1st Ayah 1 الأية ١الأوليبِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الم
Alif-lam-meem
Yoruba
'Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)
|
Ayah 29:2 الأية
أَحَسِبَ النَّاسُ أَن يُتْرَكُوا أَن يَقُولُوا آمَنَّا وَهُمْ لَا يُفْتَنُونَ
Ahasiba annasu anyutrakoo an yaqooloo amanna wahum layuftanoon
Yoruba
Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: "A gbàgbọ́", tí A ò sì níí dán wọn wò?
|
Ayah 29:3 الأية
وَلَقَدْ فَتَنَّا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَلَيَعْلَمَنَّ اللهُ الَّذِينَ
صَدَقُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْكَاذِبِينَ
Walaqad fatanna allatheena minqablihim falayaAAlamanna Allahu allatheena
sadaqoowalayaAAlamanna alkathibeen
Yoruba
A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.
|
Ayah 29:4 الأية
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ أَن يَسْبِقُونَا ۚ سَاءَ مَا
يَحْكُمُونَ
Am hasiba allatheenayaAAmaloona assayyi-ati an yasbiqoona saama yahkumoon
Yoruba
Àbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.
|
Ayah 29:5 الأية
مَن كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ اللهِ فَإِنَّ أَجَلَ اللهِ لَآتٍ ۚ وَهُوَ
السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Man kana yarjoo liqaa Allahifa-inna ajala Allahi laatin wahuwa
assameeAAualAAaleem
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
|
Ayah 29:6 الأية
وَمَن جَاهَدَ فَإِنَّمَا يُجَاهِدُ لِنَفْسِهِ ۚ إِنَّ اللهَ لَغَنِيٌّ عَنِ
الْعَالَمِينَ
Waman jahada fa-innama yujahidulinafsihi inna Allaha laghaniyyun AAani
alAAalameen
Yoruba
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 29:7 الأية
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ
سَيِّئَاتِهِمْ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَحْسَنَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ
Wallatheena amanoowaAAamiloo assalihati lanukaffirannaAAanhum sayyi-atihim
walanajziyannahum ahsana allatheekanoo yaAAmaloon
Yoruba
Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 29:8 الأية
وَوَصَّيْنَا الْإِنسَانَ بِوَالِدَيْهِ حُسْنًا ۖ وَإِن جَاهَدَاكَ لِتُشْرِكَ بِي
مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَا ۚ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ
فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Wawassayna al-insana biwalidayhihusnan wa-in jahadaka litushrika bee malaysa
laka bihi AAilmun fala tutiAAhumailayya marjiAAukum faonabbi-okum bima kuntum
taAAmaloon
Yoruba
A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
|
Ayah 29:9 الأية
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُدْخِلَنَّهُمْ فِي الصَّالِحِينَ
Wallatheena amanoowaAAamiloo assalihati lanudkhilannahum feeassaliheen
Yoruba
Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọ́n sínú àwọn ẹni rere.
|
Ayah 29:10 الأية
وَمِنَ النَّاسِ مَن يَقُولُ آمَنَّا بِاللهِ فَإِذَا أُوذِيَ فِي اللهِ جَعَلَ
فِتْنَةَ النَّاسِ كَعَذَابِ اللهِ وَلَئِن جَاءَ نَصْرٌ مِّن رَّبِّكَ
لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمْ ۚ أَوَلَيْسَ اللهُ بِأَعْلَمَ بِمَا فِي
صُدُورِ الْعَالَمِينَ
Wamina annasi man yaqoolu amannabillahi fa-itha oothiya fee AllahijaAAala
fitnata annasi kaAAathabi Allahiwala-in jaa nasrun min rabbika layaqoolunna
innakunna maAAakum awa laysa Allahu bi-aAAlama bimafee sudoori alAAalameen
Yoruba
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: "A gba Allāhu gbọ́." Nígbà tí wọ́n bá sì fi ìnira kàn án nínú ẹ̀sìn Allāhu, ó máa mú ìnira àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyà ti Allāhu. (Ó sì máa padà sínú àìgbàgbọ́.) Tí àrànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ bá sì dé, dájúdájú wọn yóò wí pé: "Dájúdájú àwa wà pẹ̀lú yín." Ṣé Allāhu kọ́ l'Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà gbogbo ẹ̀dá ni?
|
Ayah 29:11 الأية
وَلَيَعْلَمَنَّ اللهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْمُنَافِقِينَ
WalayaAAlamanna Allahu allatheenaamanoo walayaAAlamanna almunafiqeen
Yoruba
Dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí.
|
Ayah 29:12 الأية
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا اتَّبِعُوا سَبِيلَنَا وَلْنَحْمِلْ
خَطَايَاكُمْ وَمَا هُم بِحَامِلِينَ مِنْ خَطَايَاهُم مِّن شَيْءٍ ۖ إِنَّهُمْ
لَكَاذِبُونَ
Waqala allatheena kafaroolillatheena amanoo ittabiAAoo sabeelanawalnahmil
khatayakum wama hum bihamileenamin khatayahum min shay-in innahum lakathiboon
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: "Ẹ tẹ̀lé ojú ọ̀nà tiwa nítorí kí á lè ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín." Wọn kò sì lè ru kiní kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
|
Ayah 29:13 الأية
وَلَيَحْمِلُنَّ أَثْقَالَهُمْ وَأَثْقَالًا مَّعَ أَثْقَالِهِمْ ۖ وَلَيُسْأَلُنَّ
يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَمَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Walayahmilunna athqalahumwaathqalan maAAa athqalihim walayus-alunna
yawmaalqiyamati AAamma kanoo yaftaroon
Yoruba
Dájúdájú wọn yóò ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn àti àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kan mọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. Àti pé dájúdájú A óò bi wọ́n léèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
|
Ayah 29:14 الأية
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ
إِلَّا خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ الطُّوفَانُ وَهُمْ ظَالِمُونَ
Walaqad arsalna noohan ilaqawmihi falabitha feehim alfa sanatin illa khamseena
AAamanfaakhathahumu attoofanu wahum thalimoon
Yoruba
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó gbé láààrin wọn fún ẹgbẹ̀rún ọdún àfi àádọ́ta ọdún. Ẹ̀kún-omi sì gbá wọn mú nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí.
|
Ayah 29:15 الأية
فَأَنجَيْنَاهُ وَأَصْحَابَ السَّفِينَةِ وَجَعَلْنَاهَا آيَةً لِّلْعَالَمِينَ
Faanjaynahu waas-haba assafeenatiwajaAAalnaha ayatan lilAAalameen
Yoruba
A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.
|
Ayah 29:16 الأية
وَإِبْرَاهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ اعْبُدُوا اللهَ وَاتَّقُوهُ ۖ ذَٰلِكُمْ
خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ
Wa-ibraheema ith qalaliqawmihi oAAbudoo Allaha wattaqoohu thalikumkhayrun lakum
in kuntum taAAlamoon
Yoruba
(Rántí Ànábì) 'Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀."
|
Ayah 29:17 الأية
إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ أَوْثَانًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا ۚ إِنَّ
الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا
فَابْتَغُوا عِندَ اللهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ ۖ إِلَيْهِ
تُرْجَعُونَ
Innama taAAbudoona min dooni Allahiawthanan watakhluqoona ifkan inna
allatheenataAAbudoona min dooni Allahi la yamlikoona lakumrizqan fabtaghoo
AAinda Allahi arrizqa waAAbudoohuwashkuroo lahu ilayhi turjaAAoon
Yoruba
Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fún yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
|
Ayah 29:18 الأية
وَإِن تُكَذِّبُوا فَقَدْ كَذَّبَ أُمَمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ۖ وَمَا عَلَى الرَّسُولِ
إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
Wa-in tukaththiboo faqad kaththabaomamun min qablikum wama AAala arrasooliilla
albalaghu almubeen
Yoruba
Tí ẹ bá sì pe (òdodo) ní irọ́, àwọn ìjọ kan tó ṣíwájú yín kúkú ti pe (òdodo) ní irọ́. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
|
Ayah 29:19 الأية
أَوَلَمْ يَرَوْا كَيْفَ يُبْدِئُ اللهُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۚ إِنَّ
ذَٰلِكَ عَلَى اللهِ يَسِيرٌ
Awa lam yaraw kayfa yubdi-o Allahualkhalqa thumma yuAAeeduhu inna thalika AAala
Allahiyaseer
Yoruba
Tàbí wọn kò wòye sí bí Allāhu ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá ni? Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
|
Ayah 29:20 الأية
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ بَدَأَ الْخَلْقَ ۚ ثُمَّ اللهُ
يُنشِئُ النَّشْأَةَ الْآخِرَةَ ۚ إِنَّ اللهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Qul seeroo fee al-ardi fanthurookayfa badaa alkhalqa thumma Allahu yunshi-o
annash-ataal-akhirata inna Allaha AAala kulli shay-inqadeer
Yoruba
Sọ pé: "Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí Ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá (ní ìpìlẹ̀). Lẹ́yìn náà, Allāhu l'Ó máa mú ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn wá (fún àjíǹde). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan."
|
Ayah 29:21 الأية
يُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ وَيَرْحَمُ مَن يَشَاءُ ۖ وَإِلَيْهِ تُقْلَبُونَ
YuAAaththibu man yashao wayarhamuman yashao wa-ilayhi tuqlaboon
Yoruba
Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
|
Ayah 29:22 الأية
وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن
دُونِ اللهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Wama antum bimuAAjizeena fee al-ardiwala fee assama-i wama lakum mindooni Allahi
min waliyyin wala naseer
Yoruba
Àti pé ẹ̀yin kò níí mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
|
Ayah 29:23 الأية
وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللهِ وَلِقَائِهِ أُولَٰئِكَ يَئِسُوا مِن
رَّحْمَتِي وَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Wallatheena kafaroo bi-ayatiAllahi waliqa-ihi ola-ika ya-isoo min
rahmateewaola-ika lahum AAathabun aleem
Yoruba
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu àti ìpàdé Rẹ̀ (lọ́run), àwọn wọ̀nyẹn ti sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Mi. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún.
|
Ayah 29:24 الأية
فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا اقْتُلُوهُ أَوْ حَرِّقُوهُ
فَأَنجَاهُ اللهُ مِنَ النَّارِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ
يُؤْمِنُونَ
Fama kana jawabaqawmihi illa an qaloo oqtuloohu aw harriqoohufaanjahu Allahu
mina annari inna feethalika laayatin liqawmin yu/minoon
Yoruba
Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n wí pé: "Ẹ pa á tàbí kí ẹ sun ún níná." Allāhu sì gbà á là nínú iná. Dájúdájú àwọn àmì kúkú wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́ ní òdodo.
|
Ayah 29:25 الأية
وَقَالَ إِنَّمَا اتَّخَذْتُم مِّن دُونِ اللهِ أَوْثَانًا مَّوَدَّةَ بَيْنِكُمْ
فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُ بَعْضُكُم
بِبَعْضٍ وَيَلْعَنُ بَعْضُكُم بَعْضًا وَمَأْوَاكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُم مِّن
نَّاصِرِينَ
Waqala innama ittakhathtummin dooni Allahi awthanan mawaddata baynikum fee
alhayatiaddunya thumma yawma alqiyamati yakfurubaAAdukum bibaAAdin wayalAAanu
baAAdukumbaAAdan wama-wakumu annaru wamalakum min nasireen
Yoruba
Ó sì sọ pé: "Ẹ kàn mú àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu, ní ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí (láti jọ́sìn fún) láààrin ara yín nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde apá kan yin yóò tako apá kan. Apá kan yín yó sì ṣẹ́bi lé apá kan. Iná sì ni ibùgbé yín. Kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan fún yín."
|
Ayah 29:26 الأية
فَآمَنَ لَهُ لُوطٌ ۘ وَقَالَ إِنِّي مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ
الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Faamana lahu lootun waqalainnee muhajirun ila rabbee innahu huwa
alAAazeezualhakeem
Yoruba
(Ànábì) Lūt sì gbà á gbọ́. (Ànábì 'Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Dájúdájú èmi yóò fi ìlú yìí sílẹ̀ nítorí ti Olúwa mi. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 29:27 الأية
وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَجَعَلْنَا فِي ذُرِّيَّتِهِ النُّبُوَّةَ
وَالْكِتَابَ وَآتَيْنَاهُ أَجْرَهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ
لَمِنَ الصَّالِحِينَ
Wawahabna lahu ishaqawayaAAqooba wajaAAalna fee thurriyyatihi
annubuwwatawalkitaba waataynahu ajrahu fee addunyawa-innahu fee al-akhirati
lamina assaliheen
Yoruba
A fi 'Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀) ta á lọ́rẹ. A sì ṣe ipò jíjẹ́ Ànábì àti fífúnni ní tírà sínú àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀. A fún un ní ẹ̀san rẹ̀ ní ayé yìí. Dájúdájú ní ọ̀run, ó tún wà nínú àwọn ẹni rere.
|
Ayah 29:28 الأية
وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ إِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الْفَاحِشَةَ مَا سَبَقَكُم
بِهَا مِنْ أَحَدٍ مِّنَ الْعَالَمِينَ
Walootan ith qalaliqawmihi innakum lata/toona alfahishata masabaqakum biha min
ahadin mina alAAalameen
Yoruba
(Rántí Ànábì) Lūt. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin ń ṣe ìbàjẹ́ tí kò sí ẹnì kan nínú ẹ̀dá tí ó ṣe é rí ṣíwájú yín.
|
Ayah 29:29 الأية
أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الرِّجَالَ وَتَقْطَعُونَ السَّبِيلَ وَتَأْتُونَ فِي
نَادِيكُمُ الْمُنكَرَ ۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا ائْتِنَا
بِعَذَابِ اللهِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ
A-innakum lata/toona arrijalawataqtaAAoona assabeela wata/toona fee
nadeekumualmunkara fama kana jawaba qawmihi illaan qaloo i/tina biAAathabi
Allahi inkunta mina assadiqeen
Yoruba
Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa tọ àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) lọ (fún adùn ìbálòpọ̀), ẹ tún ń dánà, ẹ tún ń ṣe ohun burúkú nínú àkójọ yín? Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan àfi kí wọ́n wí pé: "Mú ìyà Allāhu wá fún wa tí o bá wà nínú àwọn olódodo."
|
Ayah 29:30 الأية
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي عَلَى الْقَوْمِ الْمُفْسِدِينَ
Qala rabbi onsurnee AAalaalqawmi almufsideen
Yoruba
Ó sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mí lórí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́."
|
Ayah 29:31 الأية
وَلَمَّا جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا إِنَّا مُهْلِكُو
أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ ۖ إِنَّ أَهْلَهَا كَانُوا ظَالِمِينَ
Walamma jaat rusulunaibraheema bilbushra qaloo innamuhlikoo ahli hathihi
alqaryati inna ahlaha kanoothalimeen
Yoruba
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì mú ìró ìdùnnú dé bá (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, wọ́n sọ pé: "Dájúdájú àwa máa pa àwọn ará ìlú yìí run. Dájúdájú àwọn ará ìlú náà jẹ́ alábòsí."
|
Ayah 29:32 الأية
قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطًا ۚ قَالُوا نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَن فِيهَا ۖ
لَنُنَجِّيَنَّهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ
Qala inna feeha lootanqaloo nahnu aAAlamu biman feehalanunajjiyannahu waahlahu
illa imraatahu kanat minaalghabireen
Yoruba
Ó sọ pé: "Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà níbẹ̀! Wọ́n sọ pé: "Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó wà níbẹ̀. Dájúdájú àwa yóò la òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun."
|
Ayah 29:33 الأية
وَلَمَّا أَن جَاءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِيءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا
وَقَالُوا لَا تَخَفْ وَلَا تَحْزَنْ ۖ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهْلَكَ إِلَّا
امْرَأَتَكَ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ
Walamma an jaat rusulunalootan see-a bihim wadaqa bihim tharAAan waqaloola
takhaf wala tahzan inna munajjookawaahlaka illa imraataka kanat mina alghabireen
Yoruba
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Wọ́n sì sọ fún un pé: "Má bẹ̀rù, má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú a máa la ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ àfi ìyàwó rẹ tí ó máa wà nínú àwọn olùṣẹ́kù-lẹ́yìn sínú ìparun."
|
Ayah 29:34 الأية
إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰ أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ رِجْزًا مِّنَ السَّمَاءِ
بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Inna munziloona AAala ahli hathihialqaryati rijzan mina assama-i bima
kanooyafsuqoon
Yoruba
Dájúdájú a máa sọ ìyà kan kalẹ̀ lé àwọn ará ìlú yìí lórí láti inú sánmọ̀ nítorí pé, wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
|
Ayah 29:35 الأية
وَلَقَد تَّرَكْنَا مِنْهَا آيَةً بَيِّنَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Walaqad tarakna minha ayatanbayyinatan liqawmin yaAAqiloon
Yoruba
Dájúdájú A ti fi àmì kan tó fojú hàn lélẹ̀ nínú rẹ̀ fún ìjọ tó ní làákàyè.
|
Ayah 29:36 الأية
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللهَ
وَارْجُوا الْيَوْمَ الْآخِرَ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ
Wa-ila madyana akhahumshuAAayban faqala ya qawmi oAAbudoo Allahawarjoo alyawma
al-akhira wala taAAthaw feeal-ardi mufsideen
Yoruba
A tún ránṣẹ́ sí ará ìlú Mọdyan. (A rán) arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb (níṣẹ́ sí wọn). Ó sì sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ retí Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀."
|
Ayah 29:37 الأية
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ
Fakaththaboohu faakhathat-humuarrajfatu faasbahoo fee darihim jathimeen
Yoruba
Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni tó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
|
Ayah 29:38 الأية
وَعَادًا وَثَمُودَ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَاكِنِهِمْ ۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ
الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَكَانُوا مُسْتَبْصِرِينَ
WaAAadan wathamooda waqad tabayyanalakum min masakinihim wazayyana lahumu
ashshaytanuaAAmalahum fasaddahum AAani assabeeli wakanoomustabsireen
Yoruba
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) ará ‘Ād àti ará Thamūd. (Ìparun wọn) sì kúkú ti fojú hàn kedere si yín nínú àwọn ibùgbé wọn. Èṣù ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì ṣẹ́rí wọn kúrò nínú ẹ̀sìn (Allāhu). Wọ́n sì jẹ́ olùríran (nípa ọ̀rọ̀ ayé).
|
Ayah 29:39 الأية
وَقَارُونَ وَفِرْعَوْنَ وَهَامَانَ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مُّوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ
فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانُوا سَابِقِينَ
Waqaroona wafirAAawna wahamanawalaqad jaahum moosa bilbayyinati fastakbaroofee
al-ardi wama kanoo sabiqeen
Yoruba
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) Ƙọ̄rūn, Fir‘aon àti Hāmọ̄n. Dájúdájú (Ànábì) Mūsā mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Wọ́n sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Wọn kò sì lè mórí bọ́ nínú ìyà.
|
Ayah 29:40 الأية
فَكُلًّا أَخَذْنَا بِذَنبِهِ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِ حَاصِبًا
وَمِنْهُم مَّنْ أَخَذَتْهُ الصَّيْحَةُ وَمِنْهُم مَّنْ خَسَفْنَا بِهِ الْأَرْضَ
وَمِنْهُم مَّنْ أَغْرَقْنَا ۚ وَمَا كَانَ اللهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن
كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Fakullan akhathna bithanbihifaminhum man arsalna AAalayhi hasiban waminhum
manakhathat-hu assayhatu waminhum mankhasafna bihi al-arda waminhum man
aghraqnawama kana Allahu liyathlimahumwalakin kanoo anfusahum yathlimoon
Yoruba
A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé e mì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
|
Ayah 29:41 الأية
مَثَلُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللهِ أَوْلِيَاءَ كَمَثَلِ الْعَنكَبُوتِ
اتَّخَذَتْ بَيْتًا ۖ وَإِنَّ أَوْهَنَ الْبُيُوتِ لَبَيْتُ الْعَنكَبُوتِ ۖ لَوْ
كَانُوا يَعْلَمُونَ
Mathalu allatheena ittakhathoomin dooni Allahi awliyaa kamathali
alAAankabootiittakhathat baytan wa-inna awhana albuyooti labaytualAAankabooti
law kanoo yaAAlamoon
Yoruba
Àpèjúwe àwọn tó mú àwọn (òrìṣà) ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu, ó dà bí àpèjúwe aláǹtàakùn tí ó kọ́ ilé kan. Dájúdájú ilé tí ó yẹpẹrẹ jùlọ ni ilé aláǹtàakùn, tí wọ́n bá mọ̀.
|
Ayah 29:42 الأية
إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ مِن شَيْءٍ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ
الْحَكِيمُ
Inna Allaha yaAAlamu mayadAAoona min doonihi min shay-in wahuwa alAAazeezu
alhakeem
Yoruba
Dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
|
Ayah 29:43 الأية
وَتِلْكَ الْأَمْثَالُ نَضْرِبُهَا لِلنَّاسِ ۖ وَمَا يَعْقِلُهَا إِلَّا
الْعَالِمُونَ
Watilka al-amthalu nadribuhalinnasi wama yaAAqiluha illaalAAalimoon
Yoruba
Àwọn àkàwé wọ̀nyí, tí À ń fún àwọn ènìyàn, kò sì sí ẹni tí ó máa ṣe làákàyè nípa rẹ̀ àfi àwọn onímọ̀.
|
Ayah 29:44 الأية
خَلَقَ اللهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً
لِّلْمُؤْمِنِينَ
Khalaqa Allahu assamawatiwal-arda bilhaqqi inna fee thalikalaayatan lilmu-mineen
Yoruba
Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
|
Ayah 29:45 الأية
اتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ وَأَقِمِ الصَّلَاةَ ۖ إِنَّ
الصَّلَاةَ تَنْهَىٰ عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنكَرِ ۗ وَلَذِكْرُ اللهِ أَكْبَرُ
ۗ وَاللهُ يَعْلَمُ مَا تَصْنَعُونَ
Otlu ma oohiya ilayka minaalkitabi waaqimi assalata inna assalatatanha AAani
alfahsha-i walmunkariwalathikru Allahi akbaru wallahuyaAAlamu ma tasnaAAoon
Yoruba
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
|
Ayah 29:46 الأية
وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا
الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنزِلَ إِلَيْنَا
وَأُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ
مُسْلِمُونَ
Wala tujadiloo ahla alkitabiilla billatee hiya ahsanu illa allatheenathalamoo
minhum waqooloo amanna billatheeonzila ilayna waonzila ilaykum
wa-ilahunawa-ilahukum wahidun wanahnu lahu muslimoon
Yoruba
Ẹ má ṣe bá àwọn onítírà ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur'ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn tó bá ṣàbòsí nínú wọn. Kí ẹ sì sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un."
|
Ayah 29:47 الأية
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ ۚ فَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ
يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَمِنْ هَٰؤُلَاءِ مَن يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَمَا يَجْحَدُ
بِآيَاتِنَا إِلَّا الْكَافِرُونَ
Wakathalika anzalna ilaykaalkitaba fallatheena ataynahumualkitaba yu/minoona
bihi wamin haola-i manyu/minu bihi wama yajhadu bi-ayatinailla alkafiroon
Yoruba
Báyẹn ni A ṣe sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ. Nítorí náà, àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n gbà á gbọ́. Ó sì wà nínú àwọn wọ̀nyí (ìyẹn, àwọn ará Mọkkah), ẹni tó gbà á gbọ́. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn aláìgbàgbọ́.
|
Ayah 29:48 الأية
وَمَا كُنتَ تَتْلُو مِن قَبْلِهِ مِن كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا
لَّارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ
Wama kunta tatloo min qablihi min kitabinwala takhuttuhu biyameenika ithan
lartabaalmubtiloon
Yoruba
Ìwọ kò ké tírà kan rí ṣíwájú al-Ƙur'ān, ìwọ kò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ kọ n̄ǹkan rí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, kí àwọn òpùrọ́ ṣeyèméjì (sí al-Ƙur'ān).
|
Ayah 29:49 الأية
بَلْ هُوَ آيَاتٌ بَيِّنَاتٌ فِي صُدُورِ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ ۚ وَمَا
يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الظَّالِمُونَ
Bal huwa ayatun bayyinatunfee sudoori allatheena ootoo alAAilma wamayajhadu
bi-ayatina illa aththalimoon
Yoruba
Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó. al-Ƙur'ān), òhun ni àwọn āyah tó yanjú nínú igbá-àyà àwọn tí A fún ní ìmọ̀-ẹ̀sìn. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn alábòsí.
|
Ayah 29:50 الأية
وَقَالُوا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ آيَاتٌ مِّن رَّبِّهِ ۖ قُلْ إِنَّمَا
الْآيَاتُ عِندَ اللهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ
Waqaloo lawla onzila AAalayhi ayatunmin rabbihi qul innama al-ayatu AAinda
Allahiwa-innama ana natheerun mubeen
Yoruba
Wọ́n sì wí pé: "Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?" Sọ pé: "Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi."
|
Ayah 29:51 الأية
أَوَلَمْ يَكْفِهِمْ أَنَّا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ۚ
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَرَحْمَةً وَذِكْرَىٰ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Awa lam yakfihim anna anzalnaAAalayka alkitaba yutla AAalayhim inna fee
thalikalarahmatan wathikra liqawmin yu/minoon
Yoruba
Ṣé kò tó fún wọn (ní àmì ìyanu) pé A sọ tírà (al-Ƙur'ān) kalẹ̀ fún ọ, tí wọ́n ń ké e fún wọn? Dájúdájú ìkẹ́ àti ìrántí wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.
|
Ayah 29:52 الأية
قُلْ كَفَىٰ بِاللهِ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ شَهِيدًا ۖ يَعْلَمُ مَا فِي
السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَالَّذِينَ آمَنُوا بِالْبَاطِلِ وَكَفَرُوا
بِاللهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Qul kafa billahibaynee wabaynakum shaheedan yaAAlamu ma fee assamawatiwal-ardi
wallatheena amanoobilbatili wakafaroo billahi ola-ikahumu alkhasiroon
Yoruba
Sọ pé: "Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó gba irọ́ (òrìṣà) gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
|
Ayah 29:53 الأية
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ ۚ وَلَوْلَا أَجَلٌ مُّسَمًّى لَّجَاءَهُمُ
الْعَذَابُ وَلَيَأْتِيَنَّهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
WayastaAAjiloonaka bilAAathabiwalawla ajalun musamman lajaahumu
alAAathabuwalaya/tiyannahum baghtatan wahum la yashAAuroon
Yoruba
Wọ́n sì ń kán ọ lójú nípa ìyà! Tí kò bá jẹ́ pé ó ti ní gbèdéke àkókò kan ni, ìyà náà ìbá kúkú dé bá wọn. (Ìyà) ìbá dé bá wọn ní òjijì sẹ́, tí wọn kò sì níí fura.
|
Ayah 29:54 الأية
يَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌ بِالْكَافِرِينَ
YastaAAjiloonaka bilAAathabiwa-inna jahannama lamuheetatun bilkafireen
Yoruba
Wọ́n ń kán ọ lójú nípa ìyà! Dájúdájú iná Jahanamọ kúkú máa yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
|
Ayah 29:55 الأية
يَوْمَ يَغْشَاهُمُ الْعَذَابُ مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِمْ وَيَقُولُ
ذُوقُوا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ
Yawma yaghshahumu alAAathabumin fawqihim wamin tahti arjulihim wayaqoolu
thooqooma kuntum taAAmaloon
Yoruba
(Rántí) ọjọ́ tí ìyà yóò bò wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn àti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, (Allāhu) sì máa sọ pé: "Ẹ tọ́ (ìyà) ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò."
|
Ayah 29:56 الأية
يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ أَرْضِي وَاسِعَةٌ فَإِيَّايَ فَاعْبُدُونِ
Ya AAibadiya allatheenaamanoo inna ardee wasiAAatun fa-iyyayafaAAbudoon
Yoruba
Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò. Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún.
|
Ayah 29:57 الأية
كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا تُرْجَعُونَ
Kullu nafsin tha-iqatu almawti thummailayna turjaAAoon
Yoruba
Gbogbo ẹ̀mí l'ó máa tọ́ ikú wò. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni wọn yóò da yín padà sí.
|
Ayah 29:58 الأية
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ الْجَنَّةِ
غُرَفًا تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ نِعْمَ أَجْرُ
الْعَامِلِينَ
Wallatheena amanoowaAAamiloo assalihati lanubawwi-annahummina aljannati ghurafan
tajree min tahtiha al-anharukhalideena feeha niAAma ajru alAAamileen
Yoruba
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọn sínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gígá kan nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere sì dára.
|
Ayah 29:59 الأية
الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ
Allatheena sabaroo waAAalarabbihim yatawakkaloon
Yoruba
(Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
|
Ayah 29:60 الأية
وَكَأَيِّن مِّن دَابَّةٍ لَّا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللهُ يَرْزُقُهَا
وَإِيَّاكُمْ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ
Wakaayyin min dabbatin la tahmilurizqaha Allahu yarzuquha wa-iyyakumwahuwa
assameeAAu alAAaleem
Yoruba
Mélòó mélòó nínú àwọn ẹranko tí kò lè dá bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀ gbé, tí Allāhu sì ń ṣe ìjẹ-ìmu fún àwọn àti ẹ̀yin. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
|
Ayah 29:61 الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ
وَالْقَمَرَ لَيَقُولُنَّ اللهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ
Wala-in saaltahum man khalaqa assamawatiwal-arda wasakhkhara ashshamsa
walqamaralayaqoolunna Allahu faanna yu/fakoon
Yoruba
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
|
Ayah 29:62 الأية
اللهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ ۚ إِنَّ
اللهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu yabsutu arrizqaliman yashao min AAibadihi wayaqdiru lahu inna
Allahabikulli shay-in AAaleem
Yoruba
Allāhu l'Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
|
Ayah 29:63 الأية
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ
مِن بَعْدِ مَوْتِهَا لَيَقُولُنَّ اللهُ ۚ قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ
أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ
Wala-in saaltahum man nazzala mina assama-imaan faahya bihi al-arda min
baAAdimawtiha layaqoolunna Allahu quli alhamdulillahi bal aktharuhum la
yaAAqiloon
Yoruba
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Allāhu ni." Sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè."
|
Ayah 29:64 الأية
وَمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا لَهْوٌ وَلَعِبٌ ۚ وَإِنَّ الدَّارَ
الْآخِرَةَ لَهِيَ الْحَيَوَانُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ
Wama hathihi alhayatuaddunya illa lahwun walaAAibun wa-inna addaraal-akhirata
lahiya alhayawanu law kanooyaAAlamoon
Yoruba
Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀.
|
Ayah 29:65 الأية
فَإِذَا رَكِبُوا فِي الْفُلْكِ دَعَوُا اللهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ
فَلَمَّا نَجَّاهُمْ إِلَى الْبَرِّ إِذَا هُمْ يُشْرِكُونَ
Fa-itha rakiboo fee alfulki daAAawooAllaha mukhliseena lahu addeena
falammanajjahum ila albarri itha hum yushrikoon
Yoruba
Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un. Àmọ́ nígbà tí Ó bá gbà wọ́n là sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ
|
Ayah 29:66 الأية
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ وَلِيَتَمَتَّعُوا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Liyakfuroo bima ataynahumwaliyatamattaAAoo fasawfa yaAAlamoon
Yoruba
Nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
|
Ayah 29:67 الأية
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا جَعَلْنَا حَرَمًا آمِنًا وَيُتَخَطَّفُ النَّاسُ مِنْ
حَوْلِهِمْ ۚ أَفَبِالْبَاطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَةِ اللهِ يَكْفُرُونَ
Awa lam yaraw anna jaAAalna haramanaminan wayutakhattafu annasu min
hawlihimafabilbatili yu/minoona wabiniAAmati Allahiyakfuroon
Yoruba
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ (òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu?
|
Ayah 29:68 الأية
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِالْحَقِّ
لَمَّا جَاءَهُ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَافِرِينَ
Waman athlamu mimmani iftaraAAala Allahi kathiban aw kaththaba bilhaqqilamma
jaahu alaysa fee jahannama mathwan lilkafireen
Yoruba
Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí tó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
|
Ayah 29:69 الأية
وَالَّذِينَ جَاهَدُوا فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا ۚ وَإِنَّ اللهَ
لَمَعَ الْمُحْسِنِينَ
Wallatheena jahadoofeena lanahdiyannahum subulana wa-inna AllahalamaAAa
almuhsineen
Yoruba
Àwọn tó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere.
|
©
EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us
|