Prev  

53. Surah An-Najm سورة النجم

  Next  




Ayah  53:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
وَالنَّجْمِ إِذَا هَوَىٰ
Yoruba
 
Allāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur'ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.

Ayah  53:2  الأية
    +/- -/+  
مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمْ وَمَا غَوَىٰ
Yoruba
 
Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.

Ayah  53:3  الأية
    +/- -/+  
وَمَا يَنطِقُ عَنِ الْهَوَىٰ
Yoruba
 
Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.

Ayah  53:4  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَىٰ
Yoruba
 
Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.

Ayah  53:5  الأية
    +/- -/+  
عَلَّمَهُ شَدِيدُ الْقُوَىٰ
Yoruba
 
Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l'ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur'ān).

Ayah  53:6  الأية
    +/- -/+  
ذُو مِرَّةٍ فَاسْتَوَىٰ
Yoruba
 
Ó ní àlàáfíà tó péye, ó sì dúró wámúwámú,

Ayah  53:7  الأية
    +/- -/+  
وَهُوَ بِالْأُفُقِ الْأَعْلَىٰ
Yoruba
 
Nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.

Ayah  53:8  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).

Ayah  53:9  الأية
    +/- -/+  
فَكَانَ قَابَ قَوْسَيْنِ أَوْ أَدْنَىٰ
Yoruba
 
(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).

Ayah  53:10  الأية
    +/- -/+  
فَأَوْحَىٰ إِلَىٰ عَبْدِهِ مَا أَوْحَىٰ
Yoruba
 
Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí tó fún un.

Ayah  53:11  الأية
    +/- -/+  
مَا كَذَبَ الْفُؤَادُ مَا رَأَىٰ
Yoruba
 
Ọkàn (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kò parọ́ ohun tó rí.

Ayah  53:12  الأية
    +/- -/+  
أَفَتُمَارُونَهُ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ
Yoruba
 
Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun tó rí ni?

Ayah  53:13  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ رَآهُ نَزْلَةً أُخْرَىٰ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ó tún rí i nígbà kejì

Ayah  53:14  الأية
    +/- -/+  

Ayah  53:15  الأية
    +/- -/+  
عِندَهَا جَنَّةُ الْمَأْوَىٰ
Yoruba
 
Nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.

Ayah  53:16  الأية
    +/- -/+  
إِذْ يَغْشَى السِّدْرَةَ مَا يَغْشَىٰ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí ohun tó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.

Ayah  53:17  الأية
    +/- -/+  
مَا زَاغَ الْبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ
Yoruba
 
Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-ààlà.

Ayah  53:18  الأية
    +/- -/+  
لَقَدْ رَأَىٰ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِ الْكُبْرَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, tó tóbi.

Ayah  53:19  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتُمُ اللَّاتَ وَالْعُزَّىٰ
Yoruba
 
Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,

Ayah  53:20  الأية
    +/- -/+  
وَمَنَاةَ الثَّالِثَةَ الْأُخْرَىٰ
Yoruba
 
Àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.

Ayah  53:21  الأية
    +/- -/+  
أَلَكُمُ الذَّكَرُ وَلَهُ الْأُنثَىٰ
Yoruba
 
Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?

Ayah  53:22  الأية
    +/- -/+  

Ayah  53:23  الأية
    +/- -/+  
إِنْ هِيَ إِلَّا أَسْمَاءٌ سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَاؤُكُم مَّا أَنزَلَ اللهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَمَا تَهْوَى الْأَنفُسُ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ الْهُدَىٰ
Yoruba
 
(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́ (ìfẹ́-inú). Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.

Ayah  53:24  الأية
    +/- -/+  
أَمْ لِلْإِنسَانِ مَا تَمَنَّىٰ
Yoruba
 
Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan tó bá ń fẹ́!

Ayah  53:25  الأية
    +/- -/+  

Ayah  53:26  الأية
    +/- -/+  
وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِي السَّمَاوَاتِ لَا تُغْنِي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا إِلَّا مِن بَعْدِ أَن يَأْذَنَ اللهُ لِمَن يَشَاءُ وَيَرْضَىٰ
Yoruba
 
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika tó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.

Ayah  53:27  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ لَيُسَمُّونَ الْمَلَائِكَةَ تَسْمِيَةَ الْأُنثَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.

Ayah  53:28  الأية
    +/- -/+  
وَمَا لَهُم بِهِ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ ۖ وَإِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا
Yoruba
 
Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Dájúdájú àbá dídá kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.

Ayah  53:29  الأية
    +/- -/+  
فَأَعْرِضْ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا
Yoruba
 
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.

Ayah  53:30  الأية
    +/- -/+  
ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُم مِّنَ الْعِلْمِ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اهْتَدَىٰ
Yoruba
 
Ìyẹn ni ohun tí wọ́n wọ̀n nínú ìmọ̀. Dájúdájú Olúwa rẹ lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó mọ̀nà.

Ayah  53:31  الأية
    +/- -/+  
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى
Yoruba
 
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn tó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.

Ayah  53:32  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ إِلَّا اللَّمَمَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ وَاسِعُ الْمَغْفِرَةِ ۚ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنشَأَكُم مِّنَ الْأَرْضِ وَإِذْ أَنتُمْ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ ۖ فَلَا تُزَكُّوا أَنفُسَكُمْ ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اتَّقَىٰ
Yoruba
 
Àwọn tó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Òun l'Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀).

Ayah  53:33  الأية
    +/- -/+  
أَفَرَأَيْتَ الَّذِي تَوَلَّىٰ
Yoruba
 
Sọ fún mi nípa ẹni tó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),

Ayah  53:34  الأية
    +/- -/+  
وَأَعْطَىٰ قَلِيلًا وَأَكْدَىٰ
Yoruba
 
Tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!

Ayah  53:35  الأية
    +/- -/+  
أَعِندَهُ عِلْمُ الْغَيْبِ فَهُوَ يَرَىٰ
Yoruba
 
Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l'ó ma bá òun jìyà lọ́run)?

Ayah  53:36  الأية
    +/- -/+  
أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ
Yoruba
 
Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun tó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,

Ayah  53:37  الأية
    +/- -/+  
وَإِبْرَاهِيمَ الَّذِي وَفَّىٰ
Yoruba
 
Àti (tírà Ànábì) 'Ibrọ̄hīm, ẹni tó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,

Ayah  53:38  الأية
    +/- -/+  
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ
Yoruba
 
Pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.

Ayah  53:39  الأية
    +/- -/+  
وَأَن لَّيْسَ لِلْإِنسَانِ إِلَّا مَا سَعَىٰ
Yoruba
 
Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun tó ṣe níṣẹ́.

Ayah  53:40  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّ سَعْيَهُ سَوْفَ يُرَىٰ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.

Ayah  53:41  الأية
    +/- -/+  
ثُمَّ يُجْزَاهُ الْجَزَاءَ الْأَوْفَىٰ
Yoruba
 
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san tó kún jùlọ.

Ayah  53:42  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الْمُنتَهَىٰ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).

Ayah  53:43  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ هُوَ أَضْحَكَ وَأَبْكَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.

Ayah  53:44  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ هُوَ أَمَاتَ وَأَحْيَا
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.

Ayah  53:45  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ خَلَقَ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنثَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,

Ayah  53:46  الأية
    +/- -/+  
مِن نُّطْفَةٍ إِذَا تُمْنَىٰ
Yoruba
 
Láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.

Ayah  53:47  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّ عَلَيْهِ النَّشْأَةَ الْأُخْرَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,

Ayah  53:48  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ هُوَ أَغْنَىٰ وَأَقْنَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó ń fún ẹ̀dá ní ọrọ̀ dúkìá, Ó sì ń ta ẹ̀dá ní òṣì.

Ayah  53:49  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ هُوَ رَبُّ الشِّعْرَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).

Ayah  53:50  الأية
    +/- -/+  
وَأَنَّهُ أَهْلَكَ عَادًا الْأُولَىٰ
Yoruba
 
Dájúdájú Òun l'Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;

Ayah  53:51  الأية
    +/- -/+  

Ayah  53:52  الأية
    +/- -/+  
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ
Yoruba
 
Àti ìjọ Nūh tó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-ààlà jùlọ;

Ayah  53:53  الأية
    +/- -/+  
وَالْمُؤْتَفِكَةَ أَهْوَىٰ
Yoruba
 
Àti ìlú tó dojú bolẹ̀ (ìlú Ànábì Lūt), Allāhu ló yẹ̀ ẹ́ lulẹ̀ (láti òkè).

Ayah  53:54  الأية
    +/- -/+  
فَغَشَّاهَا مَا غَشَّىٰ
Yoruba
 
Ohun tó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

Ayah  53:55  الأية
    +/- -/+  
فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ
Yoruba
 
Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?

Ayah  53:56  الأية
    +/- -/+  
هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ النُّذُرِ الْأُولَىٰ
Yoruba
 
Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.


Ayah  53:58  الأية
    +/- -/+  
لَيْسَ لَهَا مِن دُونِ اللهِ كَاشِفَةٌ
Yoruba
 
Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni tó lè tú gbèdéke Àkókò náà jáde.

Ayah  53:59  الأية
    +/- -/+  
أَفَمِنْ هَٰذَا الْحَدِيثِ تَعْجَبُونَ
Yoruba
 
Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l'ó ń ṣe yín ní kàyéfì?

Ayah  53:60  الأية
    +/- -/+  
وَتَضْحَكُونَ وَلَا تَبْكُونَ
Yoruba
 
Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ kò sì sunkún!


Ayah  53:62  الأية
    +/- -/+  
فَاسْجُدُوا لِلَّهِ وَاعْبُدُوا ۩
Yoruba
 
Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).
 


© EsinIslam.Com Designed & produced by The Awqaf London. Please pray for us