Prev  

61. Surah As-Saff سورة الصف

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Sabbaha lillahi ma fee assamawatiwama fee al-ardi wahuwa alAAazeezu alhakeem

Yoruba
 
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  61:2  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفْعَلُونَ
Ya ayyuha allatheena amanoolima taqooloona ma la tafAAaloon

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́?

Ayah  61:3  الأية
كَبُرَ مَقْتًا عِندَ اللهِ أَن تَقُولُوا مَا لَا تَفْعَلُونَ
Kabura maqtan AAinda Allahi antaqooloo ma la tafAAaloon

Yoruba
 
Ó jẹ́ ohun ìbínú tó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe.

Ayah  61:4  الأية
إِنَّ اللهَ يُحِبُّ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِهِ صَفًّا كَأَنَّهُم بُنْيَانٌ مَّرْصُوصٌ
Inna Allaha yuhibbu allatheenayuqatiloona fee sabeelihi saffan kaannahum bunyanunmarsoos

Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn tó ń jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ilé tí wọ́n lẹ̀pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n

Ayah  61:5  الأية
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ لِمَ تُؤْذُونَنِي وَقَد تَّعْلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ اللهِ إِلَيْكُمْ ۖ فَلَمَّا زَاغُوا أَزَاغَ اللهُ قُلُوبَهُمْ ۚ وَاللهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ
Wa-ith qala moosaliqawmihi ya qawmi lima tu/thoonanee waqadtaAAlamoona annee rasoolu Allahi ilaykum falamma zaghooazagha Allahu quloobahum wallahu layahdee alqawma alfasiqeen

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín." Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Ayah  61:6  الأية
وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللهِ إِلَيْكُم مُّصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِن بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُم بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ
Wa-ith qala AAeesa ibnumaryama ya banee isra-eela innee rasoolu Allahiilaykum musaddiqan lima bayna yadayya mina attawratiwamubashshiran birasoolin ya/tee min baAAdee ismuhu ahmadufalamma jaahum bilbayyinati qaloohatha sihrun mubeen

Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ 'Isrọ̄'īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni 'Ahmọd." Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, wọ́n á wí pé: "Idán pọ́nńbélé ni èyí."

Ayah  61:7  الأية
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللهِ الْكَذِبَ وَهُوَ يُدْعَىٰ إِلَى الْإِسْلَامِ ۚ وَاللهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Waman athlamu mimmani iftaraAAala Allahi alkathiba wahuwa yudAAaila al-islami wallahu layahdee alqawma aththalimeen

Yoruba
 
Ta sì ni ó ṣàbòsí tó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú 'Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

Ayah  61:8  الأية
يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ
Yureedoona liyutfi-oo noora Allahibi-afwahihim wallahu mutimmu noorihi walawkariha alkafiroon

Yoruba
 
Wọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.

Ayah  61:9  الأية
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ
Huwa allathee arsala rasoolahu bilhudawadeeni alhaqqi liyuthhirahu AAala addeenikullihi walaw kariha almushrikoon

Yoruba
 
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo ('Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.

Ayah  61:10  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ تِجَارَةٍ تُنجِيكُم مِّنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Ya ayyuha allatheena amanoohal adullukum AAala tijaratin tunjeekum min AAathabinaleem

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

Ayah  61:11  الأية
تُؤْمِنُونَ بِاللهِ وَرَسُولِهِ وَتُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللهِ بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Tu/minoona billahiwarasoolihi watujahidoona fee sabeeli Allahi bi-amwalikumwaanfusikum thalikum khayrun lakum in kuntum taAAlamoon

Yoruba
 
Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.

Ayah  61:12  الأية
يَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَيُدْخِلْكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Yaghfir lakum thunoobakumwayudkhilkum jannatin tajree min tahtihaal-anharu wamasakina tayyibatan fee jannatiAAadnin thalika alfawzu alAAatheem

Yoruba
 
(Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

Ayah  61:13  الأية
وَأُخْرَىٰ تُحِبُّونَهَا ۖ نَصْرٌ مِّنَ اللهِ وَفَتْحٌ قَرِيبٌ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
Waokhra tuhibboonaha nasrunmina Allahi wafathun qarreebun wabashshirialmu/mineen

Yoruba
 
Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun tó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.

Ayah  61:14  الأية
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا أَنصَارَ اللهِ كَمَا قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ لِلْحَوَارِيِّينَ مَنْ أَنصَارِي إِلَى اللهِ ۖ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ اللهِ ۖ فَآمَنَت طَّائِفَةٌ مِّن بَنِي إِسْرَائِيلَ وَكَفَرَت طَّائِفَةٌ ۖ فَأَيَّدْنَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَىٰ عَدُوِّهِمْ فَأَصْبَحُوا ظَاهِرِينَ
Ya ayyuha allatheena amanookoonoo ansara Allahi kama qala AAeesaibnu maryama lilhawariyyeena man ansaree ilaAllahi qala alhawariyyoona nahnuansaru Allahi faamanat ta-ifatun minbanee isra-eela wakafarat ta-ifatun faayyadnaallatheena amanoo AAala AAaduwwihim faasbahoothahireen

Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: "Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa (ẹ̀sìn) Allāhu?" Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: "Àwa ni alárànṣe (fún ẹ̀sìn) Allāhu." Igun kan nínú àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl gbàgbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn tó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí.font>





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us