Prev  

27. Surah An-Naml سورة النّمل

  Next  




Ayah  27:1  الأية
    +/- -/+  
بِسْم ِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
طس ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْقُرْآنِ وَكِتَابٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Tọ̄ sīn. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.) Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah al-Ƙur'ān àti (àwọn āyah) Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

Ayah  27:2  الأية
    +/- -/+  
هُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìró ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo,

Ayah  27:3  الأية
    +/- -/+  
الَّذِينَ يُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَهُم بِالْآخِرَةِ هُمْ يُوقِنُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Ayah  27:4  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ زَيَّنَّا لَهُمْ أَعْمَالَهُمْ فَهُمْ يَعْمَهُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti ṣe àwọn iṣẹ́ (aburú ọwọ́) wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn, Nítorí náà, wọn yó sì máa pa rìdàrìdà.

Ayah  27:5  الأية
    +/- -/+  
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَهُمْ سُوءُ الْعَذَابِ وَهُمْ فِي الْآخِرَةِ هُمُ الْأَخْسَرُونَ
Yoruba
 
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìyà burúkú wà fún. Àwọn sì ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.

Ayah  27:6  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّكَ لَتُلَقَّى الْقُرْآنَ مِن لَّدُنْ حَكِيمٍ عَلِيمٍ
Yoruba
 
Dájúdájú ò ń gba al-Ƙur'ān làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Ayah  27:7  الأية
    +/- -/+  
إِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِأَهْلِهِ إِنِّي آنَسْتُ نَارًا سَآتِيكُم مِّنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ آتِيكُم بِشِهَابٍ قَبَسٍ لَّعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ
Yoruba
 
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: "Dájúdájú mo rí iná kan. Mo sì máa lọ mú ìró kan wá fún yín láti ibẹ̀, tàbí kí n̄g mú ògúnná kan tó ń tanná wá fún yín nítorí kí ẹ lè yẹ́ná.

Ayah  27:8  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَهَا نُودِيَ أَن بُورِكَ مَن فِي النَّارِ وَمَنْ حَوْلَهَا وَسُبْحَانَ اللهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pèpè pé kí ìbùkún máa bẹ fún ẹni tí ó wà níbi iná náà àti ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Mímọ́ sì ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ayah  27:9  الأية
    +/- -/+  
يَا مُوسَىٰ إِنَّهُ أَنَا اللهُ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Yoruba
 
Mūsā, dájúdájú (ẹni tí ó ń bá ọ sọ̀rọ̀), Èmi ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Ayah  27:10  الأية
    +/- -/+  
وَأَلْقِ عَصَاكَ ۚ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ لَا تَخَفْ إِنِّي لَا يَخَافُ لَدَيَّ الْمُرْسَلُونَ
Yoruba
 
Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀. (Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.) Àmọ́ nígbà tí ó rí i tó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìndà, ó ń sá lọ. Kò sì padà sẹ́yìn. (Allāhu sọ pé:) Mūsā, má ṣe páyà. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kì í páyà lọ́dọ̀ Mi.

Ayah  27:11  الأية
    +/- -/+  
إِلَّا مَن ظَلَمَ ثُمَّ بَدَّلَ حُسْنًا بَعْدَ سُوءٍ فَإِنِّي غَفُورٌ رَّحِيمٌ
Yoruba
 
Àyàfi ẹni tí ó bá ṣàbòsí, lẹ́yìn náà tí ó yí i padà sí rere lẹ́yìn aburú. Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  27:12  الأية
    +/- -/+  
وَأَدْخِلْ يَدَكَ فِي جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ ۖ فِي تِسْعِ آيَاتٍ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَقَوْمِهِ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ
Yoruba
 
Ti ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ. Ó sì máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe ti aburú. (Èyí wà) nínú àwọn àmì mẹ́sàn-án (tí o máa mú lọ) bá Fir‘aon àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Ayah  27:13  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَتْهُمْ آيَاتُنَا مُبْصِرَةً قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ
Yoruba
 
Nígbà tí àwọn àmì Wa tó fojú hàn kedere sì dé bá wọn, wọ́n wí pé: "Èyí ni idán pọ́nńbélé."

Ayah  27:14  الأية
    +/- -/+  
وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا ۚ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ
Yoruba
 
Wọ́n fi àbòsí àti ìgbéraga takò ó, ẹ̀mí wọn sì ní àmọ̀dájú pé òdodo ni. Nítorí náà, wòye sí bí àtubọ̀tán àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ti rí.

Ayah  27:15  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ آتَيْنَا دَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ عِلْمًا ۖ وَقَالَا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي فَضَّلَنَا عَلَىٰ كَثِيرٍ مِّنْ عِبَادِهِ الْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Dájúdájú A fún (Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n ní ìmọ̀. Àwọn méjèèjì sì sọ pé: "Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó fún wa ní oore àjùlọ lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ òdodo."

Ayah  27:16  الأية
    +/- -/+  
وَوَرِثَ سُلَيْمَانُ دَاوُودَ ۖ وَقَالَ يَا أَيُّهَا النَّاسُ عُلِّمْنَا مَنطِقَ الطَّيْرِ وَأُوتِينَا مِن كُلِّ شَيْءٍ ۖ إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْفَضْلُ الْمُبِينُ
Yoruba
 
(Ànábì) Sulaemọ̄n sì jogún (Ànábì) Dāwūd. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi ohùn ẹyẹ mọ̀ wá. Wọ́n sì fún wa ní gbogbo n̄ǹkan. Dájúdájú èyí, òhun ni oore àjùlọ pọ́nńbélé."

Ayah  27:17  الأية
    +/- -/+  
وَحُشِرَ لِسُلَيْمَانَ جُنُودُهُ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ وَالطَّيْرِ فَهُمْ يُوزَعُونَ
Yoruba
 
A sì kó jọ fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú àlùjànnú, ènìyàn àti ẹyẹ. A sì ń kó wọn jọ papọ̀ mọ́ra wọn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń bá a rìn káàkiri

Ayah  27:18  الأية
    +/- -/+  
حَتَّىٰ إِذَا أَتَوْا عَلَىٰ وَادِ النَّمْلِ قَالَتْ نَمْلَةٌ يَا أَيُّهَا النَّمْلُ ادْخُلُوا مَسَاكِنَكُمْ لَا يَحْطِمَنَّكُمْ سُلَيْمَانُ وَجُنُودُهُ وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba
 
Títí wọ́n fi dé àfonúfojì àwọn àwúrèbe. Àwúrèbe kan sì wí pé: "Ẹ̀yin àwúrèbe, ẹ wọ inú ilé yín lọ, kí (Ànábì) Sulaemọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ má baà tẹ̀ yín rẹ́ mọ́lẹ̀. Wọn kò sì níí furamọ̀."

Ayah  27:19  الأية
    +/- -/+  
فَتَبَسَّمَ ضَاحِكًا مِّن قَوْلِهَا وَقَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِي أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ الَّتِي أَنْعَمْتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَالِدَيَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَالِحًا تَرْضَاهُ وَأَدْخِلْنِي بِرَحْمَتِكَ فِي عِبَادِكَ الصَّالِحِينَ
Yoruba
 
Nígbà náà, (Ànábì Sulaemọ̄n) rẹ́rìn-ín músẹ́, ẹ̀rín pa á nítorí ọ̀rọ̀ (àwúrèbe náà). Ó sọ pé: "Olúwa mi, fi mọ̀ mí bí mo ṣe máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí O fi ṣe ìdẹ̀ra fún èmi àti àwọn òbí mi méjèèjì. (Fi mọ̀ mí) bí mo ṣe máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Pẹ̀lú àánú Rẹ, fi mí sáààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni rere."

Ayah  27:20  الأية
    +/- -/+  
وَتَفَقَّدَ الطَّيْرَ فَقَالَ مَا لِيَ لَا أَرَى الْهُدْهُدَ أَمْ كَانَ مِنَ الْغَائِبِينَ
Yoruba
 
Ó yẹ àwọn ẹyẹ wò, ó sì sọ pé: "Nítorí kí ni èmi kò ṣe rí ẹyẹ hudhuda? Àbí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí kò wá ni?

Ayah  27:21  الأية
    +/- -/+  
لَأُعَذِّبَنَّهُ عَذَابًا شَدِيدًا أَوْ لَأَذْبَحَنَّهُ أَوْ لَيَأْتِيَنِّي بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Dájúdájú mo máa jẹ ẹ́ níyà líle, tàbí kí n̄g dúńbú rẹ̀, tàbí kí ó mú ẹ̀rí tó yanjú wá fún mi."

Ayah  27:22  الأية
    +/- -/+  
فَمَكَثَ غَيْرَ بَعِيدٍ فَقَالَ أَحَطتُ بِمَا لَمْ تُحِطْ بِهِ وَجِئْتُكَ مِن سَبَإٍ بِنَبَإٍ يَقِينٍ
Yoruba
 
(Ànábì Sulaemọ̄n) kò dúró pẹ́ (títí ó fi dé), ó sì wí pé: "Mo mọ n̄ǹkan tí o ò mọ̀. Mo sì mú ìró kan tó dájú wá bá ọ láti ìlú Saba'i.

Ayah  27:23  الأية
    +/- -/+  
إِنِّي وَجَدتُّ امْرَأَةً تَمْلِكُهُمْ وَأُوتِيَتْ مِن كُلِّ شَيْءٍ وَلَهَا عَرْشٌ عَظِيمٌ
Yoruba
 
Dájúdájú èmi bá obìnrin kan (ní ìlú Saba'i), tó ń jọba lé wọn lórí. Wọ́n fún un ní gbogbo n̄ǹkan. Ó sì ní ìtẹ́ ńlá kan.

Ayah  27:24  الأية
    +/- -/+  
وَجَدتُّهَا وَقَوْمَهَا يَسْجُدُونَ لِلشَّمْسِ مِن دُونِ اللهِ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ فَهُمْ لَا يَهْتَدُونَ
Yoruba
 
Mo sì bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún òòrùn lẹ́yìn Allāhu. Èṣù sì ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (òdodo). Nítorí náà, wọn kò sì mọ̀nà.

Ayah  27:25  الأية
    +/- -/+  
أَلَّا يَسْجُدُوا لِلَّهِ الَّذِي يُخْرِجُ الْخَبْءَ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَيَعْلَمُ مَا تُخْفُونَ وَمَا تُعْلِنُونَ
Yoruba
 
(Èṣù ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn) torí kí wọ́n má lè forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tó ń mú ohùn tó pamọ́ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ jáde, Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn.

Ayah  27:26  الأية
    +/- -/+  
اللهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ ۩
Yoruba
 
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ ńlá."

Ayah  27:27  الأية
    +/- -/+  
قَالَ سَنَنظُرُ أَصَدَقْتَ أَمْ كُنتَ مِنَ الْكَاذِبِينَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "A máa wòye bóyá òdodo l'o sọ tàbí o wà nínú àwọn òpùrọ́.

Ayah  27:28  الأية
    +/- -/+  
اذْهَب بِّكِتَابِي هَٰذَا فَأَلْقِهْ إِلَيْهِمْ ثُمَّ تَوَلَّ عَنْهُمْ فَانظُرْ مَاذَا يَرْجِعُونَ
Yoruba
 
Mú ìwé mi yìí lọ, kí o jù ú sí wọn. Lẹ́yìn náà, kí o takété sí wọn, kí o sì wo ohun tí wọn yóò dá padà (ní èsì)."

Ayah  27:29  الأية
    +/- -/+  
قَالَتْ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ إِنِّي أُلْقِيَ إِلَيَّ كِتَابٌ كَرِيمٌ
Yoruba
 
(Bilƙīs) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjòyè, dájúdájú wọ́n ti ju ìwé alápọ̀n-ọ́nlé kan sí mi.

Ayah  27:30  الأية
    +/- -/+  
إِنَّهُ مِن سُلَيْمَانَ وَإِنَّهُ بِسْمِ اللهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ
Yoruba
 
Dájúdájú ó wá láti ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n. Dájúdájú ó (sọ pé) "Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Ayah  27:31  الأية
    +/- -/+  
أَلَّا تَعْلُوا عَلَيَّ وَأْتُونِي مُسْلِمِينَ
Yoruba
 
Kí ẹ má ṣègbéraga sí mi, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi (láti di) mùsùlùmí."

Ayah  27:32  الأية
    +/- -/+  
قَالَتْ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ أَفْتُونِي فِي أَمْرِي مَا كُنتُ قَاطِعَةً أَمْرًا حَتَّىٰ تَشْهَدُونِ
Yoruba
 
(Bilƙīs) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì í gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan títí ẹ máa fi jẹ́rìí sí i."

Ayah  27:33  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا نَحْنُ أُولُو قُوَّةٍ وَأُولُو بَأْسٍ شَدِيدٍ وَالْأَمْرُ إِلَيْكِ فَانظُرِي مَاذَا تَأْمُرِينَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "Alágbára ni àwa. Akọni ogun sì tún ni wá. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọ̀rọ̀ wà. Nítorí náà, wòye sí ohun tí o máa pa láṣẹ."

Ayah  27:34  الأية
    +/- -/+  
قَالَتْ إِنَّ الْمُلُوكَ إِذَا دَخَلُوا قَرْيَةً أَفْسَدُوهَا وَجَعَلُوا أَعِزَّةَ أَهْلِهَا أَذِلَّةً ۖ وَكَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ
Yoruba
 
(Bilƙīs) wí pé: "Dájúdájú àwọn ọba, nígbà tí wọ́n bá wọ inú ìlú kan, wọn yóò bà á jẹ́. Wọn yó sì sọ àwọn ẹni abiyì ibẹ̀ di ẹni yẹpẹrẹ. Báyẹn ni wọ́n máa ń ṣe.

Ayah  27:35  الأية
    +/- -/+  
وَإِنِّي مُرْسِلَةٌ إِلَيْهِم بِهَدِيَّةٍ فَنَاظِرَةٌ بِمَ يَرْجِعُ الْمُرْسَلُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú mo máa fi ẹ̀bùn kan ránṣẹ́ sí wọn. Mo sì máa wo ohun tí àwọn ìránṣẹ́ yóò mú padà (ní èsì)."

Ayah  27:36  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَ سُلَيْمَانَ قَالَ أَتُمِدُّونَنِ بِمَالٍ فَمَا آتَانِيَ اللهُ خَيْرٌ مِّمَّا آتَاكُم بَلْ أَنتُم بِهَدِيَّتِكُمْ تَفْرَحُونَ
Yoruba
 
Nígbà tí (ìránṣẹ́) dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Sulaemọ̄n, ó sọ pé: "Ṣé ẹ máa fi owó ràn mí lọ́wọ́ ni? Ohun tí Allāhu fún mi lóore jùlọ sí ohun tí ẹ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀yin tún ń yọ̀ lórí ẹ̀bùn yín.

Ayah  27:37  الأية
    +/- -/+  
ارْجِعْ إِلَيْهِمْ فَلَنَأْتِيَنَّهُم بِجُنُودٍ لَّا قِبَلَ لَهُم بِهَا وَلَنُخْرِجَنَّهُم مِّنْهَا أَذِلَّةً وَهُمْ صَاغِرُونَ
Yoruba
 
Padà sí ọ̀dọ̀ wọn. Dájúdájú à ń bọ̀ wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lè kojú rẹ̀. Dájúdájú a máa mú wọn jáde kúrò nínú (ìlú wọn) ní ẹni yẹpẹrẹ, tí wọn yó sì di ẹni àbùkù."

Ayah  27:38  الأية
    +/- -/+  
قَالَ يَا أَيُّهَا الْمَلَأُ أَيُّكُمْ يَأْتِينِي بِعَرْشِهَا قَبْلَ أَن يَأْتُونِي مُسْلِمِينَ
Yoruba
 
(Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjòyè, èwo nínú yín l'ó máa gbé ìtẹ́ (Bilƙīs) wá bá mi, ṣíwájú kí wọ́n tó wá bá mi (láti di) mùsùlùmí."

Ayah  27:39  الأية
    +/- -/+  
قَالَ عِفْرِيتٌ مِّنَ الْجِنِّ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَن تَقُومَ مِن مَّقَامِكَ ۖ وَإِنِّي عَلَيْهِ لَقَوِيٌّ أَمِينٌ
Yoruba
 
‘Ifrīt nínú àwọn àlùjànnú sọ pé: "Èmi yóò gbe wá fún ọ ṣíwájú kí o tó dìde kúrò ní ibùjókòó rẹ. Dájúdájú èmi ni alágbára, olùfọkàntán lórí rẹ̀."

Ayah  27:40  الأية
    +/- -/+  
قَالَ الَّذِي عِندَهُ عِلْمٌ مِّنَ الْكِتَابِ أَنَا آتِيكَ بِهِ قَبْلَ أَن يَرْتَدَّ إِلَيْكَ طَرْفُكَ ۚ فَلَمَّا رَآهُ مُسْتَقِرًّا عِندَهُ قَالَ هَٰذَا مِن فَضْلِ رَبِّي لِيَبْلُوَنِي أَأَشْكُرُ أَمْ أَكْفُرُ ۖ وَمَن شَكَرَ فَإِنَّمَا يَشْكُرُ لِنَفْسِهِ ۖ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ رَبِّي غَنِيٌّ كَرِيمٌ
Yoruba
 
Ẹni tí ìmọ̀ kan láti inú tírà wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ sọ pé: "Èmi yóò gbé e wá fún ọ ṣíwájú kí o tó ṣẹ́jú." Nígbà tí ó rí i tí ó dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: "Èyí wà nínú oore àjùlọ Olúwa mi láti fi dán mi wò bóyá mo máa dúpẹ́ tàbí mo máa ṣàì moore. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́ (fún Allāhu), ó dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàìmoore, dájúdájú Olúwa mi ni Ọlọ́rọ̀, Alápọ̀n-ọ́nlé."

Ayah  27:41  الأية
    +/- -/+  
قَالَ نَكِّرُوا لَهَا عَرْشَهَا نَنظُرْ أَتَهْتَدِي أَمْ تَكُونُ مِنَ الَّذِينَ لَا يَهْتَدُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ẹ pa á lójú dà fún un sí ìrísí mìíràn tí kò fi níí dá a mọ̀, kí á wò ó bóyá ó máa dá a mọ̀ tàbí ó máa wà nínú àwọn tí kò níí dá a mọ̀."

Ayah  27:42  الأية
    +/- -/+  
فَلَمَّا جَاءَتْ قِيلَ أَهَٰكَذَا عَرْشُكِ ۖ قَالَتْ كَأَنَّهُ هُوَ ۚ وَأُوتِينَا الْعِلْمَ مِن قَبْلِهَا وَكُنَّا مُسْلِمِينَ
Yoruba
 
Nígbà tí (Bilƙīs) dé, wọ́n sọ fún un pé: "Ṣé bí ìtẹ́ rẹ ṣe rí nìyí?" Ó wí pé: "Ó dà bí ẹni pé òhun ni." (Ànábì Sulaemọ̄n sì sọ pé): "Wọ́n ti fún wa ní ìmọ̀ ṣíwájú Bilƙīs. A sì jẹ́ mùsùlùmí."

Ayah  27:43  الأية
    +/- -/+  
وَصَدَّهَا مَا كَانَت تَّعْبُدُ مِن دُونِ اللهِ ۖ إِنَّهَا كَانَتْ مِن قَوْمٍ كَافِرِينَ
Yoruba
 
Ohun tó ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu sì ṣẹ́rí rẹ̀ (kúrò níbi jíjọ́sìn fún Allāhu). Dájúdájú ó wà nínú ìjọ aláìgbàgbọ́.

Ayah  27:44  الأية
    +/- -/+  
قِيلَ لَهَا ادْخُلِي الصَّرْحَ ۖ فَلَمَّا رَأَتْهُ حَسِبَتْهُ لُجَّةً وَكَشَفَتْ عَن سَاقَيْهَا ۚ قَالَ إِنَّهُ صَرْحٌ مُّمَرَّدٌ مِّن قَوَارِيرَ ۗ قَالَتْ رَبِّ إِنِّي ظَلَمْتُ نَفْسِي وَأَسْلَمْتُ مَعَ سُلَيْمَانَ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Yoruba
 
Wọ́n sọ fún un pé: "Wọ inú ààfin." Nígbà tí ó rí i, ó ṣe bí ibúdò ni. Ó sì ká aṣọ kúrò ní ojúgun rẹ̀ méjèèjì. (Ànábì Sulaemọ̄n) sọ pé: "Dájúdájú ààfin tí a ṣe rigidin pẹ̀lú díńgí ni." (Bilƙīs) sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú mo ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Mo sì di mùsùlùmí pẹ̀lú (Ànábì) Sulaemọ̄n, fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá."

Ayah  27:45  الأية
    +/- -/+  
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا إِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمْ صَالِحًا أَنِ اعْبُدُوا اللهَ فَإِذَا هُمْ فَرِيقَانِ يَخْتَصِمُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí ìjọ Thamūd. (A rán) arákùnrin wọn, Sọ̄lih (níṣẹ́ sí wọn), pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu." Nígbà náà ni wọ́n pín sí ìjọ méjì, tó ń bára wọn jiyàn.

Ayah  27:46  الأية
    +/- -/+  
قَالَ يَا قَوْمِ لِمَ تَسْتَعْجِلُونَ بِالسَّيِّئَةِ قَبْلَ الْحَسَنَةِ ۖ لَوْلَا تَسْتَغْفِرُونَ اللهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Yoruba
 
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá (ìyà) aburú pẹ̀lú ìkánjú ṣíwájú (ohun) rere (tó yẹ kí ẹ mú ṣe níṣẹ́)? Ẹ kò ṣe tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu nítorí kí Wọ́n lè ṣàánú yín?"

Ayah  27:47  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا اطَّيَّرْنَا بِكَ وَبِمَن مَّعَكَ ۚ قَالَ طَائِرُكُمْ عِندَ اللهِ ۖ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ تُفْتَنُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí pé: "A rí àmì aburú láti ọ̀dọ̀ rẹ àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ." (Ànábì Sọ̄lih) sọ pé: "Àmì aburú yín wà (nínú kádàrá yín) lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì rí bí ẹ ṣe rò ó àmọ́ ìjọ aládàn-ánwò ni yín."

Ayah  27:48  الأية
    +/- -/+  
وَكَانَ فِي الْمَدِينَةِ تِسْعَةُ رَهْطٍ يُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ
Yoruba
 
Àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án kan sì wà nínú ìlú, tí wọ́n ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣàtúnṣe.

Ayah  27:49  الأية
    +/- -/+  
قَالُوا تَقَاسَمُوا بِاللهِ لَنُبَيِّتَنَّهُ وَأَهْلَهُ ثُمَّ لَنَقُولَنَّ لِوَلِيِّهِ مَا شَهِدْنَا مَهْلِكَ أَهْلِهِ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
Yoruba
 
Wọ́n wí (fúnra wọn) pé: "Kí á dìjọ fí Allāhu búra pé dájúdájú a máa lọ bá òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní alẹ́ (láti pa á). Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa sọ fún ẹbí rẹ̀ pé ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣojú wa. Dájúdájú olódodo sì ni àwa."

Ayah  27:50  الأية
    +/- -/+  
وَمَكَرُوا مَكْرًا وَمَكَرْنَا مَكْرًا وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ
Yoruba
 
Wọ́n déte gan-an, Àwa náà sì déte gan-an, wọn kò sì fura.

Ayah  27:51  الأية
    +/- -/+  
فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ مَكْرِهِمْ أَنَّا دَمَّرْنَاهُمْ وَقَوْمَهُمْ أَجْمَعِينَ
Yoruba
 
Wo bí àtubọ̀tán ète wọn ti rí. Dájúdájú A pa àwọn àti ìjọ wọn run pátápátá.

Ayah  27:52  الأية
    +/- -/+  
فَتِلْكَ بُيُوتُهُمْ خَاوِيَةً بِمَا ظَلَمُوا ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
Nítorí náà, ìwọ̀nyẹn ni ilé wọn. Ó tí di ilé ahoro nítorí pé wọ́n ṣàbòsí. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó nímọ̀.

Ayah  27:53  الأية
    +/- -/+  
وَأَنجَيْنَا الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ
Yoruba
 
A gba àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo là, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).

Ayah  27:54  الأية
    +/- -/+  
وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَتَأْتُونَ الْفَاحِشَةَ وَأَنتُمْ تُبْصِرُونَ
Yoruba
 
(A tún fi iṣẹ́ ìmísí rán Ànábì) Lūt. (Rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣé iṣẹ́ aburú ni ẹ óò máa ṣe ni, ẹ sì ríran?

Ayah  27:55  الأية
    +/- -/+  
أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الرِّجَالَ شَهْوَةً مِّن دُونِ النِّسَاءِ ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ تَجْهَلُونَ
Yoruba
 
Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa lọ jẹ adùn (ìbálòpọ̀) lára àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín ni) dípò àwọn obìnrin? Àní sẹ́, òpè ènìyàn ni yín."

Ayah  27:56  الأية
    +/- -/+  
فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا أَخْرِجُوا آلَ لُوطٍ مِّن قَرْيَتِكُمْ ۖ إِنَّهُمْ أُنَاسٌ يَتَطَهَّرُونَ
Yoruba
 
Kò sí ohun kan tí ìjọ rẹ̀ fọ̀ ní èsì tayọ pé wọ́n wí pé: "Ẹ lé àwọn ènìyàn Lūt jáde kúrò nínú ìlú yín. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ènìyàn tó ń fọra wọn mọ́ (níbi ẹ̀ṣẹ̀)."

Ayah  27:57  الأية
    +/- -/+  
فَأَنجَيْنَاهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ قَدَّرْنَاهَا مِنَ الْغَابِرِينَ
Yoruba
 
Nítorí náà, A gba òun àti ẹbí rẹ̀ là àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ ọ́ pé ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.

Ayah  27:58  الأية
    +/- -/+  
وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنذَرِينَ
Yoruba
 
A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.

Ayah  27:59  الأية
    +/- -/+  
قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ وَسَلَامٌ عَلَىٰ عِبَادِهِ الَّذِينَ اصْطَفَىٰ ۗ آللهُ خَيْرٌ أَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Kí àlàáfíà máa bá àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tí Ó ṣà lẹ́ṣà. Ṣé Allāhu l'Ó lóore jùlọ ni tàbí n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀?"

Ayah  27:60  الأية
    +/- -/+  
أَمَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنبَتْنَا بِهِ حَدَائِقَ ذَاتَ بَهْجَةٍ مَّا كَانَ لَكُمْ أَن تُنبِتُوا شَجَرَهَا ۗ أَإِلَٰهٌ مَّعَ اللهِ ۚ بَلْ هُمْ قَوْمٌ يَعْدِلُونَ
Yoruba
 
(Ṣé ìbọ̀rìṣà l'ó lóore jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sọ omi kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀, tí A sì fi omi náà hu àwọn ọgbà oko tí ó dára jáde? Kò sì sí agbára fún yín láti mu igi rẹ̀ hù jáde. Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Rárá, ìjọ tó ń ṣẹbọ sí Allāhu ni wọ́n ni.

Ayah  27:61  الأية
    +/- -/+  
أَمَّن جَعَلَ الْأَرْضَ قَرَارًا وَجَعَلَ خِلَالَهَا أَنْهَارًا وَجَعَلَ لَهَا رَوَاسِيَ وَجَعَلَ بَيْنَ الْبَحْرَيْنِ حَاجِزًا ۗ أَإِلَٰهٌ مَّعَ اللهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
Yoruba
 
(Ṣé ìbọ̀rìṣà l'ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ibùgbé, tí Ó fi àwọn odò sáààrin rẹ̀, tí Ó fi àwọn àpáta gbagidi sínú ilẹ̀, tí Ó sì fi gàgá sáààrin ibúdò méjèèjì? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

Ayah  27:62  الأية
    +/- -/+  
أَمَّن يُجِيبُ الْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ السُّوءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَاءَ الْأَرْضِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَّعَ اللهِ ۚ قَلِيلًا مَّا تَذَكَّرُونَ
Yoruba
 
(Ṣé ìbọ̀rìṣà l'ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń jẹ́pè ẹni tí ara ń ni nígbà tí ó bá pè É, tí Ó sì máa gbé aburú kúrò fún un, tí Ó sì ń ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Díẹ̀ ni ohun tí ẹ̀ ń lò nínú ìrántí!

Ayah  27:63  الأية
    +/- -/+  
أَمَّن يَهْدِيكُمْ فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَمَن يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَّعَ اللهِ ۚ تَعَالَى اللهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ
Yoruba
 
(Ṣé ìbọ̀rìṣà l'ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ń tọ yín sọ́nà nínú àwọn òkùnkùn orí ilẹ̀ àti inú ibúdò, tí Ó tún ń fi atẹ́gùn ránṣẹ́ ní ìró ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Allāhu ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

Ayah  27:64  الأية
    +/- -/+  
أَمَّن يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَمَن يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَّعَ اللهِ ۚ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Yoruba
 
(Ṣé ìbọ̀rìṣà l'ó dára jùlọ ni) tàbí (jíjọ́sìn fún) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí Ó máa dá a padà (lẹ́yìn ikú), tí Ó sì ń pèsè fún yín láti sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo."

Ayah  27:65  الأية
    +/- -/+  
قُل لَّا يَعْلَمُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الْغَيْبَ إِلَّا اللهُ ۚ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àfi Allāhu. Àti pé wọn kò sì mọ àsìkò wo ni A máa gbé àwọn òkú dìde."

Ayah  27:66  الأية
    +/- -/+  
بَلِ ادَّارَكَ عِلْمُهُمْ فِي الْآخِرَةِ ۚ بَلْ هُمْ فِي شَكٍّ مِّنْهَا ۖ بَلْ هُم مِّنْهَا عَمُونَ
Yoruba
 
Rárá, ìmọ̀ wọn máa kẹ́sẹjá ní ọ̀run (orí wọn máa pé ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ (báyìí). Àní sẹ́, wọ́n fọ́jú nípa rẹ̀ ni.

Ayah  27:67  الأية
    +/- -/+  
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَإِذَا كُنَّا تُرَابًا وَآبَاؤُنَا أَئِنَّا لَمُخْرَجُونَ
Yoruba
 
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Ṣé nígbà tí àwa àti àwọn bàbá wa bá ti di erùpẹ̀, ṣé (nígbà náà ni) wọn yóò mú wa jáde?

Ayah  27:68  الأية
    +/- -/+  
لَقَدْ وُعِدْنَا هَٰذَا نَحْنُ وَآبَاؤُنَا مِن قَبْلُ إِنْ هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Yoruba
 
Wọ́n kúkú tí ṣe àdéhùn èyí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́."

Ayah  27:69  الأية
    +/- -/+  
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُجْرِمِينَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe rí."

Ayah  27:70  الأية
    +/- -/+  
وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَلَا تَكُن فِي ضَيْقٍ مِّمَّا يَمْكُرُونَ
Yoruba
 
Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Má sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń dá ní ète kó ìnira bá ọ.

Ayah  27:71  الأية
    +/- -/+  
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ
Yoruba
 
Wọ́n ń wí pé: "Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?"

Ayah  27:72  الأية
    +/- -/+  
قُلْ عَسَىٰ أَن يَكُونَ رَدِفَ لَكُم بَعْضُ الَّذِي تَسْتَعْجِلُونَ
Yoruba
 
Sọ pé: "Ó lè jẹ́ pé apá kan ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ti súnmọ́ yín tán."

Ayah  27:73  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَشْكُرُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Ọlọ́lá lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kì í dúpẹ́ (fún Un).

Ayah  27:74  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَعْلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمْ وَمَا يُعْلِنُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó kúkú mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀.

Ayah  27:75  الأية
    +/- -/+  
وَمَا مِنْ غَائِبَةٍ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ
Yoruba
 
Àti pé kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó hàn kedere.

Ayah  27:76  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ هَٰذَا الْقُرْآنَ يَقُصُّ عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَكْثَرَ الَّذِي هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Yoruba
 
Dájúdájú al-Ƙur'ān yìí yóò máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ 'Isrọ̄'īl nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu sí.

Ayah  27:77  الأية
    +/- -/+  
وَإِنَّهُ لَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّلْمُؤْمِنِينَ
Yoruba
 
Àti pé dájúdájú ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ayah  27:78  الأية
    +/- -/+  
إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِي بَيْنَهُم بِحُكْمِهِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْعَلِيمُ
Yoruba
 
Dájúdájú Olúwa rẹ máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú ìdájọ́ Rẹ̀. Òun ni Alágbára, Onímọ̀.

Ayah  27:79  الأية
    +/- -/+  
فَتَوَكَّلْ عَلَى اللهِ ۖ إِنَّكَ عَلَى الْحَقِّ الْمُبِينِ
Yoruba
 
Nítorí náà, gbáralé Allāhu. Dájúdájú ìwọ wà lórí òdodo pọ́nńbélé.

Ayah  27:80  الأية