Gbagede Yoruba
 



Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure
 
Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu Olusheye Iyiade, Akure

Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure

Ileese olopaa ipinle Ondo ni awon ti n wa gbogbo ona lati fi panpe oba gbe toko–taya kan ti won fesun kan pe won lu Testimony Tooke Babalola, omo bibi inu ara won pa l'Akure, l'Ojoruu, Wesidee, ose to koja.

Femi Joseph to je alukoro ileese ohun so lojo Aiku, Sannde, to koja yii pegbogbo igbese to ye lawon n gbe lowo lati ri i daju pe owo te Ogbeni Felix Babalola ati iyawo re laipe rara, ki won le waa so tenu won lori oro iku omobinrin eni odun merin ohun.

O ni opo igba lawon ti de ile ti won n gbe l'Akure, sugbon ti awon ko ba won, sugbon o ni awon ko ni i sinmi titi ti won yoo fi ri awon afurasi mejeeji ohun mu.

Abileko Babalola to je iya omodebinrin ohun ni won lo gbe e digbadigba lo sile-iwosan ijoba to wa l'Akure ni irole Ojoruu, Wesidee, ose to koja, kawon dokita to ba lenu ishe l'ojo naa too fidi re mule pe omo to gbe wa ti ku.

Orishiirishii apa ti won ri lara oloogbe ohun lasiko to fi wa nileewosan lo mu kawon oshishe ibe fura pe iku re ko le je oju lasan.

Obinrin yii ni won ri to gbe oku omo re pon, to si sare jade nileewosan. Ko seni to mo irin obinrin ohun mo titi di ojo keji, ti Eni-Owo Mathew Ologun to je pasito ijo Katoliiki Mary Queen of Angels, to wa l'Akure, nibi to ti n josin, too tu ashiri oun ati oko re.

Alufaa ohun ni bo tile je pe ojo pe ti toko–taya naa ti n fiya je omo yii, ojo keji,oshu kefa, odun ta a wa yii lo ni oun sheshe n gbo nipa re.

Ninu iwadii to she lo ni oun ti fidi re mule pe opolopo oju ogbe ati àpá to wa lara Testimony Babalola ko sheyin baba re, Felix Babalola, atawon ara ijo Kerubu, C & S, to ti n josin tele, latari itusile ti won ni awon n she fomo naa nitori emi okunkun ti won lo n gbe inu re.

O ni omodebinrin yii ko ti i ju bii omo oshu mesan-an pere lo nigba to ti n gbe lodo iya baba re ni Ikare Akoko, laipe yii lo ni okunrin naa loo binu mu un kuro lori esun pe iya oun ko ba oun ko o lawon eko ile to ye.

Iya Tesitimony so pe opo egbo to wa lara omo re waye latari lilu lalubami nigba gbogbo lati owo baba re lori esun pe ki i kunle ki oun.

A gbo pe Babalola funra re jewo fun awon eeyan kan to sun mo ko too sa kuro l'Akure pe asotele ti won so foun ninu ijo Kerubu ti oun n lo lo shokunfa awon lilu atawon ogbe to wa lara re.

Gege bi iroyin ta a gbo lati Ikare Akoko, nibi ti toko–taya ohun sa lo, aaro Ojo Abameta, Satide, ose naa lawon olopaa topase won lo sibi ti won sapamo si, ti won si gbiyanju ati mu won lo si teshan won.

Eyi ni won n she lowo tawon oloye adugbo kan atawon odo die fi jade si won,ti won si ko jale pe awon agbofinro ko ni i mu won lo.

Leyin opolopo awuyewuye ni won ni meji ninu awon ijoye ohun be awon olopaa to waa mu won pe ki won shi maa lo na, won si sheleri lati funra won fa toko–taya naa le won lowo l'Akure, lowo lojo Aje, Monde, ose ta a wa yii

 Posted By Ifiranse Eleyi Je Thursday, September 12 @ 06:55:58 PDT Lati Owo MediaYorubaTeam



Comments 💬 التعليقات
 

For Your Membership Comments And Registered Debates Please, See Below Or Register Here :-: للحصول على تعليقات عضويتك و مناقشات الأعضاء انظر من فضلك أدناه أو سجّل هنا

Awọn ọna asopọ ti o jọmọ

· Die sii Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu
· Iroyin Nipasẹ MediaYorubaTeam


Ọpọlọpọ Itan Ka Nipa Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu:
Nitori Oro Ti Ko To Nnkan - Lamidi Fogo Mo Ore E Lori, Lo Ba Ku Patapta: Won Ti


Iwọn Abala

Apapọ Dimegilio: 0
Awon Ibo Ni Oniyi: 0

Jọ̀wọ́ Gba Ẹ̀ẹ̀kejI ki o sI dIbo fun Abala YIi:

O tayọ
O dara pupọ
O dara
Deede
Buburu


Aṣayan


 Ọrẹ-itẹwe Ọrẹ-itẹwe





Akole Atoka Agbo-Oro

Irukerudo Ati Awon Iwa Janduku Nilu



"Awon Olopaa Fee Mu Baba Atiya Ti Won Lu Omo Won Pa L'Akure" | Buwolu wọle/Ṣẹda Eto Akọsilẹ | 0 Awon Alaiye


Awọn asọye jẹ Ohun ini nipasẹ Iwe ifiweranṣẹ. A Ko Lodidi Fun Akoonu wọn. Nibayi, A Pe Awọn oluka lati jabo Eyikeyi Abusive, Unsuitable And/tabi Islamophobic Content



Ko si awọn ọrọIwoye Ti o gba laaye Fun Aisinisi, Jọwọ Forukọsilẹ
 

Gbagede Yoruba
Akọọlẹ Tirẹ
Ojule Akọkọ  | Awọn Itan Yoruba  | Gbagede Yoruba  | Ifiranṣẹ Ara-ẹni  | Ọmọ-Ẹgbẹ Yoruba  | Koko Mẹwa  | Ẹka Abule  | Ifirohin-Ransẹ  | Iwadi  | Agbeyẹwo  | Ifimufilẹ  | Iwe Akọọlẹ  | Apoti Akọsilẹ  | Isopọ Ọpọnlujara  | Ẹgba Ayelujara  | Ipolongo Wa


Ẹsin Islam الدين الإسلامي Religion of Islam Addinin Musulunci Agama Islam Religión del Islam 伊斯兰教 Dini ya Kiislamu Религия Ислам Religião do Islã イスラム教 Esin Islam 이슬람의 종교 Portal African Muslim Website - Arabic English African Islamic Website For World News, Fatwas, Audios, Videos, Muslim News, Articles, Radio, Audio, Video, Quran, Hadith, TV Channels, Fatwas, Muslim News, Newspapers, Magazines Headlines, Forums, College, Schools, Universities, Mosques, Quranic, Sunnah, Fiqh, Prayers, Salat, Ramadan, Vidoes, Books, Fasting, PDFs On EsinIslam.Com And IslamAfrica.Com