Prev  

30. Surah Ar­Rûm سورة الرّوم

  Next  




Ayah  30:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
الم
Yoruba
 
'Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)


Ayah  30:3  الأية
    +/- -/+  
فِي أَدْنَى الْأَرْضِ وَهُم مِّن بَعْدِ غَلَبِهِمْ سَيَغْلِبُونَ
Yoruba
 
Ní àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn

Ayah  30:4  الأية
    +/- -/+  
فِي بِضْعِ سِنِينَ ۗ لِلَّهِ الْأَمْرُ مِن قَبْلُ وَمِن بَعْدُ ۚ وَيَوْمَئِذٍ يَفْرَحُ الْمُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Ní ọdún díẹ̀ (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣáájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú

Ayah  30:5  الأية
    +/- -/+  
بِنَصْرِ اللهِ ۚ يَنصُرُ مَن يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ
Yoruba
 
Sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  30:6  الأية
    +/- -/+  
وَعْدَ اللهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللهُ وَعْدَهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
(Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Ayah  30:7  الأية
    +/- -/+  
يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِّنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ
Yoruba
 
Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Ayah  30:8  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا فِي أَنفُسِهِم ۗ مَّا خَلَقَ اللهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُّسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ لَكَافِرُونَ
Yoruba
 
Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

Ayah  30:9  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا الْأَرْضَ وَعَمَرُوهَا أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
Yoruba
 
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

Ayah  30:10  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ كَانَ عَاقِبَةَ الَّذِينَ أَسَاءُوا السُّوأَىٰ أَن كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللهِ وَكَانُوا بِهَا يَسْتَهْزِئُونَ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn tó ṣaburú nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Allāhu ní irọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Ayah  30:11  الأية
    +/- -/+  
اللهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Yoruba
 
Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.

Ayah  30:12  الأية
    +/- -/+  
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُبْلِسُ الْمُجْرِمُونَ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù.

Ayah  30:13  الأية
    +/- -/+  
وَلَمْ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَائِهِمْ شُفَعَاءُ وَكَانُوا بِشُرَكَائِهِمْ كَافِرِينَ
Yoruba
 
Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn.

Ayah  30:14  الأية
    +/- -/+  
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَتَفَرَّقُونَ
Yoruba
 
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ayah  30:15  الأية
    +/- -/+  
فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَهُمْ فِي رَوْضَةٍ يُحْبَرُونَ
Yoruba
 
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí wọn yó sì máa dùn wọ́n nínú.

Ayah  30:16  الأية
    +/- -/+  
وَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ فَأُولَٰئِكَ فِي الْعَذَابِ مُحْضَرُونَ
Yoruba
 
Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná.

Ayah  30:17  الأية
    +/- -/+  
فَسُبْحَانَ اللهِ حِينَ تُمْسُونَ وَحِينَ تُصْبِحُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní ìrọ̀lẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀.

Ayah  30:18  الأية
    +/- -/+  
وَلَهُ الْحَمْدُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَعَشِيًّا وَحِينَ تُظْهِرُونَ
Yoruba
 
TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán.

Ayah  30:19  الأية
    +/- -/+  
يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَيُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ وَكَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde.

Ayah  30:20  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ
Yoruba
 
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé).

Ayah  30:21  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
Yoruba
 
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fún yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó láròjinlẹ̀.

Ayah  30:22  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْعَالِمِينَ
Yoruba
 
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀.

Ayah  30:23  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُم مِّن فَضْلِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ
Yoruba
 
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀.

Ayah  30:24  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Yoruba
 
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

Ayah  30:25  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ أَن تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِّنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنتُمْ تَخْرُجُونَ
Yoruba
 
Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀.

Ayah  30:26  الأية
    +/- -/+  
وَلَهُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَّهُ قَانِتُونَ
Yoruba
 
TiRẹ̀ ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.

Ayah  30:27  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn tó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  30:28  الأية
    +/- -/+  
ضَرَبَ لَكُم مَّثَلًا مِّنْ أَنفُسِكُمْ ۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُم مِّن شُرَكَاءَ فِي مَا رَزَقْنَاكُمْ فَأَنتُمْ فِيهِ سَوَاءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Yoruba
 
(Allāhu) ṣàkàwé kan fún yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fún yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gban̄dọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ'àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

Ayah  30:29  الأية
    +/- -/+  
بَلِ اتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَهْوَاءَهُم بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ فَمَن يَهْدِي مَنْ أَضَلَّ اللهُ ۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ
Yoruba
 
Ńṣe ni àwọn tó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn.

Ayah  30:30  الأية
    +/- -/+  
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا ۚ فِطْرَتَ اللهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا ۚ لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللهِ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn Islām, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sí ìyípadà fún ẹ̀sìn Allāhu. (ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn Allāhu padà.) Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Ayah  30:31  الأية
    +/- -/+  
مُنِيبِينَ إِلَيْهِ وَاتَّقُوهُ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُشْرِكِينَ
Yoruba
 
(Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kí ìrun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Ayah  30:32  الأية
    +/- -/+  
مِنَ الَّذِينَ فَرَّقُوا دِينَهُمْ وَكَانُوا شِيَعًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ
Yoruba
 
(Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn tó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.

Ayah  30:33  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا مَسَّ النَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا أَذَاقَهُم مِّنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn

Ayah  30:34  الأية
    +/- -/+  
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

Ayah  30:35  الأية
    +/- -/+  
أَمْ أَنزَلْنَا عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُوا بِهِ يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, tó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?

Ayah  30:36  الأية
    +/- -/+  
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا بِهَا ۖ وَإِن تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù.

Ayah  30:37  الأية
    +/- -/+  
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Yoruba
 
Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu l'Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.

Ayah  30:38  الأية
    +/- -/+  
فَآتِ ذَا الْقُرْبَىٰ حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجْهَ اللهِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn tó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.

Ayah  30:39  الأية
    +/- -/+  
وَمَا آتَيْتُم مِّن رِّبًا لِّيَرْبُوَ فِي أَمْوَالِ النَّاسِ فَلَا يَرْبُو عِندَ اللهِ ۖ وَمَا آتَيْتُم مِّن زَكَاةٍ تُرِيدُونَ وَجْهَ اللهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُضْعِفُونَ
Yoruba
 
Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀yáwó, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san.

Ayah  30:40  الأية
    +/- -/+  
اللهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ ثُمَّ رَزَقَكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۖ هَلْ مِن شُرَكَائِكُم مَّن يَفْعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَيْءٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fún yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

Ayah  30:41  الأية
    +/- -/+  
ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Yoruba
 
Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú).

Ayah  30:42  الأية
    +/- -/+  
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُم مُّشْرِكِينَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn tó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ."

Ayah  30:43  الأية
    +/- -/+  
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ الْقَيِّمِ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ يَوْمٌ لَّا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná).

Ayah  30:44  الأية
    +/- -/+  
مَن كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِأَنفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ
Yoruba
 
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún

Ayah  30:45  الأية
    +/- -/+  
لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِن فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ
Yoruba
 
Nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́.

Ayah  30:46  الأية
    +/- -/+  
وَمِنْ آيَاتِهِ أَن يُرْسِلَ الرِّيَاحَ مُبَشِّرَاتٍ وَلِيُذِيقَكُم مِّن رَّحْمَتِهِ وَلِتَجْرِيَ الْفُلْكُ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِن فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Yoruba
 
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fún yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

Ayah  30:47  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَانتَقَمْنَا مِنَ الَّذِينَ أَجْرَمُوا ۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيْنَا نَصْرُ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  30:48  الأية
    +/- -/+  
اللهُ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُ فِي السَّمَاءِ كَيْفَ يَشَاءُ وَيَجْعَلُهُ كِسَفًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ ۖ فَإِذَا أَصَابَ بِهِ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Yoruba
 
Allāhu ni Ẹni tó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa gbé ẹ̀ṣújò dìde. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s'ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú.

Ayah  30:49  الأية
    +/- -/+  
وَإِن كَانُوا مِن قَبْلِ أَن يُنَزَّلَ عَلَيْهِم مِّن قَبْلِهِ لَمُبْلِسِينَ
Yoruba
 
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀.

Ayah  30:50  الأية
    +/- -/+  
فَانظُرْ إِلَىٰ آثَارِ رَحْمَتِ اللهِ كَيْفَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Yoruba
 
Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yẹn ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Ayah  30:51  الأية
    +/- -/+  
وَلَئِنْ أَرْسَلْنَا رِيحًا فَرَأَوْهُ مُصْفَرًّا لَّظَلُّوا مِن بَعْدِهِ يَكْفُرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀.

Ayah  30:52  الأية
    +/- -/+  
فَإِنَّكَ لَا تُسْمِعُ الْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ الصُّمَّ الدُّعَاءَ إِذَا وَلَّوْا مُدْبِرِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú ìwọ kọ́ l'o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.

Ayah  30:53  الأية
    +/- -/+  
وَمَا أَنتَ بِهَادِ الْعُمْيِ عَن ضَلَالَتِهِمْ ۖ إِن تُسْمِعُ إِلَّا مَن يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا فَهُم مُّسْلِمُونَ
Yoruba
 
Ìwọ kọ́ l'o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu.

Ayah  30:54  الأية
    +/- -/+  
اللهُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن ضَعْفٍ ثُمَّ جَعَلَ مِن بَعْدِ ضَعْفٍ قُوَّةً ثُمَّ جَعَلَ مِن بَعْدِ قُوَّةٍ ضَعْفًا وَشَيْبَةً ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْقَدِيرُ
Yoruba
 
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára.

Ayah  30:55  الأية
    +/- -/+  
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُقْسِمُ الْمُجْرِمُونَ مَا لَبِثُوا غَيْرَ سَاعَةٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَانُوا يُؤْفَكُونَ
Yoruba
 
Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ." Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo.

Ayah  30:56  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَالْإِيمَانَ لَقَدْ لَبِثْتُمْ فِي كِتَابِ اللهِ إِلَىٰ يَوْمِ الْبَعْثِ ۖ فَهَٰذَا يَوْمُ الْبَعْثِ وَلَٰكِنَّكُمْ كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: "Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀."

Ayah  30:57  الأية
    +/- -/+  
فَيَوْمَئِذٍ لَّا يَنفَعُ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَعْذِرَتُهُمْ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.

Ayah  30:58  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِن كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَلَئِن جِئْتَهُم بِآيَةٍ لَّيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ أَنتُمْ إِلَّا مُبْطِلُونَ
Yoruba
 
A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur'ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: "Ẹ̀yin (Òjíṣẹ́) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́."

Ayah  30:59  الأية
    +/- -/+  
كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللهُ عَلَىٰ قُلُوبِ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀.

Ayah  30:60  الأية
    +/- -/+  
فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللهِ حَقٌّ ۖ وَلَا يَسْتَخِفَّنَّكَ الَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ di òpè (bí irú wọn).
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us