Gbagede Yoruba
 



O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo
 
Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo Lati Owo Florence Babasola,Osogbo

O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo

Pelu iyanu lawon eeyan agbegbe Odeyemi, ni Kolawole, niluu Osogbo, n wo lose to koja nigba ti omokunrin kan deede dake lori opo ina to ti n so waya papo, sugbon nigba to di pe ko mira mo ni won figbe ta.

Redio la gbo pe Ismaheel Dauda n tun se lagbegbe naa, sugbon igbakigba ti ina ijoba ba ti yonu lori opo ni won maa n ranse si i ni soobu re to si maa n ba won se e.

Bii eni pe ara ti n ro ajalu fun un lojo naa ni nitori nigba ti ore re kan koko loo pe e pe ko waa ba won so ina awon IBEDC, a gbo pe se ni Dauda koko yari pe oun ko se. Sugbon nigba ti ebe po, o gba lati ba won se e, bee la gbo pe o loo wa akaba onirin kan to fi gun opo ina ohun.

Ko ti i ju iseju marun-un to gun un ti ina fi gbe e, sugbon awon ti won wa layika ibe ko tete mo, se ni won kan n fokan si i pe Dauda n sise lo lara opo ina ni.

Awon kan ti won n muti lagbegbe ohun ti won n wo nnkan to n sele loookan la gbo pe won sakiyesi pe okunrin naa ko mira lori opo ina to wa, bayii ni won sunmo ibe, ti won si ri i pe ina ti gbe e. Gbogbo won bere si i mi opo ina naa titi ti Dauda fi jabo lu garawa kan to wa legbee opo naa ko too jabo sileele.

Nigba to n fi aidunnu re han si isele buruku ohun, agbenuso ileese apinna IBEDC, Kike Owoeye, ni o se ni laaanu pe pelu gbogbo ariwo ati ikilo ti ajo naa n pa pe ki enikeni ti ko ba mo nipa ina ma se maa sunmo opo ina, sibe awon eeyan kan si n femi ara won wewu.

O waa ro awon eeyan ipinle Osun lati jawo ninu fifi owo kan dukia ajo IBEDC.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:12:35 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo:
Agbonrin abami ran pasito lo sorun apapandodo l'Okeigbo


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Ijamba Isele Aburu Agbako Ati Ifemi Sofo



"O Ma Se O! Dauda To n Tun Redio Se Gan Mona L'Osogbo" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com