Topic: Oga O! Were Fi Sisoosi Gun Olokada Nikun Sakasaka: Ile Oti Ti Won Ti N We Okada Tuntun Ni Samuel Ti Ji I Gbe n’Ilorin
Timeline: 2012-05-13 04:22:33
Lati Owo Idris Alooma, Ilorin ati Idris Alooma, Ilorin
Oga O! Were Fi Sisoosi Gun Olokada Nikun Sakasaka: Ile Oti Ti Won Ti N We Okada Tuntun Ni Samuel Ti Ji I Gbe n’Ilorin
Olorun lo yo okunrin kan, Baba Danmairomu, se ni were sadeede gun un ni sisoosi ninu ati aya e laduugbo Elekoyangan, n Ilorin, to si daku rangbondan. Gbogbo ifun e lo tu jade, bi ki i baa se Olorun to ko o yo, nise ni i ba ku patapata. Sugbon oro e da bii eni t Olorun o pa, bo ba ku, yoo tun ji pada saye.
Gege bi iwadii oniroyin wa, omo bibi ilu Ilorin, lagbegbe Ita Goma, ni Ogbeni Danmairomu, o n bo latodo eeyan kan to lo lori okada e ni, bo se de Elekoyangan lo ri okunrin to n koja loju-popo. Ohun to ro ni pe koun duro fun un lati ma baa ko lu u. Sadeede lokunrin yii mu sisoosi, to si gun Danmairomu ninu ati aya, eyi to mu un digbo lule, to si daku rangbondan.
Awon eeyan to wa laduugbo naa lo sare gbe e lo si osibitu kan to n je Oorelope, nitosi ibe. Eyin e lawon molebi were yii be awon to wa nibe lati ba won ra a mu, ko ma baa tun se elomi-in lese.
Ni nnkan bii odun meje seyin lara okunrin naa ko ti ya, sugbon won ti toju e, ara e si ti ya daadaa. Koda won ni ko seni to le mo pe iru nnkan bee se e ri, sugbon sadeede laisan naa tun bere si i lojiji, to kuro nile bo soju-popo. Ko seeyan to ri i pelu bo se wo aso to daa ti yoo mo pe nnkan n se e lopolo.
Nigba ti a de Osibitu Oorelope ti won gbe okunrin naa lo fun itoju, aanu abiyamo seeyan nitori nise lawon noosi ati dokita fun un lorisiirisii oogun ko too di pe o pada ji saye, bee lo si je pe won ni lati ba a ran inu e pada ni.
O·kunrin naa funra e soro, o losise to ti feyinti loun, eka ti won ti n te iwe nileese eto iroyin nipinle Kwara lo loun wa nigba naa. O so pe okada toun gun lojo buruku yii ki i se pe oun fi n sise lati wa ounje oojo, oun fi n sese rin ni.
O salaye pe ni deede aago mefa irole toun n pada lo sile leyin toun kuro nibi toun lo, sadeede lokunrin to wo aso daadaa yii jana mo oun lenu, eyi toun ro pe omoleewe ni nitori opo igba lawon omoleewe Poli to po lagbegbe naa maa n fojudi moto ati okada. O ni afigba tokunrin naa sun mo oun, to si bere si i gun oun ni sisoosi nla to wa lowo e. Okunrin yii fi kun oro re pe ni gbogbo ara lo ti n gun oun, sugbon inu ati aya lo lagbara ju. O ni bo se gun oun loun daku, toun si subu lule lori okada toun wa, oun ko si mo ibi toun wa mo.
Danmairomu salaye pe awon molebi okunrin were naa saajo oun gan-an ni, nitori gbogbo igba ni won maa n waa wo oun losibitu, bee ni won seleri lati sanwo ti won fi toju oun. Lakooko ti a de tesan olopaa ilu Oke Oyi, nijoba ibile Ila-Oorun, n Ilorin, awon olopaa to wa nibe so pe awon ko le soro lori isele naa, afi ti a ba de olu ileese awon. Won lalukoro awon nikan lo le soro.
A de olu ileese won ni Kwara, alukoro won, Ogbeni Dabo Ezekiel, ko si nile, sugbon olopaa kan to ni ka foruko boun lasiiri so pe loooto lawon gbo nipa isele ohun, sugbon awon gbo pe awon toro naa sele si ti so pe awon ko sejo rara.
Ni bayii, okunrin naa si n gbatoju losibitu.
Ile Oti Ti Won Ti N We Okada Tuntun Ni Samuel Ti Ji I Gbe n’Ilorin
Gelete ni oku adigunjale kan, Ogbeni Samuel to be sinu odo Asa, n Ilorin laipe yii wu tawon eeyan si fi n seran wo.
Nigba to yo poro mo awon to fee dana sun un lowo leyin towo te e pe o ji okada gbe nibi ti won ti n sajoyo lo mu ko be sodo, to si ku patapata.
Gege bi iwadii oniroyin wa, a gbo pe laipe yii lokunrin kan ra okada, ajo lo fi ra a, oun naa deni to n lo okada tuntun loju awon to ti ro o pin pe ko le je nnkan laye. Eyi lo mu kinu e dun, to si ko awon eeyan lo sagbegbe kan to n je Obo Road, to wa nitosi Unity, n Ilorin, lati sajoyo okada naa.
Ni kete to debe lo bere si i ra oti fun won, ti gbogbo won si n sadura fun un pe yoo remii lo okada tuntun naa, ati pe ole ko ni i gbe e lo. Lara awon to ba a nibe tawon naa n ba a yo, bo tile je pe ko mo opolopo won ri lokan ninu won sadeede dide leyin to ti muti igo kan si i lorun tan, to si se bii eni pe o fee loo to, sugbon sadeede lo bo segbee okada naa, to si ki kokoro kan bo o lenu.
Kokoro aramonda kan ti won n pe ni masita kii lo fi sina okada naa, o si n gbe e sa lo.
A gbo pe bawon eeyan se n kigbe, Ole le okunrin naa lori, ti won si n le e lo lowo te e.
Awon ero iworan to wa nibe ja a sihooho, won fee so taya moto si i lorun, ki won si lu u pa.
Lakooko naa gan-an lawon olopaa to n kaakiri agbegbe naa de, won si gba a sile lowo won ki won ma baa sedajo funra won.
Nigba naa lokunrin yii raaye yo poro mo won lowo, to si n sa lo. Eyi lo mu kawon olopaa bere si i le e latimuun, ki won le gbe e lo si tesan won.
Ibi to ti n sa lo tawon olopaa n le e, ti won fee mu ni tipa tipa lokunrin naa ti ri i pe omi ti tan leyin eja oun, bo se sare de bebe odo nla ti won n pe ni Asa to la ilu Ilorin koja niyen, bawon olopaa se n wo o pe owo awon ti te e nitori ko le sare koja odo naa towo yoo fi te e, si iyalenu won, se nigaara olosa naa be sinu odo jua.
Ninu oro okunrin kan tisele ohun soju e, Ogbeni Abiodun, o so pe ni kete tokunrin naa ti be sodo lawon olopaa ti da okada naa pada feni to ni in, ti won si ki i ku oriire. Awon oti yooku tawon to n ba a sajoyo mu ku, ibe ni won fi gbogbo e si nitori oro ti pesi je.
Abiodun fi kun un pe nigba to di ojo keta ti Samuel ti be sodo loku e lefoo, nigba to ya lomi gbe e wa si bebe odo, oku e si tiwubente. Oniroyin wa ba oku Samuel ni eti odo Asa eyi to wa lopopo Station tawon eeyan si n pewo o. Nigba ti a de olu ileese awon olopaa to wa lagbegbe GRA, n’Ilorin, a o ba alukoro won lofiisi, enikan to da wa lohun so pe loooto lawon gbo nipa isele naa.
Ni bayii, a gbo pe awon olopaa ti gbe oku okunrin naa lo si mosuari Osibitu Fasiti Ilorin.
**{Legacy activities, comments etc counter: 530; topic series: 1; forum: MediaYoruba; associated: 1- /*}