Topic: Alagba Soosi Lo N Bayawo Mi Sun— Ogbeni Michael Adebayo: Wahala Boko Haraamu Oro Azazi — Sola Adeyeye
Timeline: 2012-05-13 04:44:42
Idris Alooma, Ilorin ati Florence Babasola, Osogbo
Alagba Soosi Lo N Bayawo Mi Sun— Ogbeni Michael Adebayo: Wahala Boko Haraamu Oro Azazi — Sola Adeyeye
Ariwo, E gba mi o, alagba soosi wa n ba iyawo mi sun ni Ogbeni Michael Adebayo n pa laipe yii n Ilorin, o si ti seleri pe oun ko ni i gba, ati pe ijoba ni yoo bawon da si i. Sugbon iyawo e ti so pe iro lo n pa, o ni arun opolo lo n yo o lenu.
Okunrin naa soro ohun laipe yii, o ni soosi kan ti a foruko bo lasiiri to wa lagbegbe Sango loun n lo, oun si n se ojuse oun gege bii olujosin ododo. O ni o pe tawon kan ti n so foun pe Alagba soosi awon tawon eeyan mo si Olawumi n ba iyawo oun sun sugbon oun ko gba a soooto rara.
Baale ile yii ni akara oro naa tu sepo laipe yii nigba toun ri leta atejise ori foonu ti alagba ohun ko siyawo oun to so pe oun gbadun e gan-an lanaa, ati pe se ibi ana naa ni kawon tun ti pade. O lohun to fa kasiiri naa tu ni pe oun lo si irin ajo kan toun ti loo sise birikila, sugbon onile to ye ko waa pade awon lati Eko pe lori foonu pe oun lasidenti, eyi ti ko fi le wa mo.
Ogbeni Adebayo ni dipo ose kan to ye koun lo nibe, ojo keji loun pada de, eyi to mu koun pada wa siluu Ilorin ni kia. Sugbon boun se n bo lati Ofa tawon lo, dipo koun pe iyawo oun lati so fun un, oun ko se bee rara, nitori eti oun to ti kun tele nipa bi won se jo n gbera won kiri.
Bi mo se n bo ni mo gba soobu e lo. Ojiji ni moyo si i, nimobamu foonu e, mo se bii eni pe mo fee fi pe okan lara awon osise mi, bi mo se gba a ni mo ye awon leta ori e wo, ni mo ba sare fi leta naa ranse sori foonu mi nitori mo mo pe o le paro.
Leyin eyi lo so pe oun seefu nomba naa sori foonu oun. O ni boun se soju furu niyi bii eni pe oun ko mo nnkan kan, nigba ti yoo fi to ogbon iseju, okunrin naa ni iyawo oun ti pa gbogbo awon leta ori foonu e re. Loun ba dogbon lo sita lati loo pe eeyan naa lori foonu nibudo ipe.
Okunrin yii ni iyalenu lo je foun nigba teni to gbe foonu naa je Alagba soosi awon, o loun se bii eni pe oun si nomba naa pe ni. Adebayo ni boun se dele loun fi foonu iyawo oun pe nomba e toun ti ha sori. O ni boun se pe e, aserunlosoo, Hair Dresser, lo gbe jade. Sugbon okunrin lo gbe foonu to si so pe, Bawo ni dia . Bee oke lo loun fi foonu si. Eyi lo mu kiyawo oun fura pe asiri oun ti tu.
Adebayo ni gbogbo eyi loun fi mo pe onisekuse ni. O loun ti loo fejo alagba soosi naa atiyawo oun sun ni kootu nitori oun ko fe e mo. Bee lo so pe oun ti fi to awon alase ijo naa leti. Nigba ti a beere lowo obinrin yii, o niro loko oun n pa mo Alagba naa, o lo ti fori gbale lori okada ri. O ni boya arun opolo e lo tun de si i. Ni bayii, oko obinrin naa ti paaro kokoro to wa lenu ona yara iyawo e yii. A o si ti i mo ibi toro naa yoo ja si.
E Je Ka Tete Ronu Sohun Ti Azazi So—Sola Adeyeye
Ninu irohin miran ti o te awon oniwerohin Yoruba lowo, asofin to n soju awon eeyan agbegbe Aarin Gbungun Osun nile igbimo asofin agba, Ojogbon Olusola Adeyeye, ti salaye pe kawon eeyan orileede yii ma se foju te nbe lu oro ti oludamoran fun aare Naijiria lori eto aabo, Ogagun-feyinti Andrew Azazi so pe egbe oselu PDP lo n sokunfa wahala Boko Haraamu to n fojoojumo sele.
Lakooti Adeyeye nba Iwe Iroyin Yoruba soro niluu Osogbo lose to koja lo ti so pe latigba toun ti maa n gbo oruko Azazi, ko seni kan to le jade sita so pe okunrin naa je eni ti ki i ronu ko too soro lori nnkan.
Asofin agba yii gboriyin fun okunrin naa fun igboya nla to ni lati soro to so naa, o loun gbagbo pe oro naa ko ja bo lenu e, ayafi ti enikeni ba le jade lati so nnkan to yato si eleyii.
Adeyeye te siwaju pe, Ohun ti Jenera Azazi so nipa egbe oselu PDP je oro igboya, mo mo okunrin naa gege bii eni to maa n ronu ko too so ohunkohun.
Nitori awon akosile to ni ati opolopo odun to fi gba idanilekoo, mo fe kawon eeyan gba oro okunrin naa ro. O fi kun un pe w a h a l a B o k o Haraamu ati ainise lowo pelu ainireti to n da omi alaafia orileede yii ru bayii je nnkan to le fo o. O lo ye ki tolori-telemu fowosowo-po lati koju e ko too koja agbara.
Lori abo iwadi ile igbimo asofin apapo nipa afikun owo epo, o kilo fawon alase lati ma se doju abo iwadii naa ru bii tawon to ti sele siwaju nitori ko sohun ti won le dowo bo nipa re mo. B a k a n n a a n i Adeyeye ro awon eeyan o r i l e - e d e Naijiria lati ma se dake nipa siso fun ijoba apapo pe ki won gbe igbese lori abo iwadii naa, ati pe ki won fiya to to je enikeni ti aje iwa ibaje oro naa ba si mo lori.
**{Legacy activities, comments etc counter: 1340; topic series: 6; forum: MediaYoruba; associated: 6- /*}