Gbagede Yoruba
 



Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo Lati Owo Akoroyin Olootu

Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku

Ogbeni Oladiran ti pade iku ojiji lasiko to n pari ija to waye laarin omo re, Olajoke Oladiran pelu Stanley Okere to je araadugbo won.

Nigba tomo baba naa n ba akoroyin wa soro leka to n topinpin esun ipaniyan nileese olopaa to wa ni Panti nipa iku baba e, Joke to je eni odun metadinlogbon so pe, ''Idi omi taapu to wa laduugbo wa ni Adisatu, l'Orile-Iganmu, ni mo lo laaaro ojo Isegun, Tusde, ojo kin-inni, osu keta, yii, lati loo ba aburo mi gbe omi wale. Bi mo se debe, mo ba awon omobinrin meji kan ati omo kekere kan pelu aburo mi nibe, lobinrin to n ta omi ba so fun awa ta a duro pe ka pon omi wa, ka ma duro de awon ti garawa omi won wa saaju tiwa lori ila.'' Leyin tawon omobinrin mejeeji pon omi won tan ti Joke ni koun gbe garawa omi ti aburo re gbe sori ila ni omo kekere kan to ni ko ju omo odun mejila lo so pe ko ma gbero lati se bee nitori boun se wa yii, oun lagidi gan-an, bee lomo naa beere pe se ko ya were?

Oro tomo naa so si Joke lo se so fun un pe boun ba ki i mole toun n na an, awon eeyan a so pe oun ri i lomode loun se n fiya je e. Oro yii ni Joke atomo ohun n fa lowo ti egbon re, Stanley Okere fi sunmo won lati da si i, to si gba Joke leti lori oro ti ko to nnkan

Aburo Joke la gbo pe o loo fi ohun to sele to baba won leti tiyen fi sare debe lati beere ohun to faja gan-an lowo omo e. Joke salaye oro fun baba e, leyin eyi ni baba naa sunmo Stanley toun atomo re jo n ja lati bi i leere idi oro naa, niyen ba so fun baba pe ko loo bi omo re.

Bi baba naa se waa gbese to n dun un le okuta to fi di pe eje n da lara re ni ko gba ibi kan ye enikeni titi di bi a ti n ko iroyin ohun jo. Ileewosan keji ti won gbe Ogbeni Oladiran de ni won ti taari re lo sosibitu Jenera, won ni ko si eje kankan nile tawon le fa sara oloogbe naa to ti padanu eje pupo laarin asiko ohun.

Ki itoju baba won le ya lawon omo oloogbe yii se gbe e lo sileewosan nla kan ti ko fi bee jinna saduugbo won, nibi ti baba yii pada ku si.

Iwe afihan awon olopaa tawon oloyinbo n pe ni 'police report' la gbo pe Joke atawon ebi baba re kan fee loo gba ni tesan olopaa kan to wa lagbegbe won ti won fi ba Stanley atawon eeyan e kan ti won mu esun wa sibe pade. Leyin to han sawon agbofinro pe awon meteeta ni won lowo sija ohun ni won mu won sile, ki won too waa taari won wa sileese olopaa to wa ni Panti, nibi tawon afurasi naa ti n ran awon olopaa lowo lori ohun to fa sababi iku baba naa.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 19:47:49 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo:
Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo



"Ija Ni Baba Joke La L'Orile-Iganmu, Lo Ba Gbabe Ku" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com