Topic: Won N Wa Awon Gomina Ni London, Won Fee So Won Sewon Bii Ibori
Timeline: 2012-05-13 04:56:23
Lati Owo Ademola Adejare
Won N Wa Awon Gomina Ni London, Won Fee So Won Sewon Bii Ibori
Bi eto ba to daadaa, ko le pe ti won yoo fi tun taari awon Gomina atijo kan lo siluu oyinbo. Awon oyinbo n wa won , bee ni inu awon EFCC yoo si dun lati ran won lo sohun-un kiakia, nitori won mo pe bi won ba wa ni Naijiria nibi, apa awon ko le ka won.
Eto kan wa laarin ijoba Naijiria atijoba United Kingdom, pe won ko ni i di ara won lowo lati waadii, ki won si mu odaran yoowu to ba se sofin, paapaa bo ba je nidii iwa ibaje tabi ikowo-ijoba-pamo. Labe ajose yii ni won fi ri James Ibori gbe, ti won si la a mewon odun metala, ti won ni ko loo faso penpe roko oba.
Oro Ibori yii lo ti waa dakoba fawon Gomina to ku, awon ti won ti ji owo ilu ko, to si je London ni won ko won si. Iwe Iroyin Yoruba gbo pe awon Olopaa ilu oyinbo ti tun bere si i kowe sawon ijoba ile yii, bi won ti n ko si EFCC, ni won n ko sileese Aare, won lawon Gomina atijo kan wa tawon fe niluu awon, paapaa awon meji kan tawon ti koko mu tele, sugbon ti won sa lo mo awon lowo.
Bi e ko ba gbagbe, ojo keji, osu kesan-an, odun 2004, ni won ki Gomina ipinle Plateau igba naa, Joshua Dariye mole, ti won mu un pe o kowo nla wolu London, awon si gbodo ba a sejo nitori ko le salaye bowo naa ti je, ati ibi to ti ri i. Oteeli Marriot lo de si niluu London nibe, nigba tawon olopaa si de oteeli ohun lati mu un, owo bii egberun lona okoolenigba owo dola ni won ba lowo re, ko seni to mo ohun to waa fi se.
Kia ni won ti mu un ti won si ti i mole, bii ojo keta ni won gbe e lo sile-ejo, ti won si gba beeli re, won ni ko gbodo lo sibi kan. Sugbon nibi tawon olopaa ilu nla ti n wo ibomiin ti won ko foju sodo Dariye, bee ni Gomina naa tu mo won lowo, to si sa pada wa si Naijiria, lai duro gbowo to ko wole pada, ko si deluu ohun latojo naa mo.
Ohun to bi awon oyinbo yii ninu niyen nigba ti won pada mu Gomina mi-in, leyin odun kan ti Dariye ti sa mo won lowo. Ojo buruku lojo keeedogun, osu kesan-an, odun 2005, fun Gomina Bayelsa, Dieprieye Alamieyeseigha, nitori lojo naa ni won mu un ni papako ofurufu Healthrow ni London, nitori owo buruku toun naa ko wole.
Bi won ti mu un, won ko je ko lo, o si pe gan-an ki won too gba beeli re.
Bi won ti gba beeli re paapaa, won ni ko gbodo rin koja bii maili kan sile re, iyen ni pe nibi to n gbe naa lo gbodo maa wa nigba gbogbo. Sugbon nitori pe won ko sofin kalejo ma wa a wa, lojo kan, obinrin kan we gele, o ro iro ati buba wole, nigba to si n jade lo, awon olopaa ko da a duro, won ro pe eni to wole naa lo jade pada.
Awon ko mo pe jagunlabi naa lo wa labe aso, won ko mo pe Gomina Alami funra e lo woso obinrin, to si tun de konseeti maya, o ti ba ona eburu wo Naijiria ki won too mo pe jagunlabi ti lo mo won lowo. Latigba naa ni ko ti jade niluu yii mo, bo ba si jade, eegun re ko je se ni London.
Opolo ni ti a ba soro debi iru ka fo o, beeyan ba fee ri erin lenu Alayabiagba okunrin, ko ni ko je kawon sere lo si London.
Sugbon ni bayii, awon olopaa London fe ki won da awon meji yii pada fawon, bee si lawon Gomina mi-in ti won kowo buruku pamo sohunun, Gomina atijo ile Yoruba kan si wa ti won ti de pakute nla sile fun, lojo to ba dase wo London ni kinni ohun yoo gbe e!
**{Legacy activities, comments etc counter: 848; topic series: 7; forum: MediaYoruba; legacy score: 5; legacy ratings: 1; rating_ip: **.*51.152.220; associated: 7- /*}