Topic: Abi Ki Lo N s’Oba Alowa Yii, O Si Tun n Daran Moran: Kayode Wo Aso Soja Daran n’Ilorin, O Ti Dero Kootu Bayii
Timeline: 2012-05-13 04:27:19
Latio Owo Idris Alooma, Ilorin
Abi Ki Lo N s’Oba Alowa Yii, O Si Tun n Daran Moran: Kayode Wo Aso Soja Daran n’Ilorin, O Ti Dero Kootu Bayii
Se e ti gbo ohun ti won ni Alowa Ilowa, Oba Ali tun se. Oto leyi ti a n gbo tele, nise ni won so pe Oba naa ko le rin, ko le su, ko le to, iyen ni won se so pe ko se le wa sile-ejo lati waa je ejo fifi-ipa-bani-sun ti won n ba a se, lori pe o ba omolomo kan to waa se ise sin ilu baba re n’Ilowa sun pelu tipa, toro naa si dariwo.
Ejo naa l’Oba yii wa lenu e latojo yii, to si je lopo igba ni won yoo so pe ara Oba naa ko ya, kinni kan n se e, ko le jeun, ko le mumi, tawon eeyan kan si n so pe Kabiyesi naa n dibon ni.
A¯ra¯ mi-in lo waa gbe jade lose to koja yii o. Oloun lo mo bo se se e, Oloun lo si moye owo to na to fi di pe o ri awon omoleewe atawon araalu kan ko jo, tawon yen fise gidi ti won n se sile, ti won n lo si kootu loo da soro ti won ko mo nipa e.
Won kora won jo, won n so pe ki won fi Alowa sile, won ko soro pe Alowa fi tipatipa ba omo olomo sun o, won ko soro pe ija buruku loun tomo naa ja ko too da a mole, to si ki ara re si i labe, won ko so iru ohun tawon naa le se feni to ba fi tipatipa ba omo tiwon sun o, won fise won sile, won n rin irin ranu kiri.
Ko si sohun to fa a, awon kan ni won yoo ti seto owo fun won o, ki i se pe won feran Alowa to bee yen naa, owo lo fa sababi oro naa. Ni bayii, ijoba Osun ti so pe awon yoo pe Oba naa lejo mi-in nitori won mo pe etan lo fi ko awon omo olomo jade, ki i se pe awon yen fee lo sile-ejo loo maa pariwo lori oro ti won ko si nibe nigba to sele. Bijoba ba waa tun gbe Alowa lo si kootu mi-in, ona wo ni yoo waa gba ti yoo fi bo nibe. Abi iru Kabiyesi wo ree o, ki odidi Oba si maa daran moran.
Kayode wo aso soja daran n’Ilorin, o ti dero kootu bayii
Omokunrin eni odun mejilelogun kan, Ogbeni Kayode Bello, ti wo aso soja daran n’Ilorin, esun ti won fi kan an ni pe ki i see soja, o si n wo aso won . Won ni ko salaye idi to fi n woso ohun bi ki i baa se pe o fee maa fi huwa odaran, eyi lo mu ki won wo o lo si kootu.
Iwe Iroyin Yoruba gbo pe won ba aso awon soja lorun e loooto. Bee ni won tun ba awon ohun eelo mi-in to je ti soja bii kaadi idanimo atawon eroja mi-in to je tileewe awon soja to wa niluu Kaduna lowo e. Iwa to hu naa la gbo pe o ta ko ofin ise soja lorileede Naijiria.
Oga soja kan, Ogbeni S. Samuel, to wa ni baraaki Sobi, n’Ilorin, lo mu un sugbon ko le salaye ara e daadaa lori ibi to ti ri awon ohun ti won ba lowo e. Nibe lasiiri e ti tu pe ki i se soja.
Ohun ti a gbo pe o sele ni pe o ti figba kan je omoleewe awon Soja, iyen NDA, to wa niluu Kaduna, sugbon won ti le e danu fun idi pataki kan, pelu e naa, nise lo si n kaakiri igboro to n se bii soja, to si tun n lo kaadi idanimo won pelu. Bo tile je pe odaran naa bebe fun idariji, sibe olopaa to n soju ijoba ni Kootu Majisreeti to wa n’Ilorin, Ogbeni Ernest Eniolorunda, so pe ko ye ki won gba beeli e rara, nitori esun ti won fi kan an ti po nigboro, won si nilo lati fopin si i.
Adajo kootu naa, Tunde Kuranga pase pe ki won fi i sile latimole olopaa, nitori bi odaran naa se bebe pe oun ko ni i sa lo, ati pe oun setan lati tele awon ilana ti kootu ba la kale lori oro naa.
Eyi ni Adajo se pase pe ki won faaye beeli e sile pelu owo to to egberun mewaa naira. O waa sun igbejo si Ojobo, Tosde to n bo.
**{Legacy activities, comments etc counter: 896; topic series: 6; forum: MediaYoruba; associated: 6- /*}