Prev  

88. Surah Al-Ghâshiyah سورة الغاشية

  Next  




1st Ayah  1  الأية ١الأولي
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْغَاشِيَةِ
Hal ataka hadeethu alghashiyat

Yoruba
 
Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

Ayah  88:2  الأية
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ خَاشِعَةٌ
Wujoohun yawma-ithin khashiAAa

Yoruba
 
Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.

Ayah  88:3  الأية
عَامِلَةٌ نَّاصِبَةٌ
AAamilatun nasiba

Yoruba
 
Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).

Ayah  88:4  الأية
تَصْلَىٰ نَارًا حَامِيَةً
Tasla naran hamiya

Yoruba
 
Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).

Ayah  88:5  الأية
تُسْقَىٰ مِنْ عَيْنٍ آنِيَةٍ
Tusqa min AAaynin aniya

Yoruba
 
Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.

Ayah  88:6  الأية
لَّيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٍ
Laysa lahum taAAamun illamin dareeAA

Yoruba
 
Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.

Ayah  88:7  الأية
لَّا يُسْمِنُ وَلَا يُغْنِي مِن جُوعٍ
La yusminu wala yughnee minjooAA

Yoruba
 
Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.

Ayah  88:8  الأية
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاعِمَةٌ
Wujoohun yawma-ithin naAAima

Yoruba
 
Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn

Ayah  88:9  الأية
لِّسَعْيِهَا رَاضِيَةٌ
LisaAAyiha radiya

Yoruba
 
Nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.

Ayah  88:10  الأية
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ
Fee jannatin AAaliya

Yoruba
 
(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.

Ayah  88:11  الأية
لَّا تَسْمَعُ فِيهَا لَاغِيَةً
La tasmaAAu feeha laghiya

Yoruba
 
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.

Ayah  88:12  الأية
فِيهَا عَيْنٌ جَارِيَةٌ
Feeha AAaynun jariya

Yoruba
 
Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.

Ayah  88:13  الأية
فِيهَا سُرُرٌ مَّرْفُوعَةٌ
Feeha sururun marfooAAa

Yoruba
 
Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,

Ayah  88:14  الأية
وَأَكْوَابٌ مَّوْضُوعَةٌ
Waakwabun mawdooAAa

Yoruba
 
Àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),

Ayah  88:15  الأية
وَنَمَارِقُ مَصْفُوفَةٌ
Wanamariqu masfoofa

Yoruba
 
Àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,

Ayah  88:16  الأية
وَزَرَابِيُّ مَبْثُوثَةٌ
Wazarabiyyu mabthootha

Yoruba
 
Àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.

Ayah  88:17  الأية
أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى الْإِبِلِ كَيْفَ خُلِقَتْ
Afala yanthuroona ilaal-ibili kayfa khuliqat

Yoruba
 
Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;

Ayah  88:18  الأية
وَإِلَى السَّمَاءِ كَيْفَ رُفِعَتْ
Wa-ila assama-i kayfarufiAAat

Yoruba
 
Àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;

Ayah  88:19  الأية
وَإِلَى الْجِبَالِ كَيْفَ نُصِبَتْ
Wa-ila aljibali kayfa nusibat

Yoruba
 
Àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);

Ayah  88:20  الأية
وَإِلَى الْأَرْضِ كَيْفَ سُطِحَتْ
Wa-ila al-ardi kayfa sutihat

Yoruba
 
Àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?

Ayah  88:21  الأية
فَذَكِّرْ إِنَّمَا أَنتَ مُذَكِّرٌ
Fathakkir innama anta muthakkir

Yoruba
 
Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.

Ayah  88:22  الأية
لَّسْتَ عَلَيْهِم بِمُصَيْطِرٍ
Lasta AAalayhim bimusaytir

Yoruba
 
Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn

Ayah  88:23  الأية
إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ
Illa man tawalla wakafar

Yoruba
 
Àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.

Ayah  88:24  الأية
فَيُعَذِّبُهُ اللهُ الْعَذَابَ الْأَكْبَرَ
FayuAAaththibuhu Allahu alAAathabaal-akbar

Yoruba
 
Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.

Ayah  88:25  الأية
إِنَّ إِلَيْنَا إِيَابَهُمْ
Inna ilayna iyabahum

Yoruba
 
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.

Ayah  88:26  الأية
ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا حِسَابَهُم
Thumma inna AAalayna hisabahum

Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l'A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.





© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us