Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
Àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.