Gbagede Yoruba
 



Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore
 
Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo Lati Owo Akoroyin Olootu

Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore

Oro beyin yo nile-ejo giga kan to fikale siluu Ore, nijoba ibile Odigbo, nipinle Ondo, l'Ojoru, Wesde, ose to koja yii, pelu bi kootu ohun se pase pe ki Ogbeni Omojeje Ajisola Victor sanwo to to egberun lona eedegbeta naira (N500,000) fun iyawo re to fee ko sile, bee lo ni odo iyawo, Folasade Omojeje, ni kawon omo mejeeji tigbeyawo naa so leso maa gbe.

Omojeje to je oko-iyawo la gbo pe o mu esun iyawo re lo sile-ejo giga pe ki won tu igbeyawo odun merinla to wa laarin awon ka, kile-ejo naa si pase fun iyawo lati yonda awon omo mejeeji to bi fun un lati maa toju won, sugbon iyalenu loro ohun je fawon ero kootu pe okunrin to pejo naa lo pada jebi bo.

Lara awon esun ti Omojeje fi kan iyawo re nile-ejo ni fifi eto eni dun ni, pipa oun ti fun ojo pipe ati aisi ife mo laarin awon.

Kootu ijoba apapo kan to wa lagbegbe Ikoyi, niluu Eko, la gbo pe o so awon mejeeji po gege bii toko-taya ni ogbonjo, osu kejila, odun 2002, leyii to mu ki igbeyawo ohun ku die ko pe odun merinla gbako lodun ta a wa yii.

Lati nnkan bii odun meje seyin la gbo pe iyawo ohun ti n da gbe pelu awon omo mejeeji to bi foko re. Obinrin naa lo n da gbo bukaata awon omo titi kan owo ileewe won. Gbogbo awon risiiti owo tabileko ohun na lori itoju awon omo e lo ko wa siwaju adajo gege bii eri lati gbe oro re lese.

Nigba to n gbe idajo re kale, Onidaajo Olorundahunsi fidi e mule pe gbogbo awon atotonu to ti n waye lateyinwa latenu agbejoro olupejo ati olujejo fi han pe ko sohun meji ti toko- taya yii n fe ju kile-ejo tu won ka lo. O ni eyi fi han pe ko si ife mo laarin won pelu bi won se n gbe lotooto lati nnkan bii odun meje seyin bayii.

Ohun tadajo ohun so pe o se koko ju nigbakigba tile-ejo ba fee tu igbeyawo ka ni igbe-aye irorun awon omo to ba ti iru igbeyawo bee jade. O waa pa a lase pe kawon omo mejeeji, Omojeje Folusayo ati Folusewa maa gbe lodo iya won pelu pe baba won letoo lati maa be won wo nigbakigba to ba wu u.

Bee lo so fun Omojeje pe o gbodo maa san egberun meeedogbon naira (N25,000) losoosu fun iyaale ile yii gege bii owo itoju awon omo, ko tun maa san ida meje lara owo ileewe awon omo naa latigba naa lo.

Lakootan, Olorundahunsi ni ki okunrin naa san egberun lona eedegbeta naira (N500,000) fobinrin yii gege bii ara owo to ti fi n da toju awon omo mejeeji latigba to ti n da gbe.

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, February 26 @ 20:18:29 PST Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo:
Yoruba Greetings, (Middle) Names In Yoruba Language With Titles Of Obas (Kings)


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Atoka Feyikogbon - Ninu Oye Esin Ati Imo



"Igbeyawo Odun Merinla Fori Sanpon L'Ore" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com