Gbagede Yoruba
 



Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran
 
Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran

Gbogbo eto la gbo pe o ti to bayii fun egbe alaabo So Safe Corps nipinle Ogun, eyi ti Ogbeni Olusoji Ganzallo je Komanda won lati wo iya ija peluu awon odaran kaakiri ipinle naa, paapaa bi won tun she towo bowe adehun peluu awon ileeshe eleto aabo yooku kaakiri.

Fawon to ba mo bi nnkan she n lo, won a mo daju pe bi awon asiko ayeye gbogboogbo bayii ba ti n waye lawon odaran bii omo egbe okunkun, adigunjale maa n gbero lati shoshe won, eyi ti won loo le da alaafia ilu laamu.

Eyi gan an la gbo pe o mu egbe alaabo So Safe Corps pinu lati shishe papo peluu awon ileeshe eleto aabo yooku kaakiri ipinle Ogun, ki eto aabo le tubo kesejare lasiko ati leyin odun Ileya.

Gege bi agbenuso fun egbe naa, Ogbeni Moruf Yusuf she shalaye fun wa, o so pe bo tile je pe awon ko sheshe maa towo bowe adehun pelu awon ileeshe eleto aabo, sugbon, eyi tawon tuntun sheshe she yii yato patapata sawon eyi tawon ti n she tele, nitori pe ishe won ti yato si tigba tawon shi n je Fijilante.

Moruf so pe gbogbo awon ahere kaakiri awon adugbo lawon ti sheto awon omo egbe won si lati maa sho enikeni to ba fee wo ipinle Ogun wa a shishe ibi, lati le tete koju won, ati pe awon ko ni i gba iwa odaran kankan laaye lasiko ati leyin odun Ileya, tori pe ojushe won ni lati daabo bo awon araalu.

O wa fokan awon araalu bale pe ki won ma she foya tabi beru, nitori pe awon ti wa ni igbaradi lati daabo bo emi ati dukia won, ati pe asiko naa re e ti won le sun, ki won hon oorun.

Bee lo ro awon araalu pe ki won ma she pa enu won mo lati tete fi awon odaran ti won ba kefiri lagbegbe won to won leti, eyi to so pe o le tubo mu ishe rorun fun won.

Bakan naa lo tun so pe awon ti sheto awon nomba ero ibanisoro meji otooto tawon araale le maa fi ishele to ba n lo to won leti. Awon nomba naa ni: 09069392064 ati 08035479930.

E RiN JiNNa SIPINLE OGUN LaSiKo aTI LẸ́YiN ILeYa - Ọ̀Ga FIJILANTe PaROWa FaWON Ọ̀DARaN

Beeyan ba ri atejade ikilo ti oga agba Fijilante nipinle Ogun, Komanda Nureni Olanrewaju Adedoyin fi sita laipe yi, yoo mo pe okunrin naa ko gba igbakugba fun iwa odaran rara, paapaa bo tun she so pe awon ti da awon omo egbe naa ti ko din ni egberun marun un sita kaakiri ipinle Ogun lasiko ayeye odun Ileya to n bo lona yi.

Komanda Adedoyin so pe nitori pe aabo emi ati dukia awon araalu lo je won logun, eyi lo fa a, tawon fi gbodo maa wa nimurasile lati she ojushe awon ni gbogbo igba, paapaa lasiko ti odun ba ti n sunmo etile, eyi tawon adaran maa n fe ri gege bi afaani lati shoshe.

O fi ye wa ninu atejade naa pe kawon odaran ti won ba lero pe awon le ja baagi gba, tabi yo foonu lapo awon araalu, tabi lo gbajue tete ba ara won soro lati rin jinna sipinle Ogun nitori pe gbogbo eto lo ti to.

Oga agba naa to mo daadaa nipa eto aabo, eni to tun ti gba orishirishi aami eye ati iwe eri lori aabo naa tun je ko di mimo pe, asiko elege ti aabo ni orileede Naijiria, paapaa ile Yoruba wa bayii, idi ni yi to fi je pe awon ko gbodo foju kan oorun losan ati loru, to si je pe awon ero igbalode to n tu ashiri odaran lo ti wa nile ni sepe lati dekun awon iwa odaran lawujo.

Nibe lo tun ti je ko ye wa pe ileeshe awon ko tii pinu lati fa seyin nipa fifowosowopo peluu awon ileeshe eleto aabo yoo ku bii Olopaa, Sifu Difensi atawon eso oju popona kaakiri, nitori pe awon ti forikori lati je alaafia joba lawujo.

Bee lo tun fidi e mule pe kawon ti won lero wipe awon le ayeye awon olodun ru mo pe ko ni i si aaye kankan fun won, nitori pe digbi lawon ti mura sile, to si tun fi ye wa pe opo awon omo egbe won tawon ko sita ni won ko ni wo asho idanimo.

Nigba to ń parowa naa, o so pe ọdaran ti owo ba te yoo fi enu re fe ara bi abebe, koda a, to tun so pe awon ti won ba n ri, lẹ́yin to ba jaja bo yoo ba a kaaanu, to si ni o shee she ki won fi ẹ̀wọ̀n gbara labẹ́ ofin. 

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Sunday, September 01 @ 02:56:25 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose:
Iru Pasito Radarada Wo Waa Ni Oluso-Aguntan Oyelami Yii Gbogbo Awon Omobinrin Ij


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Asakasa Ati Sise Eru Awon Oyinbo Nikose



"Ayeye Odun ileya: Egbe So Safe Corps Fee Wo Iya-Ija Pelu Awon Odaran" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com