Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àti àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ.
Àwọn yẹhudi wí pé: "‘Uzaer ni ọmọ Allāhu." Àwọn nasọ̄rọ̄ sì wí pé: "Mọsīh ni ọmọ Allāhu." Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasọ̄rọ̄) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: "Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé."
Wọ́n kúkú ti wá ìyọnu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì fimú fínlẹ̀ sì ọ (tí wọ́n dete sì ọ) títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì borí; ẹ̀mí wọn sì kórira rẹ̀.
Tí dáadáa kan bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: "A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)" Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú.
Sọ pé: "Kò sí ohun kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa." Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kórira rẹ̀.
Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́.
Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan tó ń bẹ̀rù.
Wọ́n ń fi Allāhu búra fún yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ló sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pe kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: "Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni." Sọ pé: "Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́?"
Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ alátìlẹ́yìn fún apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba 'Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì gbúnrí (tí wọ́n kọ̀yìn si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.