Prev  

66. Surah At-Tahrîm سورة التحريم

  Next  




Ayah  66:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ لِمَ تُحَرِّمُ مَا أَحَلَّ اللهُ لَكَ ۖ تَبْتَغِي مَرْضَاتَ أَزْوَاجِكَ ۚ وَاللهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba
 
Ìwọ Ànábì, nítorí kí ni o ṣe máa sọ n̄ǹkan tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ di èèwọ̀? Ìwọ ń wá ìyọ́nú àwọn ìyàwó rẹ. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  66:2  الأية
    +/- -/+  
قَدْ فَرَضَ اللهُ لَكُمْ تَحِلَّةَ أَيْمَانِكُمْ ۚ وَاللهُ مَوْلَاكُمْ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Allāhu ti ṣe àlàyé òfin ìtánràn ìbúra yín fún yín. Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ yín. Òun sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  66:3  الأية
    +/- -/+  
وَإِذْ أَسَرَّ النَّبِيُّ إِلَىٰ بَعْضِ أَزْوَاجِهِ حَدِيثًا فَلَمَّا نَبَّأَتْ بِهِ وَأَظْهَرَهُ اللهُ عَلَيْهِ عَرَّفَ بَعْضَهُ وَأَعْرَضَ عَن بَعْضٍ ۖ فَلَمَّا نَبَّأَهَا بِهِ قَالَتْ مَنْ أَنبَأَكَ هَٰذَا ۖ قَالَ نَبَّأَنِيَ الْعَلِيمُ الْخَبِيرُ
Yoruba
 
Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni tó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā'iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i). Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: "O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā'iṣah létí."). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: "Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?" (Ànábì) sọ pé: "Onímọ̀, Alámọ̀tán l'Ó fún mi ní ìró náà."

Ayah  66:4  الأية
    +/- -/+  
إِن تَتُوبَا إِلَى اللهِ فَقَدْ صَغَتْ قُلُوبُكُمَا ۖ وَإِن تَظَاهَرَا عَلَيْهِ فَإِنَّ اللهَ هُوَ مَوْلَاهُ وَجِبْرِيلُ وَصَالِحُ الْمُؤْمِنِينَ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ بَعْدَ ذَٰلِكَ ظَهِيرٌ
Yoruba
 
Tí ẹ̀yin méjèèjì bá ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu, (Ó máa gba ìronúpìwàdà yín). Ṣebí ọkàn yín kúkú ti tẹ̀ (síbi kí Ànábì má fẹ̀ẹ́ Mọ̄riyah). Tí ẹ bá sì ran ara yín lọ́wọ́ (láti kó ìbànújẹ́) bá a, dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, àti (mọlāika) Jibrīl àti ẹni rere nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn mọlāika tí wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (tún wà fún un).

Ayah  66:5  الأية
    +/- -/+  
عَسَىٰ رَبُّهُ إِن طَلَّقَكُنَّ أَن يُبْدِلَهُ أَزْوَاجًا خَيْرًا مِّنكُنَّ مُسْلِمَاتٍ مُّؤْمِنَاتٍ قَانِتَاتٍ تَائِبَاتٍ عَابِدَاتٍ سَائِحَاتٍ ثَيِّبَاتٍ وَأَبْكَارًا
Yoruba
 
Ó ṣeé ṣe, tí ó bá kọ̀ yín sílẹ̀, kí Olúwa rẹ̀ fi àwọn obìnrin kan, tí wọn lóore jù yín lọ rọ́pò fún un, (tí wọ́n máa jẹ́) mùsùlùmí, onígbàgbọ́ òdodo, olùtẹ̀lé-àṣẹ, olùronúpìwàdà, olùjọ́sìn, olùgbààwẹ̀ (tí wọ́n máa jẹ́) adélébọ̀ àti wúńdíá.

Ayah  66:6  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قُوا أَنفُسَكُمْ وَأَهْلِيكُمْ نَارًا وَقُودُهَا النَّاسُ وَالْحِجَارَةُ عَلَيْهَا مَلَائِكَةٌ غِلَاظٌ شِدَادٌ لَّا يَعْصُونَ اللهَ مَا أَمَرَهُمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí ara yín àti àwọn ará ilé yín níbi Iná. Ènìyàn àti òkúta ni n̄ǹkan ìkoná rẹ̀. Àwọn mọlāika tó rorò, tí wọ́n le ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. Wọn kò níí yapa àṣẹ Allāhu níbi ohun tí Ó bá pa láṣẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá pa láṣẹ fún wọn.

Ayah  66:7  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ كَفَرُوا لَا تَعْتَذِرُوا الْيَوْمَ ۖ إِنَّمَا تُجْزَوْنَ مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ ṣàì gbàgbọ́, ẹ má ṣe ṣàròyé ní ọjọ́ òní. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.

Ayah  66:8  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا تُوبُوا إِلَى اللهِ تَوْبَةً نَّصُوحًا عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَن يُكَفِّرَ عَنكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَيُدْخِلَكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ يَوْمَ لَا يُخْزِي اللهُ النَّبِيَّ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ ۖ نُورُهُمْ يَسْعَىٰ بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَبِأَيْمَانِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا أَتْمِمْ لَنَا نُورَنَا وَاغْفِرْ لَنَا ۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba
 
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní ìronúpìwàdà òdodo. Ó ṣeé ṣe pé Olúwa yín máa pa àwọn àṣìṣe yín rẹ́ fún yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ tí Allāhu kò níí dójú ti Ànábì àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọn yóò sọ pé: "Olúwa wa, pé ìmọ́lẹ̀ wa fún wa, kí O sì foríjìn wá. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan."

Ayah  66:9  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Yoruba
 
Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Ibùgbé wọn sì ni iná Jahanamọ. Ìkángun náà sì burú.

Ayah  66:10  الأية
    +/- -/+  
ضَرَبَ اللهُ مَثَلًا لِّلَّذِينَ كَفَرُوا امْرَأَتَ نُوحٍ وَامْرَأَتَ لُوطٍ ۖ كَانَتَا تَحْتَ عَبْدَيْنِ مِنْ عِبَادِنَا صَالِحَيْنِ فَخَانَتَاهُمَا فَلَمْ يُغْنِيَا عَنْهُمَا مِنَ اللهِ شَيْئًا وَقِيلَ ادْخُلَا النَّارَ مَعَ الدَّاخِلِينَ
Yoruba
 
Allāhu fi ìyàwó (Ànábì) Nūh àti ìyàwó (Ànábì) Lūt ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ẹrúsìn méjì rere nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Àwọn (obìnrin) méjèèjì sì jàǹbá àwọn ọkọ wọn. Àwọn ọkọ wọn kò sì fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. A ó sì sọ fún àwọn obìnrin méjèèjì pé: "Ẹ wọ inú Iná pẹ̀lú àwọn olùwọlé (sínú Iná)."

Ayah  66:11  الأية
    +/- -/+  
وَضَرَبَ اللهُ مَثَلًا لِّلَّذِينَ آمَنُوا امْرَأَتَ فِرْعَوْنَ إِذْ قَالَتْ رَبِّ ابْنِ لِي عِندَكَ بَيْتًا فِي الْجَنَّةِ وَنَجِّنِي مِن فِرْعَوْنَ وَعَمَلِهِ وَنَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Yoruba
 
Allāhu tún fi ìyàwó Fir‘aon ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Nígbà tí ó sọ pé: "Olúwa mi, kọ́ ilé kan fún mi lọ́dọ̀ Rẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Là mí lọ́wọ́ Fir‘aon àti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Kí O sì là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí."

Ayah  66:12  الأية
    +/- -/+  
وَمَرْيَمَ ابْنَتَ عِمْرَانَ الَّتِي أَحْصَنَتْ فَرْجَهَا فَنَفَخْنَا فِيهِ مِن رُّوحِنَا وَصَدَّقَتْ بِكَلِمَاتِ رَبِّهَا وَكُتُبِهِ وَكَانَتْ مِنَ الْقَانِتِينَ
Yoruba
 
Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us