Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn, (wọ́n sọ) pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Allāhu." Wọ́n wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: "Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?" Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni? Wọ́n sì ń tako àwọn āyah Wa!
Títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: "Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?" Wọ́n yóò sọ pé: "Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l'Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l'Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."
Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn, tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ tó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí tó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san.
A ku n yín) sìn títí di ọjọá hu pátápátá.n ní Ọjọ́ Àjíǹde.́ wọn gbàgbé Allāhu.ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn tó ṣe sùúrù. A kò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá.
Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀).
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur'ān.
A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur'ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan?