Topic: Mama Damilola Olokada Tawon Olopaa Pa n’Ilesa Pariwo: Oron Nla Lawon To Pa Damilola Da Mi
Timeline: 2012-05-13 04:11:59
Lati Owo Bisi Adesoye, Ilesa ati Florence Babasola, Osogbo
Mama Damilola Olokada Tawon Olopaa Pa n’Ilesa Pariwo: Oron Nla Lawon To Pa Damilola Da Mi
Leyin ose meji ti olopaa kan fi pa Damilola lagbegbe Egbe-Idi, nijoba ibile Iwo-Oorun Ilesa, ilee se olopaa ipinle Osun ko ti i gbe igbese kankan, yala lati sanwo gba-ma-binu fun molebi omo ti won pa tabi gbe odaran naa lo sile-ejo.
Iwadii fidi e mule pe lojo buruku esu gbomimu naa ni olopaa ohun wa oko re laibikita fun ofin atawon awon eeyan ti won n lo loju popo, to kolu olokada naa toruko re n je Damilola.
Gege bi eni toro naa soju e se so, o ni bi naa ti gba okunrin yii to si n gbiyanju lati yira re kuro labe e, nise ni awako naa tun feyin rin pada, o te omokunrin olokada naa lori, ti opolo re si tuka si oju popo. dele awon oloogbe yii lati ba iya re soro, nigba ti obinrin naa ri wa, nise lo bu sekun.
Arabinrin Adedunni Agboola salaye pe o pe toun atawon molebi oun ti n gbiyanju lati tomo naa.
Iya yii ni oun fi Damilola senu ekose ise aranso leyin to jade nileewe pelu afojusun pe yoo duro bii oko ati baba foun, sugbon se ni naa da emi re legbodo.
Fun bii ogbon iseju lobinrin naa fi n sunkun, to si n gbe eni to sise ibi naa sepe, leyin to dake ekun sisun lo so fun akoroyin wa pe Damilola ti bi omo kan, sugbon eso abemi naa ko ti i ju odun meji lo. O lo niyawo, bee lo si n gbo bukaata lori won, sugbon eru naa ti di toun bayii.
Arabinrin Agboola lawon ko ti i ri owo gba-ma-binu kankan gba lati odo enikeni, yala olopaa tabi ipinle Osun. O waa ni ile-ejo ni yoo yanju oro naa, afi bi ko ba sofin mo lorileede yii nikan lo ku. Ogbeni Adetunji Aderemi to je aburo Iya Damilola so pe iwa ta ni yoo mu mi lawon olopaa ipinle Osun gbe wo, o ni won gbagbo pe ofin orile-ede ko si fawon lati mulo. O·kunrin naa ni laipe yii ni gbogbo molebi awon yoo gbe igbese labe ofin, o ni kawon olopaa ipinle Osun gbaradi lati foju odaran to pa won lomo han ile-ejo.
Alaga egbe Ilesa ti Damilola je omo egbe won, Ogbeni Ayeni Sayo, so pe awon olopaa ko ti i gbe igbese lati sanwo gba-mabinu, won ko si ti i gbe odaran naa lo sile-ejo.
O ni lojo Abameta, to koja ni oludari agba fun egbe awon, Ogbeni Amos Ogunbiyi, ba oga olopaa ni ekun Ijesa, Kayode Tuner sepade, ninu ipade naa ni oga olopaa naa ti ni oun ko ti i ri esi kankan gba lati olu ileese awon l’Osogbo.
Ilesa ni Abileko Aduke ti wa s’Osogbo, lo ba ku sibe
Ise ati osi to n ba opolopo awon eeyan orile-ede yii finra lakooko yii ti ran iya agbalagba eni odun marundinlaaadorin kan, Aduke Idowu lo sorun osan gangan niluu Osogbo laipe yii.
Se lawon eeyan agbegbe Agowande si Igbona, niluu Osogbo deede ri iya agba legbee gota kan laaaro Wesde, ojo kokanla, osu kerin, odun yii. Akiyesi awon to koko ri i ni pe ara iya naa ko bale rara, ati pe ko seni to le ri i ti ko ni i mo pe owo ebi wa lara e.
Ko ma baa di pe iya yii yoo ku sagbegbe won, won ranse sawon alase ijoba ibile Olorunda lati wa nnkan se soro obinrin naa ko too bo sori, sugbon Iwe Iroyin Yoruba gbo pe se lawon yen so fun won pe ko si nikawo awon lati se ohunkohun lori e.
Bayii ni won ranse si Komisanna foro odo, ere-idaraya ati akanse ise, Amofin Stephen Kola Balogun, sugbon a gbo pe won ko ri enikeni da won lohun nibe. Gege bi Arabinrin Aduke Idowu se salaye fawon oniroyin ko too di pe o jade laye, o ni nigba ti ko si nnkan toun le je, ti aisan si n yo oun lenu gidigidi ni alaaanu kan gbe oun wa sagbegbe naa.
O ni, Araromi, n’Ilesa ni mo ti wa, awon alaaanu kan ni won gbe mi wa si Osogbo kawon ijoba baa le ri mi nitori pe ara mi ko ya, Eko ni gbogbo awon omo mi n gbe, ko seni ti mo fee ran si won. Mo wa sibi kijoba le ran mi lowo nipa fifun mi lounje, ki won si ba mi toju ara mi, sugbon n ko ri enikeni ran mi lowo. Gbogbo ojo to ro lojo Wesde lo da le mi lori ninu gota yii, bee ni n ko ni okun ati agbara kankan mo.
Ileese kan ti won n pe ni The Hope for Family Development Initiative (HFDI) to wa ni Agowande ti won gbe iya yii si salaye fawon oniroyin pe ni kete tawon ti ri i lawon ti bere igbese pelu kiko leta si komisanna foro odo, ere-idaraya atakanse ise lati dide iranlowo fun un, sugbon gbogbo re lo ja si pabo.
Gege bi alaamojuto egbe HFDI, Ogbeni Aremu Stephen, se salaye, ojo kejila, osu kerin ni won ko leta si komisanna yii, sugbon iyalenu lo je pe okunrin naa ko gbe igbese kankan titi ti iya agba ohun fi jade laye ni Fraide, ojo ketala, osu kerin.
Aremu ni, O ya mi lenu pe komisanna ko gbe igbese kankan lori leta ti a ko yen, a si salaye sinu leta yen pe apa ajo wa ko ka itoju mama yen ni a ko se daya ko o, a si ro pe ijoba yoo wa nnkan se si i, sugbon ijakule la ba pade latodo awon komisanna wa titi ti iya yen fi gbemii mi ni nnkan bii aago mejila osan ojo Fraide.
Aremu ni, Lati aaro ojo keji ti won ti gbe mama yii sile, iyen ojo Tosde, ni ko ti le da jokoo daadaa mo, to ti di pe se lo n wo nile, ko si seni ti ko mo pe ebi lo n pa a, bee lara re ko si da rara.
**{Legacy activities, comments etc counter: 550; topic series: 9; forum: MediaYoruba; associated: 9- /*}