لَّكُمْ إِن كُنتُم
مُّؤْمِنِينَ
Warasoolan ila banee isra-eelaannee qad ji/tukum bi-ayatin min rabbikum annee
akhluqulakum mina atteeni kahay-ati attayrifaanfukhu feehi fayakoonu tayran bi-ithni
Allahiwaobri-o al-akmaha wal-abrasa waohyeealmawta bi-ithni Allahi waonabbi-okum
bimata/kuloona wama taddakhiroona fee buyootikum inna fee thalikalaayatan lakum
in kuntum mu/mineen
Yoruba
(Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) "Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fún yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
|
Ayah 3:50 الأية
وَمُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَلِأُحِلَّ لَكُم بَعْضَ
الَّذِي حُرِّمَ عَلَيْكُمْ ۚ وَجِئْتُكُم بِآيَةٍ مِّن رَّبِّكُمْ فَاتَّقُوا
اللهَ وَأَطِيعُونِ
Wamusaddiqan lima baynayadayya mina attawrati wali-ohilla lakumbaAAda allathee
hurrima AAalaykum waji/tukumbi-ayatin min rabbikum fattaqoo Allaha waateeAAoon
Yoruba
Mo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
|
Ayah 3:51 الأية
إِنَّ اللهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۗ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ
Inna Allaha rabbee warabbukum faAAbudoohuhatha siratun mustaqeem
Yoruba
Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà."
|
Ayah 3:52 الأية
فَلَمَّا أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنْهُمُ الْكُفْرَ قَالَ مَنْ أَنصَارِي إِلَى اللهِ ۖ
قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ اللهِ آمَنَّا بِاللهِ وَاشْهَدْ
بِأَنَّا مُسْلِمُونَ
Falamma ahassa AAeesaminhumu alkufra qala man ansaree ila Allahiqala
alhawariyyoona nahnu ansaruAllahi amanna billahi washhadbi-anna muslimoon
Yoruba
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: "Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.
|
Ayah 3:53 الأية
رَبَّنَا آمَنَّا بِمَا أَنزَلْتَ وَاتَّبَعْنَا الرَّسُولَ فَاكْتُبْنَا مَعَ
الشَّاهِدِينَ
Rabbana amanna bimaanzalta wattabaAAna arrasoola faktubnamaAAa ashshahideen
Yoruba
Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí."
|
Ayah 3:54 الأية
وَمَكَرُوا وَمَكَرَ اللهُ ۖ وَاللهُ خَيْرُ الْمَاكِرِينَ
Wamakaroo wamakara Allahu wallahukhayru almakireen
Yoruba
Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l'óore jùlọ nínú àwọn adéte.
|
Ayah 3:55 الأية
إِذْ قَالَ اللهُ يَا عِيسَىٰ إِنِّي مُتَوَفِّيكَ وَرَافِعُكَ إِلَيَّ
وَمُطَهِّرُكَ مِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا وَجَاعِلُ الَّذِينَ اتَّبَعُوكَ فَوْقَ
الَّذِينَ كَفَرُوا إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ ۖ ثُمَّ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ
فَأَحْكُمُ بَيْنَكُمْ فِيمَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
Ith qala Allahu yaAAeesa innee mutawaffeeka warafiAAuka ilayya wamutahhirukamina
allatheena kafaroo wajaAAilu allatheenaittabaAAooka fawqa allatheena kafaroo ila
yawmialqiyamati thumma ilayya marjiAAukum faahkumubaynakum feema kuntum feehi
takhtalifoon
Yoruba
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: "‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn pátápátá. Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Mo sì máa fi àwọn tó tẹ̀lé ọ borí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
|
Ayah 3:56 الأية
فَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا فَأُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا فِي الدُّنْيَا
وَالْآخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ
Faamma allatheena kafaroofaoAAaththibuhum AAathaban shadeedan fee
addunyawal-akhirati wama lahum min nasireen
Yoruba
Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
|
Ayah 3:57 الأية
وَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ ۗ
وَاللهُ لَا يُحِبُّ الظَّالِمِينَ
Waamma allatheena amanoowaAAamiloo assalihati fayuwaffeehimojoorahum wallahu la
yuhibbu aththalimeen
Yoruba
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí.
|
Ayah 3:58 الأية
ذَٰلِكَ نَتْلُوهُ عَلَيْكَ مِنَ الْآيَاتِ وَالذِّكْرِ الْحَكِيمِ
Thalika natloohu AAalayka mina al-ayatiwaththikri alhakeem
Yoruba
Ìyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún òye ìjìnlẹ̀(ìyẹn, al-Ƙur'ān).
|
Ayah 3:59 الأية
إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِندَ اللهِ كَمَثَلِ آدَمَ ۖ خَلَقَهُ مِن تُرَابٍ ثُمَّ
قَالَ لَهُ كُن فَيَكُونُ
Inna mathala AAeesa AAinda Allahikamathali adama khalaqahu min turabin thumma
qalalahu kun fayakoon
Yoruba
Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀.
|
Ayah 3:60 الأية
الْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُن مِّنَ الْمُمْتَرِينَ
Alhaqqu min rabbika fala takunmina almumtareen
Yoruba
Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì.
|
Ayah 3:61 الأية
فَمَنْ حَاجَّكَ فِيهِ مِن بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ فَقُلْ تَعَالَوْا
نَدْعُ أَبْنَاءَنَا وَأَبْنَاءَكُمْ وَنِسَاءَنَا وَنِسَاءَكُمْ وَأَنفُسَنَا
وَأَنفُسَكُمْ ثُمَّ نَبْتَهِلْ فَنَجْعَل لَّعْنَتَ اللهِ عَلَى الْكَاذِبِينَ
Faman hajjaka feehi min baAAdi majaaka mina alAAilmi faqul taAAalaw nadAAu
abnaanawaabnaakum wanisaana wanisaakumwaanfusana waanfusakum thumma nabtahil
fanajAAal laAAnataAllahi AAala alkathibeen
Yoruba
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: "Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣàdúà ìparun (lórí òpùrọ́ nínú wa). Nítorí náà, a óò sọ pé, "ibi dandan (ìgbéjìnnà sí ìkẹ́) Allāhu kí ó máa jẹ́ ti àwọn òpùrọ́."
|
Ayah 3:62 الأية
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْقَصَصُ الْحَقُّ ۚ وَمَا مِنْ إِلَٰهٍ إِلَّا اللهُ ۚ
وَإِنَّ اللهَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Inna hatha lahuwa alqasasualhaqqu wama min ilahin illa Allahuwa-inna Allaha
lahuwa alAAazeezu alhakeem
Yoruba
Dájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 3:63 الأية
فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّ اللهَ عَلِيمٌ بِالْمُفْسِدِينَ
Fa-in tawallaw fa-inna AllahaAAaleemun bilmufsideen
Yoruba
Tí wọ́n bá sì pẹ̀yìndà (kúrò níbi òdodo), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 3:64 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ تَعَالَوْا إِلَىٰ كَلِمَةٍ سَوَاءٍ بَيْنَنَا
وَبَيْنَكُمْ أَلَّا نَعْبُدَ إِلَّا اللهَ وَلَا نُشْرِكَ بِهِ شَيْئًا وَلَا
يَتَّخِذَ بَعْضُنَا بَعْضًا أَرْبَابًا مِّن دُونِ اللهِ ۚ فَإِن تَوَلَّوْا
فَقُولُوا اشْهَدُوا بِأَنَّا مُسْلِمُونَ
Qul ya ahla alkitabi taAAalawila kalimatin sawa-in baynana wabaynakum
allanaAAbuda illa Allaha wala nushrika bihishay-an wala yattakhitha
baAAdunabaAAdan arbaban min dooni Allahi fa-intawallaw faqooloo ishhadoo bi-anna
muslimoon
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan tó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu." Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: "Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa."
|
Ayah 3:65 الأية
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تُحَاجُّونَ فِي إِبْرَاهِيمَ وَمَا أُنزِلَتِ
التَّوْرَاةُ وَالْإِنجِيلُ إِلَّا مِن بَعْدِهِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Ya ahla alkitabi lima tuhajjoonafee ibraheema wama onzilati attawratuwal-injeelu
illa min baAAdihi afalataAAqiloon
Yoruba
Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-'Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni?
|
Ayah 3:66 الأية
هَا أَنتُمْ هَٰؤُلَاءِ حَاجَجْتُمْ فِيمَا لَكُم بِهِ عِلْمٌ فَلِمَ تُحَاجُّونَ
فِيمَا لَيْسَ لَكُم بِهِ عِلْمٌ ۚ وَاللهُ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Ha antum haola-i hajajtumfeema lakum bihi AAilmun falima tuhajjoona feemalaysa
lakum bihi AAilmun wallahu yaAAlamu waantumla taAAlamoon
Yoruba
Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀? Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
|
Ayah 3:67 الأية
مَا كَانَ إِبْرَاهِيمُ يَهُودِيًّا وَلَا نَصْرَانِيًّا وَلَٰكِن كَانَ حَنِيفًا
مُّسْلِمًا وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ
Ma kana ibraheemuyahoodiyyan wala nasraniyyan walakinkana haneefan musliman wama
kana minaalmushrikeen
Yoruba
(Ànábì) 'Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe nasọ̄rọ̄, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
|
Ayah 3:68 الأية
إِنَّ أَوْلَى النَّاسِ بِإِبْرَاهِيمَ لَلَّذِينَ اتَّبَعُوهُ وَهَٰذَا النَّبِيُّ
وَالَّذِينَ آمَنُوا ۗ وَاللهُ وَلِيُّ الْمُؤْمِنِينَ
Inna awla annasibi-ibraheema lallatheena ittabaAAoohu wahathaannabiyyu
wallatheena amanoo wallahuwaliyyu almu/mineen
Yoruba
Dájúdájú àwọn ènìyàn tó súnmọ́ (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm jùlọ (nínú ẹ̀sìn 'Islām) ni àwọn tó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí). Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
|
Ayah 3:69 الأية
وَدَّت طَّائِفَةٌ مِّنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَوْ يُضِلُّونَكُمْ وَمَا يُضِلُّونَ
إِلَّا أَنفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ
Waddat ta-ifatun min ahli alkitabilaw yudilloonakum wama yudilloona
illaanfusahum wama yashAAuroon
Yoruba
Igun kan nínú àwọn onítírà fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura.
|
Ayah 3:70 الأية
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللهِ وَأَنتُمْ تَشْهَدُونَ
Ya ahla alkitabi limatakfuroona bi-ayati Allahi waantumtashhadoon
Yoruba
Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)!
|
Ayah 3:71 الأية
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تَلْبِسُونَ الْحَقَّ بِالْبَاطِلِ وَتَكْتُمُونَ
الْحَقَّ وَأَنتُمْ تَعْلَمُونَ
Ya ahla alkitabi limatalbisoona alhaqqa bilbatili wataktumoonaalhaqqa waantum
taAAlamoon
Yoruba
Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)?
|
Ayah 3:72 الأية
وَقَالَت طَّائِفَةٌ مِّنْ أَهْلِ الْكِتَابِ آمِنُوا بِالَّذِي أُنزِلَ عَلَى
الَّذِينَ آمَنُوا وَجْهَ النَّهَارِ وَاكْفُرُوا آخِرَهُ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Waqalat ta-ifatun min ahlialkitabi aminoo billathee onzilaAAala allatheena
amanoo wajha annahariwakfuroo akhirahu laAAallahum yarjiAAoon
Yoruba
Igun kan nínú àwọn onítírà wí pé: "Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn 'Islām).
|
Ayah 3:73 الأية
وَلَا تُؤْمِنُوا إِلَّا لِمَن تَبِعَ دِينَكُمْ قُلْ إِنَّ الْهُدَىٰ هُدَى اللهِ
أَن يُؤْتَىٰ أَحَدٌ مِّثْلَ مَا أُوتِيتُمْ أَوْ يُحَاجُّوكُمْ عِندَ رَبِّكُمْ ۗ
قُلْ إِنَّ الْفَضْلَ بِيَدِ اللهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللهُ وَاسِعٌ
عَلِيمٌ
Wala tu/minoo illa limantabiAAa deenakum qul inna alhuda huda Allahian yu/ta
ahadun mithla ma ooteetum aw yuhajjookumAAinda rabbikum qul inna alfadla biyadi
Allahiyu/teehi man yashao wallahu wasiAAunAAaleem
Yoruba
(Wọ́n tún wí pé:) "Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín." Sọ pé: "Dájúdájú ìmọ̀nà ('Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu." (Wọ́n tún wí pé:) "(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí wọ́n fún yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín." Sọ pé: "Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀."
|
Ayah 3:74 الأية
يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ
Yakhtassu birahmatihi man yashaowallahu thoo alfadli alAAatheem
Yoruba
(Allāhu) ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá.
|
Ayah 3:75 الأية
وَمِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ مَنْ إِن تَأْمَنْهُ بِقِنطَارٍ يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ
وَمِنْهُم مَّنْ إِن تَأْمَنْهُ بِدِينَارٍ لَّا يُؤَدِّهِ إِلَيْكَ إِلَّا مَا
دُمْتَ عَلَيْهِ قَائِمًا ۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لَيْسَ عَلَيْنَا فِي
الْأُمِّيِّينَ سَبِيلٌ وَيَقُولُونَ عَلَى اللهِ الْكَذِبَ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Wamin ahli alkitabi man in ta/manhubiqintarin yu-addihi ilayka waminhum man in
ta/manhubideenarin la yu-addihi ilayka illa madumta AAalayhi qa-iman thalika bi-annahum
qaloolaysa AAalayna fee al-ommiyyeena sabeelun wayaqooloonaAAala Allahi
alkathiba wahum yaAAlamoon
Yoruba
Ó ń bẹ nínú àwọn onítírà, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: "Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà." Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
|
Ayah 3:76 الأية
بَلَىٰ مَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ وَاتَّقَىٰ فَإِنَّ اللهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Bala man awfa biAAahdihi wattaqafa-inna Allaha yuhibbu almuttaqeen
Yoruba
Rárá (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
|
Ayah 3:77 الأية
إِنَّ الَّذِينَ يَشْتَرُونَ بِعَهْدِ اللهِ وَأَيْمَانِهِمْ ثَمَنًا قَلِيلًا
أُولَٰئِكَ لَا خَلَاقَ لَهُمْ فِي الْآخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ اللهُ وَلَا
يَنظُرُ إِلَيْهِمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ
أَلِيمٌ
Inna allatheena yashtaroona biAAahdiAllahi waaymanihim thamanan qaleelan
ola-ikala khalaqa lahum fee al-akhirati walayukallimuhumu Allahu wala
yanthuruilayhim yawma alqiyamati wala yuzakkeehim walahumAAathabun aleem
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore kan fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde. Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn.
|
Ayah 3:78 الأية
وَإِنَّ مِنْهُمْ لَفَرِيقًا يَلْوُونَ أَلْسِنَتَهُم بِالْكِتَابِ لِتَحْسَبُوهُ
مِنَ الْكِتَابِ وَمَا هُوَ مِنَ الْكِتَابِ وَيَقُولُونَ هُوَ مِنْ عِندِ اللهِ
وَمَا هُوَ مِنْ عِندِ اللهِ وَيَقُولُونَ عَلَى اللهِ الْكَذِبَ وَهُمْ
يَعْلَمُونَ
Wa-inna minhum lafareeqan yalwoonaalsinatahum bilkitabi litahsaboohu
minaalkitabi wama huwa mina alkitabiwayaqooloona huwa min AAindi Allahi wama
huwa minAAindi Allahi wayaqooloona AAala Allahi alkathibawahum yaAAlamoon
Yoruba
Dájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn tó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: "Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu." Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
|
Ayah 3:79 الأية
مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُؤْتِيَهُ اللهُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ
ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُوا عِبَادًا لِّي مِن دُونِ اللهِ وَلَٰكِن كُونُوا
رَبَّانِيِّينَ بِمَا كُنتُمْ تُعَلِّمُونَ الْكِتَابَ وَبِمَا كُنتُمْ تَدْرُسُونَ
Ma kana libasharin anyu/tiyahu Allahu alkitaba walhukmawannubuwwata thumma
yaqoola linnasikoonoo AAibadan lee min dooni Allahi walakinkoonoo rabbaniyyeena
bima kuntum tuAAallimoonaalkitaba wabima kuntum tadrusoon
Yoruba
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, òye ìjìnlẹ̀ àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, "ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu." Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) "ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn)."
|
Ayah 3:80 الأية
وَلَا يَأْمُرَكُمْ أَن تَتَّخِذُوا الْمَلَائِكَةَ وَالنَّبِيِّينَ أَرْبَابًا ۗ
أَيَأْمُرُكُم بِالْكُفْرِ بَعْدَ إِذْ أَنتُم مُّسْلِمُونَ
Wala ya/murakum an tattakhithooalmala-ikata wannabiyyeena arbabanaya/murukum
bilkufri baAAda ith antum muslimoon
Yoruba
(Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni?
|
Ayah 3:81 الأية
وَإِذْ أَخَذَ اللهُ مِيثَاقَ النَّبِيِّينَ لَمَا آتَيْتُكُم مِّن كِتَابٍ
وَحِكْمَةٍ ثُمَّ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مُّصَدِّقٌ لِّمَا مَعَكُمْ لَتُؤْمِنُنَّ بِهِ
وَلَتَنصُرُنَّهُ ۚ قَالَ أَأَقْرَرْتُمْ وَأَخَذْتُمْ عَلَىٰ ذَٰلِكُمْ إِصْرِي ۖ
قَالُوا أَقْرَرْنَا ۚ قَالَ فَاشْهَدُوا وَأَنَا مَعَكُم مِّنَ الشَّاهِدِينَ
Wa-ith akhatha Allahumeethaqa annabiyyeena lama ataytukummin kitabin wahikmatin
thumma jaakumrasoolun musaddiqun lima maAAakum latu/minunna bihiwalatansurunnahu
qala aaqrartum waakhathtumAAala thalikum isree qaloo aqrarnaqala fashhadoo waana
maAAakum mina ashshahideen
Yoruba
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: "Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí nígbà tí Mo bá fún yín ní tírà àti òye ìjìnlẹ́, lẹ́yìn náà Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò dé ba yín; ó máa fi èyí tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́." (Allāhu) sọ pé: "Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?" Wọ́n sọ pé: "A gbà." (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí."
|
Ayah 3:82 الأية
فَمَن تَوَلَّىٰ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Faman tawalla baAAda thalikafaola-ika humu alfasiqoon
Yoruba
Nítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 3:83 الأية
أَفَغَيْرَ دِينِ اللهِ يَبْغُونَ وَلَهُ أَسْلَمَ مَن فِي السَّمَاوَاتِ
وَالْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَإِلَيْهِ يُرْجَعُونَ
Afaghayra deeni Allahi yabghoonawalahu aslama man fee assamawati wal-arditawAAan
wakarhan wa-ilayhi yurjaAAoon
Yoruba
Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.
|
Ayah 3:84 الأية
قُلْ آمَنَّا بِاللهِ وَمَا أُنزِلَ عَلَيْنَا وَمَا أُنزِلَ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ
وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطِ وَمَا أُوتِيَ مُوسَىٰ
وَعِيسَىٰ وَالنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمْ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِّنْهُمْ
وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ
Qul amanna billahiwama onzila AAalayna wama onzila AAalaibraheema wa-ismaAAeela
wa-ishaqawayaAAqooba wal-asbati wama ootiya moosawaAAeesa wannabiyyoona min
rabbihim lanufarriqu bayna ahadin minhum wanahnu lahumuslimoon
Yoruba
Sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, 'Ismọ̄‘īl, 'Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un."
|
Ayah 3:85 الأية
وَمَن يَبْتَغِ غَيْرَ الْإِسْلَامِ دِينًا فَلَن يُقْبَلَ مِنْهُ وَهُوَ فِي
الْآخِرَةِ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Waman yabtaghi ghayra al-islamideenan falan yuqbala minhu wahuwa fee al-akhirati
minaalkhasireen
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí 'Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.
|
Ayah 3:86 الأية
كَيْفَ يَهْدِي اللهُ قَوْمًا كَفَرُوا بَعْدَ إِيمَانِهِمْ وَشَهِدُوا أَنَّ
الرَّسُولَ حَقٌّ وَجَاءَهُمُ الْبَيِّنَاتُ ۚ وَاللهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ
الظَّالِمِينَ
Kayfa yahdee Allahu qawman kafaroobaAAda eemanihim washahidoo anna arrasoola
haqqunwajaahumu albayyinatu wallahu layahdee alqawma aththalimeen
Yoruba
Báwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí tó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
|
Ayah 3:87 الأية
أُولَٰئِكَ جَزَاؤُهُمْ أَنَّ عَلَيْهِمْ لَعْنَةَ اللهِ وَالْمَلَائِكَةِ
وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ
Ola-ika jazaohum annaAAalayhim laAAnata Allahi walmala-ikati wannasiajmaAAeen
Yoruba
Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn.
|
Ayah 3:88 الأية
خَالِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنْهُمُ الْعَذَابُ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ
Khalideena feeha layukhaffafu AAanhumu alAAathabu wala hum yuntharoon
Yoruba
Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
|
Ayah 3:89 الأية
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا فَإِنَّ اللهَ غَفُورٌ
رَّحِيمٌ
Illa allatheena taboomin baAAdi thalika waaslahoo fa-inna Allahaghafoorun raheem
Yoruba
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
|
Ayah 3:90 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بَعْدَ إِيمَانِهِمْ ثُمَّ ازْدَادُوا كُفْرًا لَّن
تُقْبَلَ تَوْبَتُهُمْ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الضَّالُّونَ
Inna allatheena kafaroo baAAda eemanihimthumma izdadoo kufran lan tuqbala
tawbatuhum waola-ikahumu addalloon
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùṣìnà.
|
Ayah 3:91 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَمَاتُوا وَهُمْ كُفَّارٌ فَلَن يُقْبَلَ مِنْ أَحَدِهِم
مِّلْءُ الْأَرْضِ ذَهَبًا وَلَوِ افْتَدَىٰ بِهِ ۗ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ
أَلِيمٌ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ
Inna allatheena kafaroo wamatoowahum kuffarun falan yuqbala min ahadihim
miloal-ardi thahaban walawi iftada bihi ola-ikalahum AAathabun aleemun wama
lahum min nasireen
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
|
Ayah 3:92 الأية
لَن تَنَالُوا الْبِرَّ حَتَّىٰ تُنفِقُوا مِمَّا تُحِبُّونَ ۚ وَمَا تُنفِقُوا مِن
شَيْءٍ فَإِنَّ اللهَ بِهِ عَلِيمٌ
Lan tanaloo albirra hattatunfiqoo mimma tuhibboona wama tunfiqoo minshay-in
fa-inna Allaha bihi AAaleem
Yoruba
Ọwọ́ yín kò lè ba oore náà (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ń ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.
|
Ayah 3:93 الأية
كُلُّ الطَّعَامِ كَانَ حِلًّا لِّبَنِي إِسْرَائِيلَ إِلَّا مَا حَرَّمَ
إِسْرَائِيلُ عَلَىٰ نَفْسِهِ مِن قَبْلِ أَن تُنَزَّلَ التَّوْرَاةُ ۗ قُلْ
فَأْتُوا بِالتَّوْرَاةِ فَاتْلُوهَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Kullu attaAAami kanahillan libanee isra-eela illa ma harramaisra-eelu AAala
nafsihi min qabli an tunazzala attawratuqul fa/too bittawrati fatlooha inkuntum
sadiqeen
Yoruba
Gbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl àyàfi èyí tí 'Isrọ̄'īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: "Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo."
|
Ayah 3:94 الأية
فَمَنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللهِ الْكَذِبَ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ
الظَّالِمُونَ
Famani iftara AAala Allahialkathiba min baAAdi thalika faola-ika humuathalimoon
Yoruba
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni alábòsí.
|
Ayah 3:95 الأية
قُلْ صَدَقَ اللهُ ۗ فَاتَّبِعُوا مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا وَمَا كَانَ مِنَ
الْمُشْرِكِينَ
Qul sadaqa Allahu fattabiAAoomillata ibraheema haneefan wama kanamina
almushrikeen
Yoruba
Sọ pé: "Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-'Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ."
|
Ayah 3:96 الأية
إِنَّ أَوَّلَ بَيْتٍ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكًا وَهُدًى
لِّلْعَالَمِينَ
Inna awwala baytin wudiAAa linnasilallathee bibakkata mubarakan wahudan
lilAAalameen
Yoruba
Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah. (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 3:97 الأية
فِيهِ آيَاتٌ بَيِّنَاتٌ مَّقَامُ إِبْرَاهِيمَ ۖ وَمَن دَخَلَهُ كَانَ آمِنًا ۗ
وَلِلَّهِ عَلَى النَّاسِ حِجُّ الْبَيْتِ مَنِ اسْتَطَاعَ إِلَيْهِ سَبِيلًا ۚ
وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ اللهَ غَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ
Feehi ayatun bayyinatunmaqamu ibraheema waman dakhalahu kana aminanwalillahi
AAala annasi hijjualbayti mani istataAAa ilayhi sabeelan waman kafarafa-inna
Allaha ghaniyyun AAani alAAalameen
Yoruba
Àwọn àmì tó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 3:98 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللهِ وَاللهُ شَهِيدٌ
عَلَىٰ مَا تَعْمَلُونَ
Qul ya ahla alkitabi limatakfuroona bi-ayati Allahi wallahushaheedun AAala ma
taAAmaloon
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
|
Ayah 3:99 الأية
قُلْ يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لِمَ تَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللهِ مَنْ آمَنَ
تَبْغُونَهَا عِوَجًا وَأَنتُمْ شُهَدَاءُ ۗ وَمَا اللهُ بِغَافِلٍ عَمَّا
تَعْمَلُونَ
Qul ya ahla alkitabi lima tasuddoonaAAan sabeeli Allahi man amana
tabghoonahaAAiwajan waantum shuhadao wama Allahu bighafilinAAamma taAAmaloon
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ̀yin onítírà, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni tó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ó wọ́, ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo 'Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
|
Ayah 3:100 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن تُطِيعُوا فَرِيقًا مِّنَ الَّذِينَ أُوتُوا
الْكِتَابَ يَرُدُّوكُم بَعْدَ إِيمَانِكُمْ كَافِرِينَ
Ya ayyuha allatheena amanooin tuteeAAoo fareeqan mina allatheena ootoo
alkitabayaruddookum baAAda eemanikum kafireen
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 3:101 الأية
وَكَيْفَ تَكْفُرُونَ وَأَنتُمْ تُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ آيَاتُ اللهِ وَفِيكُمْ
رَسُولُهُ ۗ وَمَن يَعْتَصِم بِاللهِ فَقَدْ هُدِيَ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ
Wakayfa takfuroona waantum tutlaAAalaykum ayatu Allahi wafeekum rasooluhuwaman
yaAAtasim billahi faqad hudiya ilasiratin mustaqeem
Yoruba
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.
|
Ayah 3:102 الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللهَ حَقَّ تُقَاتِهِ وَلَا تَمُوتُنَّ
إِلَّا وَأَنتُم مُّسْلِمُونَ
Ya ayyuha allatheena amanooittaqoo Allaha haqqa tuqatihi walatamootunna illa
waantum muslimoon
Yoruba
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí.
|
Ayah 3:103 الأية
وَاعْتَصِمُوا بِحَبْلِ اللهِ جَمِيعًا وَلَا تَفَرَّقُوا ۚ وَاذْكُرُوا نِعْمَتَ
اللهِ عَلَيْكُمْ إِذْ كُنتُمْ أَعْدَاءً فَأَلَّفَ بَيْنَ قُلُوبِكُمْ
فَأَصْبَحْتُم بِنِعْمَتِهِ إِخْوَانًا وَكُنتُمْ عَلَىٰ شَفَا حُفْرَةٍ مِّنَ
النَّارِ فَأَنقَذَكُم مِّنْهَا ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللهُ لَكُمْ آيَاتِهِ
لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
WaAAtasimoo bihabliAllahi jameeAAan wala tafarraqoo wathkurooniAAmata Allahi
AAalaykum ith kuntum aAAdaanfaallafa bayna quloobikum faasbahtum
biniAAmatihiikhwanan wakuntum AAala shafa hufratinmina annari faanqathakum minha
kathalikayubayyinu Allahu lakum ayatihi laAAallakumtahtadoon
Yoruba
Ẹ dìmọ́ okùn Allāhu (al-Ƙur'ān) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú 'Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà ('Islām).
|
Ayah 3:104 الأية
وَلْتَكُن مِّنكُمْ أُمَّةٌ يَدْعُونَ إِلَى الْخَيْرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ
وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Waltakun minkum ommatun yadAAoona ilaalkhayri waya/muroona bilmaAAroofi
wayanhawna AAanialmunkari waola-ika humu almuflihoon
Yoruba
Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun tó lóore, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
|
Ayah 3:105 الأية
وَلَا تَكُونُوا كَالَّذِينَ تَفَرَّقُوا وَاخْتَلَفُوا مِن بَعْدِ مَا جَاءَهُمُ
الْبَيِّنَاتُ ۚ وَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Wala takoonoo kallatheenatafarraqoo wakhtalafoo min baAAdi ma jaahumualbayyinatu
waola-ika lahum AAathabun AAatheem
Yoruba
Ẹ má ṣe dà bí àwọn tó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí 'Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé tó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún.
|
Ayah 3:106 الأية
يَوْمَ تَبْيَضُّ وُجُوهٌ وَتَسْوَدُّ وُجُوهٌ ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ اسْوَدَّتْ
وُجُوهُهُمْ أَكَفَرْتُم بَعْدَ إِيمَانِكُمْ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ
تَكْفُرُونَ
Yawma tabyaddu wujoohun wataswadduwujoohun faamma allatheena iswaddat
wujoohuhumakafartum baAAda eemanikum fathooqoo alAAathababima kuntum takfuroon
Yoruba
Ní ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (fún ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́.
|
Ayah 3:107 الأية
وَأَمَّا الَّذِينَ ابْيَضَّتْ وُجُوهُهُمْ فَفِي رَحْمَةِ اللهِ هُمْ فِيهَا
خَالِدُونَ
Waamma allatheena ibyaddatwujoohuhum fafee rahmati Allahi hum feeha khalidoon
Yoruba
Ní ti àwọn tí ojú wọn funfun (fún ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
|
Ayah 3:108 الأية
تِلْكَ آيَاتُ اللهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۗ وَمَا اللهُ يُرِيدُ
ظُلْمًا لِّلْعَالَمِينَ
Tilka ayatu Allahinatlooha AAalayka bilhaqqi wama Allahuyureedu thulman
lilAAalameen
Yoruba
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 3:109 الأية
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَإِلَى اللهِ تُرْجَعُ
الْأُمُورُ
Walillahi ma fee assamawatiwama fee al-ardi wa-ila AllahiturjaAAu al-omoor
Yoruba
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
|
Ayah 3:110 الأية
كُنتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ
وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَتُؤْمِنُونَ بِاللهِ ۗ وَلَوْ آمَنَ أَهْلُ
الْكِتَابِ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُم ۚ مِّنْهُمُ الْمُؤْمِنُونَ وَأَكْثَرُهُمُ
الْفَاسِقُونَ
Kuntum khayra ommatin okhrijat linnasita/muroona bilmaAAroofi watanhawna AAani
almunkariwatu/minoona billahi walaw amana ahlu alkitabilakana khayran lahum
minhumu almu/minoona waaktharuhumualfasiqoon
Yoruba
Ẹ jẹ́ ìjọ tó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 3:111 الأية
لَن يَضُرُّوكُمْ إِلَّا أَذًى ۖ وَإِن يُقَاتِلُوكُمْ يُوَلُّوكُمُ الْأَدْبَارَ
ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ
Lan yadurrookum illa athanwa-in yuqatilookum yuwallookumu al-adbara thumma
layunsaroon
Yoruba
Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
|
Ayah 3:112 الأية
ضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ الذِّلَّةُ أَيْنَ مَا ثُقِفُوا إِلَّا بِحَبْلٍ مِّنَ اللهِ
وَحَبْلٍ مِّنَ النَّاسِ وَبَاءُوا بِغَضَبٍ مِّنَ اللهِ وَضُرِبَتْ عَلَيْهِمُ
الْمَسْكَنَةُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَانُوا يَكْفُرُونَ بِآيَاتِ اللهِ
وَيَقْتُلُونَ الْأَنبِيَاءَ بِغَيْرِ حَقٍّ ۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَوا وَّكَانُوا
يَعْتَدُونَ
Duribat AAalayhimu aththillatuayna ma thuqifoo illa bihablin mina Allahiwahablin
mina annasi wabaoo bighadabinmina Allahi waduribat AAalayhimu almaskanatu
thalikabi-annahum kanoo yakfuroona bi-ayati Allahiwayaqtuloona al-anbiyaa
bighayri haqqin thalikabima AAasaw wakanoo yaAAtadoon
Yoruba
Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bà wọ́n àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba 'Islām) àti àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba 'Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu ààlà.
|
Ayah 3:113 الأية
لَيْسُوا سَوَاءً ۗ مِّنْ أَهْلِ الْكِتَابِ أُمَّةٌ قَائِمَةٌ يَتْلُونَ آيَاتِ
اللهِ آنَاءَ اللَّيْلِ وَهُمْ يَسْجُدُونَ
Laysoo sawaan min ahli alkitabiommatun qa-imatun yatloona ayati Allahianaa
allayli wahum yasjudoon
Yoruba
(Àwọn onítírà) kò rí bákan náà. Ìjọ kan tó dúró déédé wà nínú àwọn onítírà, tí ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun).
|
Ayah 3:114 الأية
يُؤْمِنُونَ بِاللهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ
وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَيُسَارِعُونَ فِي الْخَيْرَاتِ وَأُولَٰئِكَ مِنَ
الصَّالِحِينَ
Yu/minoona billahi walyawmial-akhiri waya/muroona bilmaAAroofi wayanhawnaAAani
almunkari wayusariAAoona fee alkhayrati waola-ikamina assaliheen
Yoruba
Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere.
|
Ayah 3:115 الأية
وَمَا يَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَلَن يُكْفَرُوهُ ۗ وَاللهُ عَلِيمٌ
بِالْمُتَّقِينَ
Wama yafAAaloo min khayrin falanyukfaroohu wallahu AAaleemun bilmuttaqeen
Yoruba
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ gbé. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
|
Ayah 3:116 الأية
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَن تُغْنِيَ عَنْهُمْ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُم
مِّنَ اللهِ شَيْئًا ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۚ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Inna allatheena kafaroo lan tughniyaAAanhum amwaluhum wala awladuhum mina
Allahishay-an waola-ika as-habu annarihum feeha khalidoon
Yoruba
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
|
Ayah 3:117 الأية
مَثَلُ مَا يُنفِقُونَ فِي هَٰذِهِ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَثَلِ رِيحٍ فِيهَا
صِرٌّ أَصَابَتْ حَرْثَ قَوْمٍ ظَلَمُوا أَنفُسَهُمْ فَأَهْلَكَتْهُ ۚ وَمَا
ظَلَمَهُمُ اللهُ وَلَٰكِنْ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Mathalu ma yunfiqoona fee hathihialhayati addunya kamathali reehinfeeha sirrun
asabat hartha qawmin thalamooanfusahum faahlakat-hu wama thalamahumu
Allahuwalakin anfusahum yathlimoon
Yoruba
Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s'órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
|
|