Fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí A bá p'èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: "Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." - Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). - Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú. Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l'ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l'ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnu àti (ohun jíjẹ) salwā kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Nítorí náà, A sọ pé: "Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà)." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Ṣé ẹ̀ ń rankàn pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: "A gbàgbọ́." Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: "Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fún yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!"
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: "Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu." Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: "Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀." Wọ́n á wí pé: "A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa." Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tó wà lẹ́yìn rẹ̀, òhun sì ni òdodo, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: "Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s'ókè orí yín, (A sọ pé:) "Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀." Wọ́n wí pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (rẹ̀)." Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: "Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo."
Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán lásìkò) ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì di kèfèrí, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n di kèfèrí, wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjèèjì, Hārūt àti Mọ̄rūt ní ìlú Bābil. Àwọn mọlāika méjèèjì náà kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n sọ pé: "Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí." Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí wọ́n bá dojú yín kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ojú rere Allāhu (ìyẹn ni pé, ẹ ti dojúkọ Allāhu ní ibi tí wọ́n bá pa yín láṣẹ pé kí ẹ dojúkọ kírun.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.
Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?" Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná.