Topic: Abiru Alagbere Obinrin Wo l’Ajile Yii: O bimo, O Si Gbe E Fun Okunrin Meji
Timeline: 2012-05-13 04:34:58
Lati Owo Johnson Akinpelu, Abeokuta
Abiru Alagbere Obinrin Wo l’Ajile Yii: O bimo, O Si Gbe E Fun Okunrin Meji
Ohun tawon eeyan ko mo ni pe opo awon fiimu tawon onitiata maa n se lo je pe awon nnkan to n sele loju aye ni won fi n ko awon ololufe won logbon, ki i se pe won kan n sere lasan. Kayeefi kan lo sele laipe yii, opo awon to gboro naa lo si n ya lenu titi di akoko yii.
Abileko, eni odun marundinlogoji kan toruko e n je Ajile Afolabi lo se nnkan ara naa, o si mu itiju bawon obinrin, ti won fi n so o laarin ara won pe obinrin naa ki i seeyan gidi, ko si ye ko maa gbe lawujo awon eeyan.
Ile oko lobinrin naa wa lati nnkan bii odun merindinlogun seyin, o si ti bi omo merin fun oko e to n je Tajudeen Afolabi, tiyen n sise mekaniiki. Adugbo kan ti won pe ni Opara Estate, Rounder, lona Ayetoro, lawon mejeeji n gbe, oko e yii gan-an lo ko ile ohun.
Lojo karun-un, osu kin-in-ni, odun yii ni obinrin yii tun bi omo tuntun nireti pe oko e ti won jo n sun, ti won jo n ji yii lo bi i fun, tiyen si se ikomo omo ohun. Ase omo ti Tajudeen n ko jade to ro pe oun ni Ajile bi i fun ki i se tie rara, omo ale ni.
Lose to koja ni asiri oro naa han sita gbangba nigba tokunrin kan ti won n pe ni Ayelabowo to je ale Ajile padanu emi e nibi ijamba moto lona Igboora. Lakooko ti won n se adura ni won so pe Ajile yoju, to si jokoo sibi tawon opo okunrin naa jokoo si. Bii aala loro naa ri loju awon to mo on, ti won si mo oko e, ibeere ti won n beere lowo ara won ni pe igba wo lobinrin yii di aya Ayelabowo ti won lo n sise dereba lojiji. Awon ti won ko le gba a mora kuku loo ba a, won si beere lowo e, sugbon si iyalenu won, o ni Ayelabowo loun bi omo toun n to lowo naa fun.
Ibi yii gan-an ni iwadii Iwe Iroyin Yoruba ti bere lati mo idi to fi bimo kan soso fun baba meji.
Nigba to n ba oniroyin wa soro, Ogbeni Tajudeen Afolabi so pe nnkan bii odun merindinlogun seyin lawon ti fera awon, to si ti bimo merin foun.
Sugbon were ni iwa e yipada, eyi to fa edeaiyede to fi ko jade kuro nile oun. O so pe, Ko pe si akoko naa lo tun pada wa, o ti fee to osu merin ko too so pe oun loyun yii. Ara ti koko fu mi nitori emi naa mo pe irin ese e ko mo rara, ti mo si so o dija.
Okunrin yii ni nibi toro naa le de nigba naa, Imaamu mosalaasi awon lo yanju e, tiyen si so pe ko le gbe oyun ale wale rara. Bee lo ni lojo to fee bimo, awon jo sun ni, aarin oru lomomuun, oun si gbe e lo si osibitu Iya Abiye to wa ni Adedotun, ibe lawon jo sun moju, bo si se bimo tan ni won gbe ibi omo foun toun si loo ri i mole. Tajudeen ni leyin tawon sekomo tan, to pe ogoji ojo lobinrin naa ko ti gbele mo, to si n paro pe soobu tuntun toun fee gba loun n yanju.Oni nigba ti ara oun ko gba a mo loun da a si wahala, se lo si fibinu fo telifisan mole ninu ile, to si tun gbabe sa lo.
O ni gbogbo agbara loun sa lati ri i, debii pe oun mu foto e lo sodo awon olopaa, bee ni won tun ba oun kede e lori redio pe awon n wa a, ase ile okunrin lo sa lo to n gbe. O ni leyin osu kan ni Ajile tun pada wa sile, loju ese loun ti pe awon olopaa pe ki won waamuun.
Bo se de tesan olopaa to wa ni Lafenwa lo bere si i dibon, to n se bii eni ti giri mu, nigba tagbara awon olopaa ko ka a ni won so pe ki won gbe e lo si osibitu, bo se de ohun lawon dokita ti so pe ko si nnkan to n se e, ko maa lo sile.
Oko iyawo ni koun too ji laaaro ojo naa, Iya Suliya, gege bi won se n pe e tun ti sa lo, ti awon ko si ri i titi di akoko ti ale e, Ayelabowo fi ku ti won fi ri i nibe, nibe lo ti so pe eni to ku naa lo lomo toun gbe dani, eyi to je iyanu fawon to wa nibe. Obinrin to tun ba
Iwe Iroyin Yoruba soro toruko e n je Monsura Afolabi to je egbon Tajudeen so pe ko seni ti ko mo peeyan jeeje ni Tajudeen, ki i ja, bee ni ko loree, nitori e lo se fee yo ile aye lemi e. O so pe Ajile ti fa aso oun ya ri lori irinkunrin to n rin yii, gbogbo igba lo maa n yo oko e lenu lawon ebi se panupo pe ko ko jade nile, sugbon awon ko mo bo se ko pada tawon ri oyun nikun e.
Arabinrin Monsurat ni o da bii pe Iya Sulia ati Ayelabowo ti n yan ara won lale tipe, ti oyun i ti o o ko too di pe o ko pada sodo Tajudeen. Oniroyin wa tun fese kan de adugbo ti Tajudeen ati iyawo e yii n gbe, ohun ta a gbo ni pe bi ki i baa se opelope Olorun, boya ni Ajile ati ale e yii iba ti da emi oko e legbodo. Won ni aimoye igba ni Ayelabowo ti won lo n gbe ni Soyoye, niluu Abeokuta, maa n waa ka obinrin naa mole, ti yoo si ba a sere daadaa ko too di pe o lo, won loko iyawo ki i mo nitori to ba ti lo sibi ise ni aaro, o di ale ko too de.
Enikan to ni ka foruko boun lasiiri to ba oniroyin wa soro so pe ojo kan wa ti Ayelabowo waa ka obinrin yii mole to so fun un pe ko yaa tete so fun oko e pe oun ko lo lomo, o ni bi ko ba tete jewo, oku yoo sun, won ni se lawon to gboro naa yanu ti won ko le pa a de.
Gbogbo akitiyan wa lati ri obinrin naa ba soro lo ja si pabo nitori won ni ko seni to le so pato ibi to n gbe, aburo e kan to n je Jimoh to n sise nileese manamana, PHCN, to wa ni Sabo to ba Iwe Iroyin Yoruba soro so pe oun naa ko le so pe ibi bayii legbon oun n gbe, oun saa mo pe odo okan lara awon ale e lo n gbe.
Jimoh so pe iwa buruku legbon oun hu, nitori e loun se le e lodo oun. O ni ko si nnkan toko e yii ko fi te e lorun, sugbon oju kokoro ko je ko gbadun. Oun naa fidi e mule pe loooto ni ale yii maa n waa ka obinrin naa mole nigba aye e. Abule kan ti won n pe ni Ojubu, Obada Ibiyemi ni won so pe Baba Ajile to je Mumini n gbe. Bee ni won ni inu baba naa ko dun si nnkan tomo e se yii.
Ni bayii, Tajudeen ti ke gbajare sawon araalu ati ijoba pe ki won gba oun o, ki won so fun obinrin yii pe ti omo mi-in ba tun wa ninu awon merin yooku ti ki i se oun lo bi won fun, ko tete waamuwon, o loun ko fee ri i mo ni sakani oun.
**{Legacy activities, comments etc counter: 1484; topic series: 5; forum: MediaYoruba; associated: 5- /*}