Prev  

84. Surah Al-Inshiqâq سورة الإنشقاق

  Next  




Ayah  84:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
إِذَا السَّمَاءُ انشَقَّتْ
Yoruba
 
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

Ayah  84:2  الأية
    +/- -/+  
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ
Yoruba
 
- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ -

Ayah  84:3  الأية
    +/- -/+  

Ayah  84:4  الأية
    +/- -/+  
وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ
Yoruba
 
Ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo

Ayah  84:5  الأية
    +/- -/+  
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ
Yoruba
 
- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)

Ayah  84:6  الأية
    +/- -/+  
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَاقِيهِ
Yoruba
 
Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.

Ayah  84:7  الأية
    +/- -/+  
فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ
Yoruba
 
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,

Ayah  84:8  الأية
    +/- -/+  
فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا
Yoruba
 
Láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.

Ayah  84:9  الأية
    +/- -/+  
وَيَنقَلِبُ إِلَىٰ أَهْلِهِ مَسْرُورًا
Yoruba
 
Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.

Ayah  84:10  الأية
    +/- -/+  
وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ وَرَاءَ ظَهْرِهِ
Yoruba
 
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,

Ayah  84:11  الأية
    +/- -/+  


Ayah  84:13  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ كَانَ فِي أَهْلِهِ مَسْرُورًا
Yoruba
 
Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).

Ayah  84:14  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ
Yoruba
 
Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).

Ayah  84:15  الأية
    +/- -/+  
بَلَىٰ إِنَّ رَبَّهُ كَانَ بِهِ بَصِيرًا
Yoruba
 
Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.

Ayah  84:16  الأية
    +/- -/+  
فَلَا أُقْسِمُ بِالشَّفَقِ
Yoruba
 
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.

Ayah  84:17  الأية
    +/- -/+  
وَاللَّيْلِ وَمَا وَسَقَ
Yoruba
 
Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.

Ayah  84:18  الأية
    +/- -/+  
وَالْقَمَرِ إِذَا اتَّسَقَ
Yoruba
 
Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.

Ayah  84:19  الأية
    +/- -/+  
لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ
Yoruba
 
Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.

Ayah  84:20  الأية
    +/- -/+  
فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Kí l'ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?

Ayah  84:21  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ الْقُرْآنُ لَا يَسْجُدُونَ ۩
Yoruba
 
Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur'ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.

Ayah  84:22  الأية
    +/- -/+  
بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُكَذِّبُونَ
Yoruba
 
Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.

Ayah  84:23  الأية
    +/- -/+  
وَاللهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ
Yoruba
 
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).

Ayah  84:24  الأية
    +/- -/+  
فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Yoruba
 
Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

Ayah  84:25  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ
Yoruba
 
Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn.
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us